ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍTÉRÌ 1-5
Ẹ́sítérì Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
Ẹ́sítérì lo ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tó gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run
Bí Ẹ́sítérì ṣe yọjú sí ọba láìjẹ́ pé ọba ló pè é lè yọrí sí ikú fún un. Ó ti tó oṣù kan tí ọba ti ránṣẹ́ pe Ẹ́sítérì gbẹ̀yìn
Onínúfùfù ni Ahasuwérúsì Ọba tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Sásítà Kìíní. Nígbà kan, ó ní kí wọ́n lọ bẹ́ ọkùnrin kan sí méjì kí wọ́n sì gbé e síbi táwọn èèyàn á ti rí i láti fi kìlọ̀ fún àwọn míì. Ó tún rọ ayaba Fáṣítì lóyè nígbà tó ṣàìgbọràn sí i
Ẹ́sítérì jẹ́ kí ọba mọ̀ pé Júù lòun, ó sì fi dá ọba lójú pé agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ tó fọkàn tán ti tàn án jẹ