Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
Ọ̀SẸ̀ JULY 4 SÍ 10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 60-68
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Mú Ìlérí Rẹ Ṣẹ?
Mímú Ìlérí Táa Bá Ọlọ́run Ṣe Ṣẹ
Kò sí àní-àní pé yíya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ táa ṣe. Nípa gbígbé ìgbésẹ̀ yìí, a fi hàn pé a fẹ́ sin Jèhófà títí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin Ọlọ́run ò nira, ó lè má rọrùn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo, báa ti ń gbé nínú ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí. (2 Tímótì 3:12; 1 Jòhánù 5:3) Ṣùgbọ́n, gbàrà tí a ‘bá ti fi ọwọ́ wa lé ohun ìtúlẹ̀,’ tí a ti di ìránṣẹ́ tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, tí a sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ tún máa wo àwọn nǹkan ti ayé tí a ti fi sílẹ̀.—Lúùkù 9:62.
Nígbà táa bá gbàdúrà sí Jèhófà, ohun kan lè sún wa láti ṣèlérí fún un pé a ó jìjàkadì láti borí ìkùdíẹ̀-káàtó kan, pé a ó mú ànímọ́ Kristẹni kan dàgbà, tàbí pé a ó mú apá kan nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìlérí wọ̀nyí ṣẹ?—Fi wé Oníwàásù 5:2-5.
Látinú ọkàn-àyà ẹni àti èrò ẹni ni ojúlówó ìlérí ti ń wá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a mú kí àwọn ìlérí táa bá Jèhófà ṣe fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nípa ṣíṣí ọkàn-àyà wa payá fún un nínú àdúrà, nípa sísọ ohun tó ń bà wá lẹ́rù jáde láìfòyà, ká sọ ohun táa fẹ́, àti àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa, láìfi ohunkóhun pa mọ́. Gbígbàdúrà nípa ìlérí táa ṣe yóò fún wa lókun láti mú un ṣẹ. A lè ka ìlérí táa bá Ọlọ́run ṣe sí gbèsè. Tí gbèsè bá pọ̀, ó yẹ ká máa san án díẹ̀díẹ̀. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìlérí táa ṣe fún Jèhófà ni yóò gba àkókò ká tó lè mú un ṣẹ tán. Ṣùgbọ́n nípa fífún un ní ohun tí a bá lè fún un déédéé, a ń fi hàn pé a ṣe tán láti mú ìlérí wa ṣẹ, òun yóò sì bù kún wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
A lè fi hàn pé a kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlérí wa nípa gbígbàdúrà nípa rẹ̀ léraléra, bóyá lójoojúmọ́ pàápàá. Èyí yóò jẹ́ kí Baba wa ọ̀run mọ̀ pé ó jẹ wá lọ́kàn. Yóò tún jẹ́ ìránnilétí ìgbà gbogbo. Dáfídì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa èyí. Nínú orin, ó bẹ Jèhófà pé: “Gbọ́ igbe ìpàrọwà mi, Ọlọ́run. Fetí sí àdúrà mi. . . . Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ títí láé, kí n lè san àwọn ẹ̀jẹ́ mi ní ọjọ́ dé ọjọ́.”—Sáàmù 61:1, 8.
Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo!
Ó ṢE PÀTÀKÌ KÁ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ TÁ A BÁ MÁA NÍ ÀJỌṢE PẸ̀LÚ RẸ̀
6 Ǹjẹ́ o lè gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìṣòro kan tó ń kó ìdààmú bá ẹ, kí ọkàn ẹ sì wá balẹ̀ lẹ́yìn náà, torí o mọ̀ pé o ti ṣe ohun tó yẹ kó o ṣe nípa ọ̀ràn náà àti pé Jèhófà máa yanjú èyí tó kù? Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Sáàmù 62:8; 1 Pétérù 5:7.) Ó yẹ kó o kọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó ṣe pàtàkì tí o bá fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Síbẹ̀, ó lè ṣòro nígbà míì láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè ohun tó o nílò. Kí nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà lójú ẹsẹ̀.—Sm. 13:1, 2; 74:10; 89:46; 90:13; Háb. 1:2.
7 Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa ń dáhùn lójú ẹsẹ̀? Má gbàgbé pé Ọlọ́run fi àjọṣe àwa àti òun wé àjọṣe tó máa ń wà láàárín ọmọ àti baba. (Sm. 103:13) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan ò le retí pé kí òbí òun fún òun ní gbogbo nǹkan tí òun bá ṣáà ti béèrè tàbí kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà míì ọmọdé lè béèrè ohun kan torí ó kàn wù ú. Àwọn nǹkan míì sì máa gba pé kí ọmọ náà ṣe sùúrù díẹ̀ títí ó fi máa tó àkókò lójú òbí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọ náà lè béèrè nǹkan míì tó lè ṣe ìpalára fún un tàbí kó ṣàkóbá fún àwọn ẹlòmíì. Síwájú sí i, tó bá jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni òbí kan máa ń fún ọmọ rẹ̀ ní gbogbo ohun tó bá béèrè, a jẹ́ pé òbí náà ti di ẹrú ọmọ náà nìyẹn, ọmọ náà sì ti di ọ̀gá. Bákan náà, Jèhófà lè rí i pé ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù ni pé kí àkókò díẹ̀ kọjá kó tó dáhùn àwọn àdúrà kan. Òun ló láṣẹ láti ṣèpinnu yẹn torí pé òun ní Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, Ọ̀gá tó nífẹ̀ẹ́ wa àti Baba wa ọ̀run. Tó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan tá à ń béèrè náà ni Jèhófà ń ṣe fún wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ìyẹn lè sọ àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín wa dìdàkudà.—Fi wé Aísáyà 29:16; 45:9.
8 Nǹkan míì ni pé, Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ. (Sm. 103:14) Nítorí náà, kò retí pé ká máa dá fara da àwọn ìṣòro wa, àmọ́ ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ torí òun ni baba wa. Òótọ́ ni pé, ìgbà míì máa ń wà tó máa ń ṣe wá bíi pé agbára wa ti pin. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé òun kò ní jẹ́ kí ìyà tó ju agbára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ jẹ wọ́n. Ó dájú pé ó máa “ṣe ọ̀nà àbájáde.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.) Nítorí náà, kò sí àní-àní pé Jèhófà mọ̀ wá lóòótọ́, ó mọ ibi tí agbára wa mọ.
9 Tá ò bá rí ìtura lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn tá a gbàdúrà, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù, ká máa wojú Ẹni tó mọ ìgbà tó dára jù lọ láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ó wu Ọlọ́run gan-an láti ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ó ń mú sùúrù dìgbà tó dáa jù láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ [òdodo]. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.”—Aísá. 30:18.
w15 4/15 ojú ìwé 22-23 ìpínrọ̀ 13-14
Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Ní Àjọṣe Tó Dán Mọ́rán Pẹ̀lú Jèhófà?
13 Rò ó wò ná: Kí Jésù tó wá sáyé, ó ti máa ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àdúrà ló fi ń bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀. Ká sọ pé Jèhófà kì í gbọ́ àdúrà ni, ǹjẹ́ Jésù máa gbàdúrà sí i rárá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé ó tún lo gbogbo òru ọjọ́ kan láti gbàdúrà sí i? (Lúùkù 6:12; 22:40-46) Ǹjẹ́ ó máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà ká sọ pé oògùn amáratuni lásán ni àdúrà jẹ́? Ó ṣe kedere pé Jésù mọ̀ pé Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Nígbà kan Jésù sọ pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, èmi mọ̀ pé ìwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo.” Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.”—Jòh. 11:41, 42; Sm. 65:2.
14 Tí àdúrà rẹ bá ṣe pàtó, ìdáhùn Jèhófà sí àdúrà rẹ á ṣe kedere sí ẹ, kódà bí kò tiẹ̀ hàn sójú táyé. Bí o bá sì ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà rẹ ni á túbọ̀ máa jẹ́ ẹni gidi sí ẹ. Bákan náà, bí o ṣe túbọ̀ ń sọ ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn fún Jèhófà, á máa sún mọ́ ẹ sí i.
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Láti Sin Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I
10 Ọ̀nà kejì tó o lè gbà mú kí ìfẹ́ tó o ní láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn jinlẹ̀ sí i ni pé kó o máa gbàdúrà. Nínú Sáàmù 65:2, a kà pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.” Kódà lákòókò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà lè gbàdúrà sí Ọlọ́run. (1 Ọba 8:41, 42) Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Ó dá àwọn tó ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ lójú pé ó máa gbọ́ tiwọn. (Òwe 15:8) Ó dájú pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ náà wà lára “àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo.”
it-2 p. 668 Àdúrà
Àwọn Tí Ọlọ́run Gbọ́ Àdúrà Wọn. Gbogbo èèyàn ẹlẹ́ran ara ló làǹfààní láti tọ Jèhófà Ọlọ́run “Olùgbọ́ àdúrà,” lọ. (Sm 65:2; Ise 15:17) Kódà nígbà Jèhófà ṣì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí “dúkìá àdáni” rẹ̀ tàbí àwọn èèyàn tó bá dá májẹ̀mú, àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wá sínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù lè gbàdúrà tàbí rúbọ sí i. (Di 9:29; 2Ki 6:32, 33; fi wé Aísá 19:22.) Nígbà tó yá, ikú Kristi fi mú yàtọ̀ tó wà hàn nínú Júù àti Kèfèrí kúrò pátápátá. (Efé 2:11-16) Bí àpẹẹrẹ, Pétérù fi èyí hàn ní ilé Kònílíù, nígbà tó sọ pé “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ise 10:34, 35) A jẹ́ pé ohun tó ń pinnu ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ni bí ọkàn ẹni ṣe rí àti ohun tí ọkàn rẹ̀ ń sún un láti ṣe. (Sm 119:145; Ida 3:41) Gbogbo ẹni tó bá pa àṣe Ọlọ́run mọ́ tó sì ń ṣe “àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀” máa ní ìdáni lójú pé “etí” rẹ̀ á ṣí sí ohun tí àwọn bá ń sọ fún un.—1Jo 3:22; Sm 10:17; Owe 15:8; 1Pe 3:12.
w06 6/1 ojú ìwé 11 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kejì Sáàmù
63:3. ‘Inú rere onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run sàn ju ìyè,’ nítorí pé láìsí i, òtúbáńtẹ́ ni ìgbésí ayé èèyàn. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́.
w06 6/1 ojú ìwé 10 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kejì Sáàmù
68:18—Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? Àwọn wọ̀nyí làwọn ọkùnrin tó wà lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lákòókò tí wọ́n jagun tí wọ́n fi gba Ilẹ̀ Ìlérí. Wọ́n wá yan irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn.—Ẹ́sírà 8:20.
Ọ̀SẸ̀ JULY 11 SÍ 17
w10 12/15 ojú ìwé 7-11 ìpínrọ̀ 2-17
Ẹ Jẹ́ Onítara Fún Ìjọsìn Tòótọ́
2 Kò sí iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní tó kọjá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Nígbà tí Máàkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù, ó kọ̀wé pé iṣẹ́ yìí la gbọ́dọ̀ “kọ́kọ́” ṣe, ìyẹn ni pé ṣáájú kí òpin tó dé. (Máàkù 13:10) Bó sì ṣe yẹ kó rí gan-an nìyẹn. Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.” Ìkórè kò ṣeé sọ di ìgbà míì; àfi kéèyàn kórè kí àkókò ìkórè tó kọjá lọ.—Mát. 9:37.
3 Tá a bá ro ti bí iṣẹ́ ìwàásù náà ti ṣe pàtàkì sí wa tó, a ó máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nípa rẹ̀, a ó sì máa lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ náà débi tí agbára wa bá gbé e dé. A gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe gan-an nìyẹn. Àwọn kan ti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì tàbí kí wọ́n lọ sìn ní ọ̀kan lára àwọn Bẹ́tẹ́lì tá a ní káàkiri ayé. Wọ́n máa ń ní ohun púpọ̀ láti ṣe nígbà gbogbo. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan, kí wọ́n sì máa dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Síbẹ̀, Jèhófà ń bù kún wọn lọ́pọ̀ yanturu. A bá wọn yọ̀! (Ka Lúùkù 18:28-30.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún àwọn míì láti di ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, síbẹ̀ wọ́n ń lo àkókò wọn débi tí agbára wọn bá gbé e dé lẹ́nu iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà, èyí sì tún kan ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—Diu. 6:6, 7.
4 Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé bí ohun kan bá jẹ́ kánjúkánjú, a gbọ́dọ̀ mọ bí àkókò tó máa gbà ṣe pọ̀ tó àti ìgbà tó máa dópin. Àkókò òpin là ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló sì wà nínú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ohun tí ìtàn sọ, tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:3, 33; 2 Tím. 3:1-5) Síbẹ̀, kò sí èèyàn kankan tó mọ àkókò pàtó tí òpin máa dé. Nígbà tí Jésù ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa “àmì” tó máa fi hàn pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó jẹ́ kó ṣe kedere pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mát. 24:36) Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó lè ṣòro fún àwọn kan láti máa fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, àgàgà tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ń bá a bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Òwe 13:12) Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ nígbà míì? Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fẹ́ ká máa ṣe lóde òní tàbí tí kò ní jẹ́ ká dẹ́kun láti máa ṣe é?
Gbé Àpẹẹrẹ Jésù Tó Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ Wa Yẹ̀ Wò
5 Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ ni Jésù Kristi jẹ́ lára gbogbo àwọn tó fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ìdí tó fi fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ náà ni pé ó ní ohun púpọ̀ láti gbé ṣe láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ péré. Síbẹ̀, kò tíì sí ẹnikẹ́ni tó ṣe ohun tó pọ̀ tó ohun tí Jésù gbé ṣe tó bá dọ̀ràn ìjọsìn tòótọ́. Ó sọ orúkọ Bàbá rẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe di mímọ̀, ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó túdìí àṣírí àgàbàgebè àti ẹ̀kọ́ èké àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ó sì fi hàn pé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run lòun fara mọ́, kódà títí dójú ikú. Ó ṣe gudugudu méje lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn, ríràn wọ́n lọ́wọ́ àti wíwò wọ́n sàn, jákèjádò ilẹ̀ náà. (Mát. 9:35) Kò sẹ́ni tó ṣiṣẹ́ ribiribi tó tó èyí tí Jésù ṣe yìí láàárín àkókò kúkúrú. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà.—Jòh. 18:37.
6 Kí nìdí tí Jésù kò fi káàárẹ̀ títí tó fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Látinú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ó ṣeé ṣe kí Jésù ti mọ ìgbà tí Jèhófà fẹ́ kí òun parí iṣẹ́ náà. (Dán. 9:27) Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ó yẹ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé parí “ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà” tàbí ní ẹ̀yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀. Kété lẹ́yìn tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sọ pé: “Wákàtí náà ti dé tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.” (Jòhánù 12:23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé ikú òun ti sún mọ́lé, kò jẹ́ kí ìyẹn gba òun lọ́kàn, kó wá jẹ́ torí ìyẹn ló fi ń ṣiṣẹ́ kára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbájú mọ́ lílo gbogbo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ àti láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn. Ìfẹ́ yìí ló mú kó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, tó dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, tó sì rán wọn jáde láti lọ wàásù. Ó ṣe èyí kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ náà lọ, kí wọ́n sì lè ṣe iṣẹ́ tó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ.—Ka Jòhánù 14:12.
7 Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù fi bí ìtara tó ní ṣe pọ̀ tó hàn kedere. Kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, nígbà Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, nígbà tí wọ́n sì dé tẹ́ńpìlì wọ́n rí “àwọn tí ń ta màlúù àti àgùntàn àti àdàbà àti àwọn onípàṣípààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn.” Kí wá ni Jésù ṣe, ipa wo ló sì ní lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?—Ka Jòhánù 2:13-17.
8 Ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ ní àkókò yẹn mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí onísáàmù náà Dáfídì sọ, pé: “Ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run.” (Sm. 69:9) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ewu ló rọ̀ mọ́ ohun tí Jésù ṣe yẹn. Ó ṣe tán, àwọn aláṣẹ tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà, àwọn akọ̀wé àtàwọn míì ló jẹ́ babaàsàlẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe òwò tí wọ́n fi ń kó àwọn èèyàn nífà èyí tó ń wáyé níbẹ̀. Torí náà bí Jésù ṣe ń túdìí àṣírí ìwà àrékérekè wọn tó sì ń sọ èròǹgbà wọn dòfo yìí, ńṣe ló ń forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀sìn tó ti fìdí múlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe kíyè sí i gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ náà rí, ó hàn gbangba pé Jésù ní ‘ìtara fún ilé Ọlọ́run’ tàbí ìtara fún ìjọsìn tòótọ́. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìtara túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ ó yàtọ̀ sí ìjẹ́kánjúkánjú?
Bí Ìjẹ́kánjúkánjú àti Ìtara Ṣe Jọra
9 Ìwé atúmọ̀ èdè kan fi hàn pé “ìtara” túmọ̀ sí fífi “ìháragàgà àti ìfẹ́ ọkàn mímúná lépa ohun kan” àti kéèyàn ní “ìgbóná-ọkàn nípa ohun kan” bíi pé iná ń jó nínú ọkàn ẹni. Ó dájú pé a lè lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Torí náà, Bíbélì Today’s English Version túmọ̀ ẹsẹ yẹn báyìí pé: “Ìfọkànsìn mi fún ilé rẹ, Ọlọ́run, ó ń jó bí iná nínú mi.” Abájọ nígbà náà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi rántí ọ̀rọ̀ Dáfídì nígbà tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́, kí ni ohun tó mú kí iná ìtara máa jó nínú ọkàn Jésù, tí ìyẹn sì sún un láti ṣe ohun tó ṣe?
10 Ọ̀rọ̀ náà “ìtara” tó wà nínú sáàmù tí Dáfídì kọ wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù kan tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ sí “jowú” tàbí “owú” ní àwọn apá ibòmíì nínú Bíbélì. Nígbà míì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ka Ẹ́kísódù 20:5; 34:14; Jóṣúà 24:19.) Nígbà tí ìwé kan tó ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Wọ́n sábà máa ń lò ó nínú àjọṣe àárín tọkọtaya . . . Bí owú tó dára, èyí tí tọkọtaya ní síra wọn, ṣe máa ń mú kí wọ́n gbà pé àwọn jọ wà fúnra àwọn ni, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni Ọlọ́run máa ń fi hàn pé Òun nìkan lòun lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àwọn tó ń sin òun, ó sì ṣe tàn láti gbèjà ẹ̀tọ́ náà.” Torí náà, bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà ìtara kọjá kéèyàn kàn ní ìtara ọkàn fún ohun kan, bí ọ̀pọ̀ olùfẹ́ eré ìdárayá ṣe máa ń ṣe nípa eré ìdárayá tí wọ́n yàn láàyò. Ìtara tí Dáfídì ní jẹ́ owú tó dára tí kò fàyè gba ìdíje tàbí ìkẹ́gàn, tó sì máa ń súnni láti ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ rere jẹ́ tàbí láti ṣàtúnṣe ohun tó ti bà jẹ́.
11 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ohun tí wọ́n rí tí Jésù ṣe nínú tẹ́ńpìlì wé ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ, bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Kì í ṣe torí pé àkókò kan ti wà fún Jésù láti parí iṣẹ́ náà ló ṣe lo ara rẹ̀ tokuntokun, bí kò ṣe torí pé ó ní ìtara, tàbí pé ó ń jowú, nítorí orúkọ Bàbá rẹ̀ àti nítorí ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tó rí ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀, ó lo ìtara tàbí pé ó jowú lọ́nà tó tọ́, ó sì ṣe nǹkan kan láti ṣàtúnṣe ọ̀ràn náà. Nígbà tí Jésù rí i tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń ni àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lára tí wọ́n sì ń kó wọn nífà, ìtara rẹ̀ mú kó pèsè ìtura fún wọn, ó sì tún mú kó ké ègbé lé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n jẹ́ aninilára náà lórí.—Mát. 9:36; 23:2, 4, 27, 28, 33.
Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́
12 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn onísìn lóde òní jọ ti ìgbà ayé Jésù, bí kò bá tiẹ̀ burú ju ti ìgbà yẹn lọ. Bí àpẹẹrẹ, rántí pé ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run ni Jésù kọ́kọ́ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún, ó ní: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Ǹjẹ́ a rí i kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, pàápàá jù lọ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa fi orúkọ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa sọ orúkọ rẹ̀ dí mímọ́ tàbí pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún orúkọ náà? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ti lo àwọn ẹ̀kọ́ èké bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti iná ọ̀run àpáàdì láti fi sọ ohun tí kò jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí Ọlọ́run dà bí ìkà, òkú òǹrorò àti ẹni tí kò ṣeé lóye. Wọ́n tún ti kó ẹ̀gàn bá Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn ìwà máà-jẹ́-á-gbọ́ àti àgàbàgebè wọn. (Ka Róòmù 2:21-24.) Síwájú sí i, kò sí ohun tí wọn ò ṣe tán nítorí àtifi orúkọ Ọlọ́run pa mọ́, kódà wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ṣèdíwọ́ fún àwọn èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—Ják. 4:7, 8.
13 Jésù tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ó ní: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa ń tún àdúrà yẹn kà léraléra, ètò ìṣèlú àtàwọn àjọ míì táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ni wọ́n ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa kọ́wọ́ tì. Síwájú sí i, wọ́n ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn tó ń sapá láti wàásù, tí wọ́n sì ń jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run yìí. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni kì í sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run mọ́, wọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.
14 Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó sọ kedere pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Bákan náà, kí Jésù tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé òun máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn èèyàn òun. (Mát. 24:45) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń yá àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lára láti sọ pé àwọn ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ǹjẹ́ ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí Ọ̀gá náà gbé lé àwọn tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́? Rárá o. Ìtàn àròsọ ni wọ́n ka ohun tí Bíbélì sọ sí. Dípò kí àwọn àlùfáà máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ agbo wọn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìtùnú àti ìlàlóye fún wọn, ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ìyẹn ẹ̀kọ́ tó dá lórí èrò àwọn èèyàn lásán, ni wọ́n fi ń kọ́ wọn. Láfikún sí i, wọ́n ti bomi la ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà tó yẹ ká máa hù kí wọ́n lè fàyè gba ohun tí wọ́n pè ní ọ̀nà ìwà rere tuntun.—2 Tím. 4:3, 4.
15 Nítorí gbogbo ohun tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣe lórúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn ni ìjákulẹ̀ ti bá tàbí tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Bíbélì mọ́. Wọ́n sì ti kó sínú akóló Sátánì àti ètò àwọn nǹkan búburú rẹ̀. Bó o ṣe ń rí i tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ tó o sì ń gbọ́ nípa rẹ̀, báwo ló ṣe rí lára rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, tó o bá rí ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe ẹ́ bíi pé kó o wá nǹkan ṣe sí i? Tó o bá rí i tí wọ́n ń tan àwọn olóòótọ́ ọkàn jẹ tí wọ́n sì ń kó wọn nífà, ṣé kì í wù ẹ́ láti tu irú àwọn èèyàn tí à ń ni lára bẹ́ẹ̀ nínú? Nígbà tí Jésù rí àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,” àánú wọn ṣe é. Èyí ló mú kó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Mát. 9:36; Máàkù 6:34) Àwa náà ní ọ̀pọ̀ ìdí láti jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́, bí Jésù ti ṣe.
16 Bá a bá wo iṣẹ́ ìwàásù wa bí ohun tó yẹ ká máa fi ìtara ṣe, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Tímótì 2:3, 4 á túbọ̀ yé wa. (Kà á.) À ń ṣiṣẹ́ kára lóde ẹ̀rí torí a mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí, àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, a tún mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nìyẹn. Ó fẹ́ kí àwọn èèyàn ní ìmọ̀ òtítọ́, kí wọ́n bàa lè kọ́ láti jọ́sìn rẹ̀, kí wọ́n sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Kì í wulẹ̀ ṣe torí pé àkókò ń lọ la ṣe ń lo ara wa tokuntokun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bí kò ṣe nítorí pé a fẹ́ láti máa bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, ká sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́.—1 Tím. 4:16.
17 Jèhófà ti jẹ́ kí àwa èèyàn rẹ̀ ní ìmọ̀ òtítọ́ nípa ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé. A ní ohun táá jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ kí wọ́n sì ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la. A lè darí wọn sí ibi tí wọ́n ti máa rí ààbò nígbà tí ìparun bá dé sórí ètò àwọn nǹkan Sátánì. (2 Tẹs. 1:7-9) Dípò tí a ó fi jẹ́ kó sú wa tàbí tí a ó fi rẹ̀wẹ̀sì bó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà kò tètè mú ìparun wá, ńṣe ló yẹ ká máa yọ̀ pé àkókò ṣì wà fún wa láti jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́. (Míkà 7:7; Háb. 2:3) Báwo la ṣe lè ní irú ìtara bẹ́ẹ̀? Èyí ni ohun tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
*** w14 1/15 ojú ìwé 23-24 Bá A Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Kí Àwọn Ọjọ́ Oníwàhálà Tó Dé ***
ÀǸFÀÀNÍ ÀRÀ-Ọ̀TỌ̀ TÁWỌN ÀGBÀ NÍ
4 Tó bá ti pẹ́ tó o ti ń sin Jèhófà, ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ kó o bi ara rẹ. Ìbéèrè náà ni pé, ‘Ní báyìí tí mo ṣì ní agbára àti okun díẹ̀, kí ni máa fi ìyókù ayé mi ṣe?’ Pẹ̀lú ìrírí tó o ti ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, o ní àwọn àǹfààní kan táwọn míì ò ní. O lè sọ àwọn nǹkan tó o ti kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà fáwọn ọ̀dọ́. O lè fún àwọn míì lókun nípa sísọ àwọn ìrírí tó o ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run fún wọn. Dáfídì Ọba tiẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá. . . . Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.”—Sm. 71:17, 18.
5 Báwo lo ṣe lè jẹ́ káwọn míì jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó o ti ní látọdún yìí wá? Ṣé o lè ní kí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wá sílé rẹ kẹ́ ẹ lè jọ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró? Ṣé o lè ní kí wọ́n bá ẹ jáde òde ẹ̀rí kí wọ́n lè rí bó o ṣe máa ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Élíhù ìgbàanì sọ pé: “Àwọn ọjọ́ ni kí ó sọ̀rọ̀, ògìdìgbó ọdún sì ni ó yẹ kí ó sọ ọgbọ́n di mímọ̀.” (Jóòbù 32:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn àgbà obìnrin tó wà nínú ìjọ pé kí wọ́n fún àwọn míì níṣìírí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ wọn. Ó sọ pé: “Kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ . . . olùkọ́ni ní ohun rere.”—Títù 2:3.
RONÚ NÍPA OHUN TÓ O LÈ FI RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́
6 Tó o bá jẹ́ Kristẹni tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Ronú nípa àwọn nǹkan tó ti yé ẹ báyìí àmọ́ tó jẹ́ pé o kò mọ̀ ní ọgbọ̀n [30] tàbí ogójì [40] ọdún sẹ́yìn. Tó o bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó kan ìgbésí ayé rẹ̀, o ti mọ bó o ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lọ́nà jíjáfáfá. Ó dájú pé o ti mọ bó o ṣe lè mú kí òtítọ́ Bíbélì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Tó o bá jẹ́ alàgbà, o mọ bó o ṣe lè ran àwọn ará tí wọ́n bá ṣi ẹsẹ̀ gbé lọ́wọ́. (Gál. 6:1) Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o ti mọ béèyàn ṣe máa ń bójú tó àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, tàbí kó o ti sìn ní onírúuru ẹ̀ka tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àpéjọ tàbí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. O lè mọ béèyàn ṣe ń rọ àwọn dókítà láti lo onírúurú ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára lọ. Kódà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe lo ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, o ti ní ìrírí tó ṣeyebíye nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, wàá ti ní ọgbọ́n téèyàn fi ń bójú tó nǹkan. Ẹ̀yin àgbà tẹ́ ẹ wà nínú ìjọ lè jẹ́ orísun ìṣírí ńláǹlà fún àwọn èèyàn Jèhófà tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tẹ́ ẹ̀ ń múpò iwájú, tẹ́ ẹ sì ń gbé wọn ró.—Ka Jóòbù 12:12.
7 Báwo lo ṣe lè túbọ̀ lo ìrírí tó o ní láti ran àwọn míì lọ́wọ́? Bóyá o lè fi béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti béèyàn ṣe ń darí rẹ̀ han àwọn ọ̀dọ́. Tó o bá jẹ́ àgbà obìnrin, ǹjẹ́ o lè dábàá ọ̀nà tí àwọn abiyamọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́mọ fi lè máa lọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tọ́mọ lọ́wọ́? Tó o bá jẹ́ àgbà ọkùnrin, ǹjẹ́ o lè kọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin bí wọ́n ṣe lè máa fi ìtara sọ àsọyé àti bí wọ́n ṣe lè máa wàásù ìhìn rere lọ́nà tó túbọ̀ já fáfá? Ṣé o lè jẹ́ kí wọ́n mọ bó o ṣe máa ń fún àwọn àgbàlagbà níṣìírí nípa tẹ̀mí nígbà tó o bá bẹ̀ wọ́n wò? Bó ò bá tiẹ̀ lè ta kébékébé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní lo ṣì ní láti dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn, ọlá ńlá àwọn arúgbó sì ni orí ewú wọn.”—Òwe 20:29.
ṢÉ O LÈ LỌ SÌN NÍBI TÍ WỌ́N TI NÍLÒ ÀWỌN ONÍWÀÁSÙ PÚPỌ̀ SÍ I?
8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọ́run nígbà tó di àgbàlagbà. Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni, tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, ó ti ṣiṣẹ́ kára gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó sì ti fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó sì lè jókòó sílùú Róòmù tó bá fẹ́, kó máa wàásù níbẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-27) Kò sí àní-àní pé inú àwọn ará tó wà ní ìlú ńlá náà á dùn pé kó ṣì máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù rí i pé iṣẹ́ ṣì ń bẹ láti ṣe láwọn ilẹ̀ òkèèrè. Torí náà, ó mú Tímótì àti Títù, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. Ó lọ sí Éfésù, lẹ́yìn náà ó kọjá sí Kírétè, ó sì ṣeé ṣe kó dé Makedóníà. (1 Tím. 1:3; Títù 1:5) A ò mọ̀ bóyá ó dé ilẹ̀ Sípéènì, àmọ́ ó ní in lọ́kàn pé òun máa débẹ̀.—Róòmù 15:24, 28.
9 Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Pétérù náà ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún nígbà tó lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ọjọ́ orí rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti Jésù nígbà tó wà láyé tàbí pé ó ju Jésù lọ díẹ̀, a jẹ́ pé á ti tó ẹni àádọ́ta ọdún nígbà tí òun àtàwọn àpọ́sítélì yòókù jọ ṣèpàdé ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni. (Ìṣe 15:7) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe ìpàdé yẹn ni Pétérù lọ sí Bábílónì kó lè máa gbé níbẹ̀. Kí nìdí? Ó dájú pé torí kó lè wàásù fáwọn Júù tó pọ̀ rẹpẹtẹ lágbègbè náà ló ṣe lọ síbẹ̀. (Gál. 2:9) Ibẹ̀ ló wà tí Ọlọ́run fi mí sí i láti kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ní nǹkan bí ọdún 62 Sànmánì Kristẹni. (1 Pét. 5:13) Kò rọrùn láti máa gbé nílẹ̀ àjèjì, àmọ́ Pétérù ò jẹ́ kí ara tó ti ń dara àgbà mú kóun pàdánù ayọ̀ tó wà nínú fífi gbogbo ara sin Jèhófà.
10 Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín àádọ́ta [50] sí ọgọ́ta [60] ọdún àtàwọn tó ti jù bẹ́ẹ̀ lọ ti rí i pé ipò àwọn ti yí pa dà àti pé ó ṣeé ṣe fáwọn láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà láwọn ọ̀nà míì. Àwọn kan lára wọn sì ti lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Robert tó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi ti ń sún mọ́ ọgọ́ta ọdún nígbà tá a rí i pé àǹfààní ṣì wà fún wa láti ṣe púpọ̀ sí i. Ọmọ kan ṣoṣo tá a bí ti ń dá gbé, a ò ní àwọn òbí àgbà tó nílò ìtọ́jú mọ́, wọ́n sì fi ogún kékeré kan sílẹ̀ fún wa. Mo ṣírò rẹ̀ pé tá a bá ta ilé wa, àá lè san èyí tó kù lára owó tá a yá ní báńkì, àá sì lè máa gbọ́ bùkátà ara wa títí tí wọ́n á fi bẹ̀rẹ̀ sí í san owó ìfẹ̀yìntì mi. A gbọ́ pé ní orílẹ̀-èdè Bòlífíà, àwọn tó ń fẹ́ ká máa báwọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀ gan-an, nǹkan ò sì wọ́n níbẹ̀. Torí náà, a pinnu láti kó lọ síbẹ̀. Ibi tá a kó lọ yẹn ò tètè mọ́ wa lára. Níbẹ̀, àwọn nǹkan yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí níbi tá a ti wá ní Amẹ́ríkà ti Àríwá. Àmọ́, Jèhófà bù kún ìsapá wa.”
*** w15 10/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3 Ohun Tí Bíbélì Sọ ***
Ọlọ́run tí yan Jésù ọmọ rẹ̀ láti ṣàkóso gbogbo ayé. (Sáàmù 2:4-8) Jésù máa gba àwọn òtòṣì lọ́wọ́ ìnilára àti ìwà ipá.—Ka Sáàmù 72:8, 12-14.
*** w10 8/15 ojú ìwé 32 Ta Ló Lè Dá Àwọn Tó Ń kígbe Fún Ìrànlọ́wọ́ Nídè? ***
Ayé Tuntun Tí Oúnjẹ Ti Máa Pọ̀ Yanturu Ń Bọ̀
19 Tún fọkàn yàwòrán bí ọjọ́ ọ̀la àwọn olódodo ṣe máa rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù. A ṣèlérí fún wa pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sm. 72:16) Níwọ̀n bí ọkà kì í ti í ṣàdédé lalẹ̀ hù lórí àwọn òkè ńlá, ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso jáde wọ̀ǹtìwọnti. Àwọn èso rẹ̀ “yóò rí bí ti Lẹ́bánónì,” ìyẹn àgbègbè kan tó ń méso jáde lọ́pọ̀ jaburata nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ìwọ rò ó wò ná! Kò ní sí àìtó oúnjẹ mọ́, kò sẹ́ni tí kò ní máa jẹun kánú, kò sì sẹ́ni tí kò ní máa rí oúnjẹ jẹ! Nígbà yẹn gbogbo èèyàn ló máa gbádùn “àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn.”—Aísá. 25:6-8; 35:1, 2.
20 Ta lọpẹ́ yẹ nítorí àwọn ìbùkún yìí? Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Ayérayé, tó sì tún jẹ́ Olùṣàkóso Ayé Àtọ̀run ni. Nígbà yẹn gbogbo wa pátá la máa fi ayọ̀ pa ohùn wa pọ̀ láti kọ apá tó gbẹ̀yìn orin aládùn tó ń mọ́kàn yọ̀ yìí, pé: “Kí orúkọ rẹ̀ [ìyẹn orúkọ Ọba náà Jésù Kristi] máa wà nìṣó fún àkókò tí ó lọ kánrin; kí orúkọ rