Orin 71
Ẹ̀mí Mímọ́, Ẹ̀bùn Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọba, Baba aláàánú,
O ju ọkàn wa ẹlẹ́sẹ̀ lọ.
Jọ̀ọ́ mú ìdààmú ọkàn wa fúyẹ́,
Fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ tù wá nínú.
2. Baba, gbogbo wa kùnà ògo rẹ;
Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣìnà.
Ọlọ́run, a bẹ̀ ọ́: Jọ̀ọ́ fún wa ní
Ẹ̀mí rẹ, kó lè máa tọ́ wa sọ́nà.
3. Nígbà àárẹ̀ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì,
Ẹ̀mí rẹ yóò sọkàn wa dọ̀tun.
Jẹ́ ká lókun ìgòkè bí idì;
Jọ̀wọ́ fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ.
(Tún wo Sm. 51:11; Jòh. 14:26; Ìṣe 9:31.)