August 17-23
Ẹ́KÍSÓDÙ 17-18
Orin 79 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́”: (10 min.)
Ẹk 18:17, 18—Jẹ́tírò rí i pé ẹrù tí Mósè ń dá gbé ti pọ̀ jù (w13 2/1 6)
Ẹk 18:21, 22—Jẹ́tírò gba Mósè níyànjú pé kó yan díẹ̀ lára iṣẹ́ rẹ̀ fáwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n (w03 11/1 6 ¶1)
Ẹk 18:24, 25—Mósè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jẹ́tírò (w02 5/15 25 ¶6)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 17:11-13—Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Áárónì àti Húrì? (w16.09 6 ¶14)
Ẹk 17:14—Kí nìdí táwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè kọ fi wà lára Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí Ọlọ́run? (it-1 406)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 17:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Kí la rí kọ́ nínú èsì tí Ladé fún Jùmọ̀kẹ́ nígbà tó sọ ohun tó rò nípa ipò táwọn òkú wà? Báwo ni Ladé ṣe ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì náà lọ́nà tó ṣe kedere?
Ìpadàbẹ̀wò: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 12)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Bíbélì Kọ́ wa, kó o sì fi ẹ̀kọ́ 6 bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 7)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (15 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 128
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 14 àti Àdúrà