Ẹbun Ẹmi Mímọ́ Ti Jehofa
“Mélòó-mélòó ni Baba ti ń bẹ ni ọ̀run yoo fi ẹmi mímọ́ fun awọn wọnni ti ń beere lọwọ rẹ̀!”—LUUKU 11:13, NW.
1, 2. (a) Ileri wo ni Jesu ṣe nipa ẹmi mímọ́, eesitiṣe ti eyi fi jẹ́ atuni nínú nitootọ? (b) Ki ni ẹmi mímọ́ jẹ́?
NÍ ÌGBÀ ìwọ́wé ọdun 32 C.E. nigba ti Jesu ń waasu ihinrere ni Judia, ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa iwa-ọlawọ Jehofa. Ó lo awọn apejuwe alagbara melookan ó sì ṣe ileri agbayanu kan lẹhin naa, ni wiwi pe: “Bi ẹyin, bi ẹ tilẹ jẹ́ eniyan buruku, ba mọ bi a ti ń fi awọn ẹbun daradara fun awọn ọmọ yin, mélòó-mélòó ni Baba ti ń bẹ ni ọ̀run yoo fi ẹmi mímọ́ fun awọn wọnni ti ń beere lọwọ rẹ̀!”—Luuku 11:13, NW.
2 Ẹ wo iru itunu ti awọn ọrọ wọnyi jẹ́! Gẹgẹ bi a ti ń farada ipo ìrúkèrúdò ti awọn ọjọ ikẹhin ayé yii, ti a dojukọ ẹmi iṣọta Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀, ti a sì ń ba awọn itẹsi ara abẹ̀ṣẹ̀ tiwa funraawa jà, ó munilọkanyọ nitootọ lati mọ pe Ọlọrun yoo fun wa lokun nipasẹ ẹmi rẹ̀. Nitootọ, ifarada oloootọ kò ṣeeṣe laisi itilẹhin yẹn. Iwọ ha ti niriiri agbara ẹmi yii, eyi ti ó jẹ́ ipá agbekankanṣiṣẹ ti Ọlọrun funraarẹ bi? Iwọ ha loye bi o ti lè ran ọ lọwọ lọpọlọpọ tó bi? Iwọ ha ń lo o dé ẹkunrẹrẹ bi?
Agbara Ẹmi Mímọ́
3, 4. Ṣakawe agbara ẹmi mímọ́.
3 Kọkọ gbe agbara ẹmi mímọ́ yẹwo. Ronu sẹhin lọ si ọdun 1954. Ìgbà yẹn ni a yin bọmbu kan tí a kì pẹlu afẹfẹ hydrogen ṣe sori Erekuṣu Bikini ni Guusu Pacific. Lọgan lẹhin ti bọmbu naa búgbàù, erekuṣu ẹlẹwa yẹn ni òbíríkítí iná titobi nla bò tí a sì sọ di yánnayànna nipasẹ ìbúgbàù kan ti ó dọgba ni ipá pẹlu yíyin 15 million tọ́ọ̀nù oogun oloro TNT. Nibo ni gbogbo agbara aṣeparun yẹn ti wa? Ó jẹ́ iyọrisi yíyí kiki ìdá kekere kan ninu itanṣan olóró uranium ati afẹfẹ hydrogen pada si agbara ti o parapọ jẹ́ kìmí inu bọmbu naa. Bi o ti wu ki o ri, ki ni, bi awọn onimọ ijinlẹ bá lè ṣe odikeji ohun ti wọn ti ṣe aṣepari rẹ̀ ni Bikini? Ki a sọ pe wọn lè kó gbogbo agbara oníná yẹn jọpọ ki wọn sì yí i si iwọnba ìtànṣán olóró uranium ati afẹfeẹ hydrogen diẹ. Iru aṣeyọri wo ni iyẹn ìbá jẹ́! Sibẹ, Jehofa ṣe ohun kan ti o farajọra pẹlu iyẹn ṣugbọn ní iwọn ti o tobi lọna gígadabú nigba ti ‘[ó] dá ọrun oun ayé ni atetekọṣe.’—Jẹnẹsisi 1:1.
