Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 9
Orin 9 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 20 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 11-14 (8 min.)
No. 1: Àwọn Onídàájọ́ 13:15-25 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ẹ̀kọ́ Wo La Rí Kọ́ Nípa Àlejò Ṣíṣe Látinú Àpẹẹrẹ Lìdíà, Gáyọ́sì àti Fílémónì (5 min.)
No. 3: Ṣé Bíbélì Máa Ń Tọ̀nà Tó Bá Sọ̀rọ̀ Nípa Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì?—igw ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà”!—Títù 2:14.
15 min: “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ ‘Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà’?” Ìjíròrò. Fi àlàyé tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 2002, ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 17 sí 19 kún ọ̀rọ̀ rẹ.
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Fóònù Wàásù.” Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní tó jẹ́ ká ríi bí àwọn onílé kan ṣe fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n wàásù fún wọn lórí fóònù. Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn kan ṣókí nípa bí a ṣe lè lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ́ yìí. Ní àfidípò, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí tí fífi fóònù wàásù kò bá wọ́pọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín: (1) Àwọn nǹkan wo ló lè jẹ́ ìpèníjà fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tàbí tó lè fẹ́ paná ìtara tá a ní fún iṣẹ́ àtàtà? (2) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o jẹ́ kí ìpèníjà yìí dí ọ lọ́wọ́ jíjẹ́ onítara? (Róòmù 10:14) (3) Báwo ni ìmúrasílẹ̀ ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ onítara? (2 Tím. 2:15) (4) Àwọn àbájáde rere wo ló lè tibẹ̀ yọ tó o bá fi ọgbọ́n pinnu ohun tí wàá sọ? (Òwe 25:11, 15) Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn ṣókí nípa bí a ṣe lè borí ìpèníjà kan tá a ní ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.
Orin 33 àti Àdúrà