Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 7
Orin 3 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 30 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 12-15 (8 min.)
No. 1: 2 Àwọn Ọba 13:12-19 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Ìwé Mímọ́ Fi Sọ Pé Ká Bẹ̀rù Jèhófà—Diu. 5:29 (5 min.)
No. 3: Kí Ló Wà Nínú Oríṣiríṣi Ìwé Tó Para Pọ̀ Di Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì?—igw ojú ìwé 31 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣ. 24:15.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Dá Àwọn Ẹni Tuntun Lẹ́kọ̀ọ́.” Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
10 min: Ẹ̀yin Ìdílé, Ǹjẹ́ Ó Mọ́ Yín Lára Láti Máa Lọ sí Ìpàdé? Àsọyé tó dá lórí ìwé Hébérù 10:24, 25. Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ìdílé kan tó láwọn ọmọ. Kí ni olórí ìdílé náà máa ń ṣe tó fi hàn pé wíwá sí àwọn ìpàdé jẹ ìdílé òun lógún gan-an? Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máà ń ṣe kí ìdílé náà lè máa wá sí àwọn ìpàdé déédéé? Ìgbà wo ni wọ́n máa ń múra ohun tí wọ́n á sọ nípàdé sílẹ̀? Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ń yááfì kí wọ́n lè wà níbẹ̀? Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé déédéé kí wọ́n sì máa kópa níbẹ̀.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Fún Irúgbìn Òtítọ́ Bíbélì Sọ́kàn Àwọn Mọ̀lẹ́bí Rẹ? (Ìṣe 10:24, 33, 48) Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2015, ojú ìwé 87, ìpínrọ̀ 1 sí 2 àti ojú ìwé 90, ìpínrọ̀ 1 sí 3. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 118 àti Àdúrà