Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 30
Orin 94 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 3 ìpínrọ̀ 14 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 30, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 32 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 6-9 (8 min.)
No. 1: 2 Kíróníkà 6:22-27 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìṣàkóso Kristi Máa Mú Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Wá—wp14 4/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Mú Káwọn Èèyàn Máa Bọ̀wọ̀ fún Wa? (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.”—1 Kọ́r. 3:6.
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù December. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ méjì tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Lọni.” Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 141 àti Àdúrà
Ìránnilétí: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́kọ́ gbọ́ orin yìí lẹ́ẹ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ará kọ orin tuntun yìí.