Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní August: Ẹ lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? àti Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí: Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?, Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?, Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?, Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí? àti Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Ǹjẹ́ Ọ̀nà Ọlọ́run Ṣàǹfààní Lóòótọ́?”
◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ wo fídíò ‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ’ ní ìmúrasílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a máa ṣe ní ọ̀sẹ̀ August 17, 2015.