Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà”?
Ǹjẹ́ o ní ìtara fún iṣẹ́ àtàtà? Gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba Ọlọ́run, ó yẹ ká ní ìtara fún iṣẹ́ àtàtà. Kí nìdí? Wo ohun tí Títù 2:11-14 sọ:
Ẹsẹ 11: Kí ni “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run,” báwo ni àwa fúnra wa sì ṣe jàǹfààní rẹ̀?—Róòmù 3:23, 24.
Ẹsẹ 12: Nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, báwo ni Ọlọ́run ṣe fún wa ní ìtọ́ni?
Ẹsẹ 13 àti 14: Ìrètí wo la ní nísinsìnyí tí a ti wẹ̀ wá mọ́? Fún ète pàtàkì wo sì ni a fi wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú àwọn ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run?
Báwo ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe ta ọ́ jí láti jẹ́ onítara fún àwọn iṣẹ́ àtàtà?