4 Jehofa ní ọpọ jaburata okun alagbara ti ń bẹ nipamọ. (Aisaya 40:26) Ni akoko iṣẹda, oun ti gbọdọ lo diẹ lara agbara yii nigba ti ó mu gbogbo ohun ti o parapọ di agbaye jade. Ki ni ó lò ninu igbokegbodo iṣẹda yii? Ẹmi mímọ́ ni. A ka pe: “Nipa ọ̀rọ̀ Oluwa [“Jehofa,” NW] ni a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa eemi ẹnu rẹ̀.” (Saamu 33:6) Akọsilẹ Jẹnẹsisi nipa iṣẹda sì ka pe: “Ẹmi Ọlọrun [ẹmi mímọ́] sì ń ràbàbà loju omi.” (Jẹnẹsisi 1:2) Iru ipá alagbara wo ni ẹmi mímọ́ jẹ́!
Awọn Iṣẹ Iyanu
5. Ni awọn ọna giga wo ni ẹmi mímọ́ ń gba ṣiṣẹ?
5 Ẹmi mímọ́ ṣì ń ṣiṣẹ ni awọn ọna giga sibẹ. Ó ń ṣe atọ́nà ó sì ń dari eto-ajọ Jehofa ti ọrun. (Esikiẹli 1:20, 21) Bii agbara ti bọmbu hydrogen mú jade, a lè lò ó lọna iṣeparun lati mu idajọ ṣẹ sori awọn ọta Jehofa, ṣugbọn ó tun ti ṣiṣẹ ni awọn ọna miiran ti ń ru wa soke lati ṣekayefi.—Aisaya 11:15; 30:27, 28; 40:7, 8; 2 Tẹsalonika 2:8.
6. Bawo ni ẹmi mímọ́ ṣe ti Mose ati awọn ọmọ Isirẹli lẹhin ninu awọn ibalo wọn pẹlu Ijibiti?
6 Fun apẹẹrẹ, ni nǹkan bii 1513 B.C.E., Jehofa ran Mose lati farahan niwaju Farao ti Ijibiti lati beere ominira fun awọn ọmọ Isirẹli. Fun 40 ọdun ti o ṣaaju, Mose ti jẹ́ oluṣọ-agutan ni Midiani, nitori naa eeṣe ti Farao fi nilati fetisilẹ si oluṣọ-agutan kan? Nitori pe Mose wá ni orukọ Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, Jehofa. Lati fẹri eyi han, Jehofa fun un lagbara lati ṣe awọn iṣẹ iyanu. Iwọnyi wọnilọkan tobẹẹ debi pe awọn alufaa Ijibiti ni a fipa mu lati gba pe: “Ika Ọlọrun ni eyi.”a (Ẹkisodu 8:19) Jehofa mu awọn ìyọnu ajakalẹ mẹwaa wá sori Ijibiti, ti eyi ti o kẹhin ninu rẹ̀ fipa mu Farao lati jẹ ki awọn eniyan Ọlọrun lọ kuro ni Ijibiti. Nigba ti Farao fi ìwarùnkì lepa wọn pẹlu ẹgbẹ́ ologun rẹ̀, awọn ọmọ Isirẹli yèbọ́ nigba ti ọna kan ṣi silẹ lọna iyanu gba inu Okun Pupa. Ẹgbẹ́ ologun Ijibiti tẹle wọn wọ́n sì rì sinu okun naa.—Aisaya 63:11-14; Hagai 2:4, 5.
7. (a) Ki ni awọn idi diẹ ti ẹmi mímọ́ fi ṣe awọn iṣẹ iyanu? (b) Bi o tilẹ jẹ pe awọn iṣẹ iyanu ti ẹmi mímọ́ ṣe kò ṣẹlẹ mọ, eeṣe ti akọsilẹ wọn ninu Bibeli fi ń tuni nínú?
7 Bẹẹni, Jehofa nipasẹ ẹmi rẹ̀ ṣe awọn iṣẹ iyanu alagbara nititori awọn ọmọ Isirẹli ni akoko Mose, ati ni awọn akoko miiran pẹlu. Ki ni ète awọn iṣẹ iyanu wọnni? Wọn gbé awọn ète Jehofa ga, mu ki orukọ rẹ̀ di mímọ̀, wọn sì ṣaṣefihan agbara rẹ̀. Ati nigba miiran, gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Mose, wọn fihan lọna aiṣiyemeji pe ẹnikọọkan ní itilẹhin Jehofa. (Ẹkisodu 4:1-9; 9:14-16) Bi o ti wu ki o ri, awọn iṣẹ iyanu ti a ṣe nipasẹ ẹmi mímọ́ jalẹjalẹ itan kò wọ́pọ̀ rara.b O ṣeeṣe pe, ọpọjulọ awọn ẹnikọọkan ti ń gbé ni awọn akoko ti a kọ Bibeli kò ri ọ̀kan ri, wọn kò si tun ṣẹlẹ mọ́ lonii. Sibẹ, gẹgẹ bi awa lonii ti ń wọ̀jà pẹlu awọn iṣoro ti o lè dabi alaiṣeebori, kò ha tuni ninu lati mọ pe bi a ba fi igbagbọ beere lọwọ Jehofa, oun yoo fun wa ni ẹmi kan naa ti ó ti Mose lẹhin niwaju Farao ti ó sì ṣí ọna kan silẹ fun awọn ọmọ Isirẹli la Okun Pupa naa ja bi?—Matiu 17:20.
Awọn Ikọwe Onimiisi
8. Ki ni ipa tí ẹmi mímọ́ kó ninu fifunni ni Ofin Mẹwaa?
8 Lẹhin idande wọn kuro ni Ijibiti, Mose ṣamọna awọn ọmọ Isirẹli lọ sori Oke Sinai, nibi ti Jehofa ti dá majẹmu kan pẹlu wọn ti ó sì fun wọn ni Ofin rẹ̀. Apa pataki ninu Ofin yẹn ti a fifunni nipasẹ Mose ni Ofin Mẹwaa, ẹ̀dà ipilẹṣẹ iwọnyi ni a sì kọ sara wàláà okuta. Lọna wo? Nipasẹ ẹmi mímọ́. Bibeli wi pe: “Ó sì fi wàláà ẹ̀rí meji, wàláà okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigba ti o [Jehofa] pari ọrọ biba a sọ tan lori Oke Sinai.”—Ẹkisodu 31:18; 34:1.
9, 10. Bawo ni ẹmi mímọ́ ṣe ṣiṣẹ ninu kíkọ Iwe Mimọ lede Heberu, bawo sì ni eyi ṣe han kedere lati inu awọn ọrọ ti awọn ọmọ-ẹhin Jesu lò?
9 Ni afikun si Ofin Mẹwaa, Jehofa nipasẹ ẹmi rẹ̀ fun Isirẹli ni ọgọrọọrun awọn ofin ati ilana lati tọ́ igbesi-aye awọn ọkunrin ati obinrin onigbagbọ sọna. Ọpọ sii ṣi ni ó sì tun ń bọ̀. Ọpọ ọrundun lẹhin ọjọ Mose, awọn ọmọ Lefi jẹrii ninu adura gbangba si Jehofa pe: “Ọpọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suuru fun [awọn ọmọ Isirẹli] ti o sì fi ẹmi rẹ jẹrii gbe wọn ninu awọn wolii rẹ.” (Nehemaya 9:5, 30) Ọpọlọpọ awọn asọtẹlẹ onimiisi tí awọn wolii wọnni sọ ni a kọsilẹ. Siwaju sii, ẹmi mímọ́ sún awọn ọkunrin oluṣotitọ lati kọ awọn ìtàn mímọ́ ati awọn orin iyin atọkanwa silẹ.
10 Pọọlu ń sọrọ nipa gbogbo awọn ikọwe wọnyi nigba ti o wi pe: “Gbogbo Iwe mímọ́ ni Ọlọrun mísí.” (2 Timoti 3:16, NW; 2 Samuẹli 23:2; 2 Peteru 1:20, 21) Nitootọ, nigba ti wọn bá ń ṣayọlo awọn iwe mímọ́ yii, awọn ọmọ-ẹhin Jesu ní ọrundun kìn-ín-ní saba maa ń lo awọn ọrọ bii “ẹmi mímọ́ . . . sọtẹlẹ lati ẹnu Dafidi,” “ẹmi mímọ́ sọrọ lọna ti ó ṣe wẹku nipa wolii Aisaya,” tabi “ẹmi mímọ́ . . . wí.” (Iṣe 1:16; 4:25; 28:25, 26, NW; Heberu 3:7) Anfaani wo ni o ti jẹ pe ẹmi mímọ́ kan naa ti o ti nipa lori kikọ Iwe Mimọ ti tọju wọn pamọ ki wọn baa lè tọ́ wa sọ́nà ki wọn sì tù wá nínú lonii!—1 Peteru 1:25.
