MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Fi Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Yin Jèhófà
Ó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa yin Jèhófà torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì, ó sì gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Fáráò! (Ẹk 15:1, 2) Bákan náà lónìí, Jèhófà ò ṣíwọ́ fifi àánú hàn sáwọn èèyàn rẹ̀. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore?—Sm 116:12.
Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. O lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó wù ẹ́, kó sì tún fún ẹ lágbára láti ṣe iṣẹ́ náà. (Flp 2:13) Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ni wọ́n kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀. O lè pinnu bóyá ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákàtí lo máa ṣe láwọn oṣù March àti April àti láwọn oṣù tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ yín wò. Tó o bá rí ayọ̀ tó wà nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ìyẹn lè mú kó wù ẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kódà, a ti rí àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi títí kan àwọn tó ní àìlera síbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. (mwb16.07 8) Kò sí àní-àní pé, ìsapá yòówù ká ṣe láti yin Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!—1Kr 16:25.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN TẸ̀GBỌ́N-TÀBÚRÒ MẸ́TA NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÒǸGÓLÍÀ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn ìṣòro wo làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta borí kí wọ́n lè di aṣáájú-ọ̀nà?
Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n rí?
Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì wo ni ọwọ́ wọn ti tẹ̀ torí pé wọ́n ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé?
Báwo ni àpẹẹrẹ wọn ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́?