Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 20
Orin 109 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 14 ìpínrọ̀ 16 sí 20 àti àpótí tó wà lójú ìwé 147 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 7-10 (10 min.)
No. 1: Diutarónómì 9:15-29 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìyá Jésù Ni Màríà Kì Í Ṣe “Ìyá Ọlọ́run”—td 23A (5 min.)
No. 3: Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé?—lr orí 36 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: “Bí A Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tá A Gbà Gbọ́ Nípa Ọdún 1914.” Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè márùn-ún tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà.
15 min: Àpilẹ̀kọ Tá Á Lè Fi Ṣàlàyé Ohun Tá A Gbà Gbọ́ Nípa Ọdún 1914. Fi àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú méje bẹ̀rẹ̀ apá yìí. Akéde kan ń lo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 11 nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2014 láti fi ṣàlàyé ṣókí fún ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì orí 4 ṣe tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ní kí àwọn ará sọ ìdí tí àṣefihàn náà fi gbéṣẹ́. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, ka Ìṣípayá 12:10, 12, kó o sì ní kí àwọn ará sọ bí mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914 ṣe ń mú ká máa wàásù ìhìn rere lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú.
Orin 133 àti Àdúrà