Ìgbáralé Ẹmi Mímọ́
11. Igbokegbodo ẹmi wo ni a ri niti kíkọ́ àgọ́-ìsìn?
11 Nigba ti a pàgọ́ awọn ọmọ Isirẹli si ẹsẹ Oke Sinai, Jehofa paṣẹ fun wọn lati kọ́ àgọ́-ìsìn kan gẹgẹ bi ọgangan idari fun ijọsin tootọ. Bawo ni wọn ṣe lè ṣaṣepari eyi? “Mose sì wi fun awọn ọmọ Isirẹli pe, Wò ó OLUWA [“Jehofa,” NW] ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ni orukọ. O si fi ẹmi Ọlọrun kun un ni ọgbọn, ni oye, ni ìmọ̀, ati ni oniruuru iṣẹ-ọna.” (Ẹkisodu 35:30, 31) Ẹmi mímọ́ tubọ fun oye iṣẹ yoowu ki Besaleli lè ní lokun, oun sì lè bojuto ìgbénàró ile pipẹtẹri yẹn lọna aṣeyọrisirere.
12. Bawo ni ẹmi ṣe fun awọn ẹnikọọkan lokun ni awọn ọna ara-ọtọ lẹhin akoko Mose?
12 Ni akoko kan lẹhin naa, ẹmi Jehofa di eyi ti ó ṣiṣẹ lori Samusini, ní fifun un ní okun ti o ju ti ẹda lọ lati jẹ́ ki o lè dá Isirẹli nídè kuro lọwọ awọn ara Filisitini. (Onidaajọ 14:5-7, 9; 15:14-16; 16:28-30) Sibẹsibẹ lẹhin naa, Solomọni ni a yọọda ọgbọn akanṣe fun gẹgẹ bi ọba awọn eniyan tí Ọlọrun yàn. (2 Kironika 1:12, 13) Labẹ rẹ̀, Isirẹli laasiki ju ti igbakigba ri lọ, ipo ayọ rẹ̀ sì di apẹẹrẹ fun awọn ibukun tí awọn eniyan Ọlọrun yoo gbadun labẹ Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun Kristi Jesu, Solomọni Titobiju naa.—1 Ọba 4:20, 25, 29-34; Aisaya 2:3, 4; 11:1, 2; Matiu 12:42.
13. Bawo ni akọsilẹ nipa fifun ti ẹmi fun Besaleli, Samusini, ati Solomọni lokun ṣe fun wa niṣiiri lonii?
13 Ibukun wo ni ó jẹ́ pe Jehofa mu ki ẹmi kan naa wà larọọwọto fun wa! Nigba ti a ba nimọlara aitootun lati mu iṣẹ ayanfunni kan ṣẹ tabi lọwọ ninu iṣẹ iwaasu, a lè sọ fun Jehofa pe ki o fun wa ni ẹmi kan naa ti ó fun Besaleli. Nigba ti a ba jiya amodi tabi farada inunibini, ẹmi kan naa ti o fun Samusini ní okun ara-ọtọ yoo fun wa lokun—àmọ́ ṣá, kii ṣe lọna iṣẹ iyanu. Nigba ti a ba sì dojukọ awọn iṣoro lilekoko tabi ti a nilati ṣe awọn ipinnu pataki, a lè sọ fun Jehofa, ẹni ti o fun Solomọni ni ọgbọn ara-ọtọ, lati ràn wá lọ́wọ́ lati gbegbeesẹ lọna ọgbọn. Lẹhin naa, bii Pọọlu, awa yoo sọ pe: “Mo ni okun fun ohun gbogbo nipa agbara oun ẹni ti ń fi agbara fun mi.” (Filipi 4:13, NW) Ileri Jakọbu yoo si ṣee fisilo fun wa pe: “Bi o ba ku ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o beere lọwọ Ọlọrun, ẹni tii fi fun gbogbo eniyan ni ọpọlọpọ, ti kii sìí baniwi; a o sì fifun un.”—Jakobu 1:5.
