Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 31, 2015.
Òtítọ́ tó ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun wo la rí nípa Jèhófà Ọlọ́run nínú àdúrà Sólómọ́nì, àǹfààní wo ló sì máa ṣe wá tá a bá ń ṣàṣàrò lé e lórí? (1 Ọba 8:22-24, 28) [July 6, w05 7/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]
Báwo ni bí Dáfídì ṣe rìn “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà” ṣe jẹ́ ìṣírí fún wa láti ṣe bíi tirẹ̀? (1 Ọba 9:4) [July 13, w12 11/15 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 18 àti 19]
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú ìtàn nípa bí Jèhófà ṣe rán Èlíjà sí opó Sáréfátì? (1 Ọba 17:8-14) [July 27, w14 2/15 ojú ìwé 14]
Báwo ni ṣíṣàṣàrò lórí ìtàn tó wà ní 1 Àwọn Ọba 17:10-16 ṣe lè mú ká túbọ̀ pinnu pé a ó máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún? [July 27, w14 2/15 ojú ìwé 13 sí 15]
Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ Èlíjà ní ti bó ṣe kojú ìdààmú ọkàn? (1 Ọba 19:4) [Aug. 3, ia ojú ìwé 102 ìpínrọ̀ 10 sí 12; w14 3/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 15 àti 16]
Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tó rí bí Èlíjà wòlíì rẹ̀ adúróṣinṣin ṣe kárí sọ, báwo la sì ṣe lè fìwà jọ Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́? (1 Ọba 19:7, 8) [Aug. 3, w14 6/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 15 àti 16]
Èrò tí kò tọ́ wo ni Áhábù Ọba ní, báwo ni àwa Kristẹni lóde òní ṣe lè yẹra fún ṣíṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀? [Aug. 10, lv ojú ìwé 164 sí 165, àpótí; w14 2/1 ojú ìwé 14 sí 15 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tí Èlíṣà béèrè lọ́wọ́ Èlíjà, báwo sì lèyí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí wọ́n bá yan iṣẹ́ tuntun kan fún wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run? (2 Ọba 2:9, 10) [Aug. 17, w03 11/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5 àti 6]
Báwo ni àwọn ọmọdé ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ọmọdébìnrin ará Ísírẹ́lì tí ìwé 2 Àwọn Ọba 5:1-3 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? [Aug. 24, w12 2/15 ojú ìwé 12 sí 13 ìpínrọ̀ 11]
Àwọn ànímọ́ tí Jéhù ní wo ló yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà sapá láti ní lákòókò òpin yìí? (2 Ọba 10:16) [Aug. 31, w11 11/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]