Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November àti December: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí: Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?, Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?, Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?, Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí? àti Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
◼ Ọ̀sẹ̀ March 28 la máa sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2016. A máa ṣe ìfilọ̀ àkòrí àsọyé náà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tó bá ní àpéjọ àyíká tàbí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé wọn ní ọ̀sẹ̀ tó bá tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú March 28.