14. Awọn wo, ni awọn akoko igbaani ati lonii, ni a ti tilẹhin nipa ẹmi mímọ́?
14 Ẹmi Jehofa tun wà lori Mose ninu iṣẹ rẹ̀ ti ṣiṣedajọ orilẹ-ede naa. Nigba ti a yan awọn miiran lati ran Mose lọwọ, Jehofa wi pe: “Emi yoo sì mu ninu ẹmi ti ń bẹ lara rẹ, emi yoo sì fi i sara wọn; wọn yoo sì maa bá ọ ru ẹrù awọn eniyan naa, ki iwọ ki o maṣe nikan rù ú.” (Numeri 11:17) Nipa bayii, awọn ọkunrin wọnni ni kò nilati gbegbeesẹ pẹlu okun tiwọn funraawọn. Ẹmi mímọ́ tì wọ́n lẹhin. Nigba ti o yá ní awọn akoko miiran a kà pe ẹmi Jehofa wà lori awọn ẹniyan miiran. (Onidaajọ 3:10, 11; 11:29) Nigba ti Samuẹli fororo yan Dafidi gẹgẹ bi ọba Isirẹli, akọsilẹ naa sọ pe: “Samuẹli mú ìwo ororo, o sì fi yà á si ọtọ laaarin awọn arakunrin rẹ̀; ẹmi Oluwa sì bà le Dafidi lati ọjọ naa lọ.” (1 Samuẹli 16:13) Awọn wọnni ti wọn ni ẹru-iṣẹ wiwuwo lonii—ti idile, ijọ, tabi ti eto-ajọ—ni a lè tù ninu lati mọ pe ẹmi Ọlọrun ṣì ń ti awọn iranṣẹ rẹ̀ lẹhin gẹgẹ bi wọn ti ń bojuto iṣẹ aigbọdọmaṣe wọn.
15. Ni ọna wo ni ẹmi mímọ́ gba fun eto-ajọ Jehofa lokun (a) ni awọn ọjọ Hagai ati Sekaraya? ati (b) lonii?
15 Ọpọ ẹgbẹrun ọdun melookan lẹhin ọjọ Mose, awọn oluṣotitọ lati inu awọn ọmọ Isirẹli pada si Jerusalẹmu lati Babiloni pẹlu aṣẹ naa lati tun tẹmpili kọ́. (Ẹsira 1:1-4; Jeremaya 25:12; 29:14) Bi o ti wu ki o ri, idena lilekoko dide, a sì kó irẹwẹsi bá wọn fun ọpọlọpọ ọdun. Nikẹhin, Jehofa gbé wolii Hagai ati wolii Sekaraya dide lati fun awọn Juu niṣiiri lati maṣe gbarale okun tiwọn funraawọn. Ṣugbọn bawo ni a o ṣe ṣaṣepari iṣẹ naa? “Kii ṣe nipa ipá, kii ṣe nipa agbara, bikoṣe nipa ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.” (Sekaraya 4:6) Ati pẹlu itilẹhin ẹmi Ọlọrun, tẹmpili naa ni a kọ́. Awọn eniyan Ọlọrun ti ṣaṣepari ọpọjulọ bakan naa lonii. Iwaasu ihinrere ti tankalẹ yika ilẹ-aye. Araadọta-ọkẹ awọn eniyan ni a ń kọ́ lẹkọọ ninu otitọ ati ododo. Awọn apejọpọ ni a ṣetojọ. Awọn Gbọngan Ijọba ati awọn ọfiisi ẹka ni a ń kọ́. Ọpọjulọ eyi ni a ti ṣe ni oju atako mimuna. Ṣugbọn awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kò mú rẹwẹsi, ni mímọ pe ohun gbogbo ti wọn ti ṣaṣepari rẹ̀ ti jẹ́, kii ṣe nipasẹ ipá ologun, tabi agbara eniyan, ṣugbọn nipasẹ ẹmi Ọlọrun.
