ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 August ojú ìwé 5
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ “Ní Ìtara fún Iṣẹ́ Rere”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ “Ní Ìtara fún Iṣẹ́ Rere”
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Fi Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Yin Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ìyípadà Nínú Iye Wákàtí Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àwọn Ìbùkún Tó Wà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 August ojú ìwé 5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ “Ní Ìtara fún Iṣẹ́ Rere”

Nínú lẹ́tà onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Títù, ó sọ pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin irú bí Títù máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti “jẹ́ àpẹẹrẹ nínú àwọn iṣẹ́ rere.” (Tit 2:6, 7) Nínú orí Bíbélì yẹn kan náà, ó sọ pé Jésù máa wẹ àwọn èèyàn Jèhófà mọ́, kí wọ́n lè “ní ìtara fún iṣẹ́ rere.” (Tit 2:14) Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ rere yẹn ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti kíkọ́ni. Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, ṣé ìwọ náà lè lo okun tó o ní láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé?​—Owe 20:29.

Tó o bá fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ṣètò ara rẹ kíwọ náà lè di aṣáájú-ọ̀nà. (Lk 14:28-30) Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe máa rówó bójú tó ara rẹ ní gbogbo ìgbà tó o fi ń ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún yìí? Báwo ni wàá ṣe dójú ìlà wákàtí tá a béèrè fún? Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm 37:5) Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe fún àwọn òbí rẹ àtàwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, kó o gbé ìgbésẹ̀, kí àwọn àfojúsùn rẹ lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀!

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ TÓ Ń YIN JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ìṣòro wo làwọn aṣáájú-ọ̀nà kan ti borí, báwo sì ni wọ́n ṣe ṣeé?

  • Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé?

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn ní ètò fún iṣẹ́ ìwàásù?

  • Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà níṣìírí, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Ìbùkún wo làwọn tó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa ń rí?

Ọ̀dọ́bìnrin kan fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó wá ń bá bàbá ẹ̀ sọ ọ́; ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ń kọ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe sílẹ́; ọ̀dọ́bìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ń bá arábìnrin kan ṣiṣẹ́ lóde-ẹ̀rí; ọ̀dọ́bìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan

Báwo ni àfojúsùn mi láti di aṣáájú-ọ̀nà ṣe lè tẹ̀ mí lọ́wọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́