Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìlélọ́gọ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti méjìlélọ́gọ́ta [362,462] ló ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù August 2014. A ò tíì ní iye akéde tó pọ̀ tó báyìí rí. Iye àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi ni ọdún 2014 náà pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́tàdínlógójì, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [737,926]. Àwọn ìbísí míì tí a kò rí irú rẹ̀ rí tá a ní oṣù August 2014 nìyí:
• Ìwé ńlá: 188,156
• Ìwé Kékeré/Ìwé Pẹlẹbẹ: 6,517,060
• Wákàtí: 8,026,150
• Ìwé ìròyìn: 2,548,968
• Ìpadàbẹ̀wò: 2,897,448
• Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 935,299
• Aṣáájú-ọ̀nà déédéé : 37,528
• Aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́: 65,846
Ǹjẹ́ kí á máa bá iṣẹ́ rere wa nìṣó nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ wa ”dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà”!—Ìṣe 18:5.