ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 February ojú ìwé 7
  • February 29 Sí March 6

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • February 29 Sí March 6
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 February ojú ìwé 7

February 29 Sí March 6

Ẹ́SÍTÉRÌ 1-5

  • Orin 86 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Ẹ́sítérì Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run”: (10 min.)

    • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítérì.]

    • Es 3:5-9​—Hámánì fẹ́ pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run (ia ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 18 àti 19)

    • Es 4:11–5:2​—Ìgbàgbọ́ tí Ẹ́sítérì ní borí ìbẹ̀rù ikú (ia ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 2; ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 24 sí 26)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Es 2:15​—Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn? (w06 3/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7)

    • Es 3:2-4​—Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (ia ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 18)

    • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

    • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

  • Bíbélì Kíkà: Ẹst 1:1-15 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọ ẹnì kan. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.

  • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Ẹ jọ jíròrò ojú ìwé 2 àti 3. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi ojú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹni tó gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run nígbà àkọ́kọ́. (km 7/12 ojú ìwé 2 sí 3 ìpínrọ̀ 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 71

  • Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ: (10 min.)

  • Báwo Lo Ṣe Ń Jàǹfààní Nínú Ọ̀nà Tuntun Tá A Gbà Ń Ṣèpàdé àti Ìwé Ìpàdé?: (5 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nínú ìpàdé tuntun yìí. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n lè máa jàǹfààní gan-an nínú rẹ̀.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 10 ìpínrọ̀ 1 sí 11 àti àpótí tó wà lójú ìwé 86 (30 min.)

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 149 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́