Ẹmi Ọlọrun ní Ọrundun Kìn-ín-ní
16. Iriri wo ni awọn iranṣẹ Jehofa ṣaaju akoko Kristẹni ní pẹlu igbokegbodo ẹmi Ọlọrun?
16 Gẹgẹ bi a ti ri i, awọn iranṣẹ Ọlọrun ṣaaju akoko Kristẹni mọ nipa agbara ẹmi Ọlọrun daradara. Wọn gbarale e lati ràn wọ́n lọ́wọ́ lati mu awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe wiwuwo ṣẹ ati lati ṣaṣepari ifẹ-inu Ọlọrun. Wọn tun mọ pe Ofin naa ati awọn ikọwe mímọ́ miiran ni a misi, ti a kọ labẹ agbara idari ẹmi Jehofa, ati nipa bayii wọn jẹ́ ‘Ọrọ Ọlọrun.’ (Saamu 119:105) Bi o ti wu ki o ri, ki ni niti sanmani Kristẹni?
17, 18. Ki ni diẹ lara awọn ifihan oniṣẹ iyanu ti ẹmi ni sanmani Kristẹni, ète wo ni o sì ṣiṣẹ fun?
17 Ọrundun kìn-ín-ní ninu Sanmani Tiwa tun ri awọn agbayanu igbokegbodo ẹmi Ọlọrun. Isọtẹlẹ onimiisi ẹmi ń bẹ. (1 Kọrinti 14:1, 3) Ni imuṣẹ ileri Jesu pe ẹmi mímọ́ yoo rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leti gbogbo awọn ohun ti ó ti sọ ati pe yoo kọ́ wọn ni awọn ìhà otitọ siwaju sii, ọpọlọpọ awọn iwe ni a kọ labẹ agbara idari ẹmi mímọ́. (Johanu 14:26; 15:26, 27; 16:12, 13) Awọn iṣẹ iyanu ń bẹ pẹlu, gẹgẹ bi a o ti jiroro lẹkun-unrẹrẹ sii ninu ọrọ-ẹkọ wa ti ó tẹle e. Nitootọ, ọrundun kìn-ín-ní ni a muwọlede nipasẹ iṣẹ iyanu pipẹtẹri kan. Ni nǹkan bi ọdun 2 B.C.E., ọmọ-ọwọ akanṣe kan ni a o bi, ati gẹgẹ bi àmì kan, iya rẹ̀ ọdọ ni o nilati jẹ́ wundia. Bawo ni eyi ṣe lè ri bẹẹ? Nipasẹ ẹmi mímọ́. Akọsilẹ naa sọ pe: “Bi ìbí Jesu Kristi ti ri niyi: ni akoko ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josẹfu, ki wọn to pade, a ri i, ó loyun lati ọwọ́ ẹmi mímọ́ wá.”—Matiu 1:18; Luuku 1:35, 36.
18 Nigba ti Jesu dagba, ó lé awọn ẹmi eṣu jade, mu awọn alaisan larada, o tilẹ ji oku dide paapaa ni agbara ẹmi mímọ́. Diẹ lara awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tun ṣe awọn iṣẹ iyanu ati iṣẹ alagbara. Awọn agbara akanṣe wọnyi jẹ́ ẹbun ẹmi mímọ́. Ki ni ète wọn? Gan-an gẹgẹ bi awọn iṣẹ iyanu iṣaaju ti ṣe, wọn gbe ète Ọlọrun ga wọn sì ṣipaya agbara rẹ̀. Ju bẹẹ lọ, wọn ṣaṣefihan ijoootọ ọrọ ti Jesu fi idaloju sọ pe oun ni a rán lati ọdọ Ọlọrun; ati lẹhin naa, wọn fẹri han pe ijọ Kristẹni ọrundun kìn-ín-ní jẹ́ orilẹ-ede ti Ọlọrun yàn.—Matiu 11:2-6; Johanu 16:8; Iṣe 2:22; 1 Kọrinti 12:4-11; Heberu 2:4; 1 Peteru 2:9.
19. Bawo ni a ṣe fun igbagbọ wa lokun nipasẹ akọsilẹ Bibeli nipa awọn iṣẹ iyanu Jesu ati awọn apọsiteli rẹ?
19 Bi o ti wu ki o ri, apọsiteli Pọọlu wi pe iru awọn ifihansode oniṣẹ iyanu ti ẹmi bẹẹ jẹ́ ti igba ọmọde ijọ naa ati pe yoo kọja lọ, nitori naa lonii awa kò rí iru iṣẹ iyanu bẹẹ tí ẹmi mímọ́ ṣe. (1 Kọrinti 13:8-11) Sibẹ, awọn iṣẹ iyanu tí Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ ṣe ní ju anfaani onitan lọ. Wọn fun igbagbọ wa ninu ileri Ọlọrun lokun pe ko ní sí àyè fun aisan ati iku labẹ iṣakoso Jesu ninu ayé titun.—Aisaya 25:6-8; 33:24; 65:20-24.
Janfaani Lati Inu Ẹmi Mímọ́ Ọlọrun
20, 21. Bawo ni a ṣe le mu araawa wà larọọwọto fun ipese ẹmi mímọ́?
20 Ẹ wo iru ipá alagbara ti ẹmi yii jẹ́! Ṣugbọn bawo ni awọn Kristẹni lonii ṣe lè mu un lò? Lakọọkọ, Jesu sọ pe a nilati beere fun un, nitori naa eeṣe ti iwọ kò fi ṣe iyẹn gan-an? Gbadura si Jehofa lati fun ọ ni ẹbun agbayanu yii kii ṣe kiki ni awọn akoko inira ṣugbọn ni gbogbo akoko. Ni afikun, ka Bibeli ki ẹmi mímọ́ baa lè ba ọ sọrọ. (Fiwe Heberu 3:7.) Ronu jinlẹ lori ohun ti o kà ki o sì fi i silo ki ẹmi mímọ́ baa lè jẹ́ agbara idari kan ninu igbesi-aye rẹ. (Saamu 1:1-3) Siwaju sii, kẹgbẹpọ—lẹnikọọkan, ninu ijọ ati ni awọn apejọ—pẹlu awọn ẹlomiiran ti wọn gbarale ẹmi Ọlọrun. Bawo ni ẹmi mímọ́ ti fi okun fun awọn wọnni ti wọn bukun fun Ọlọrun wọn “ni apejọpọ awọn eniyan” lọna jingbinni tó!—Saamu 68:26, NW.
21 Jehofa kii ha iṣe Ọlọrun ọlawọ bi? Ó sọ pe ki a saa ti beere fun ẹmi mímọ́ oun yoo sì fifun wa. Bawo ni o ti jẹ́ iwa oponu tó lati gbarale ọgbọn ati okun tiwa funraawa nigba ti iru iranlọwọ alagbara bẹẹ wà ni àrọ́wọ́tó wa! Bi o ti wu ki o ri, awọn ọran miiran ti o niiṣe pẹlu ẹmi Ọlọrun ti o nipa lori wa gẹgẹ bi Kristẹni wà, iwọnyi ni a o sì jiroro ninu ọrọ-ẹkọ ti ó kàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọrọ naa “ika Ọlọrun” saba maa ń tọka si ẹmi mímọ́.—Fiwe Luuku 11:20 ati Matiu 12:28.
b Ọpọjulọ awọn iṣẹ iyanu ti a ṣakọsilẹ ninu Bibeli ṣẹlẹ lakooko Mose ati Joṣua, Elija ati Eliṣa, ati Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀.
Iwọ Ha Lè Dahun Awọn Ibeere Ti Wọn Tẹle e Yii Bi?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe da gbogbo ohun ti o di agbaye?
◻ Awọn ọna diẹ wo ni ẹmi mímọ́ gbà ṣiṣẹ ṣaaju awọn akoko Kristẹni?
◻ Bawo ni o ṣe tù wá nínú lonii lati mọ ohun ti ẹmi mímọ́ ṣaṣepari ni awọn akoko igbaani?
◻ Bawo ni a ṣe lè mu araawa wà larọọwọto fun ipese ẹmi mimọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹmi naa ti ó fun Samusini ni okun ti o rekọja ti eniyan lè fun wa ni agbara fun ohun gbogbo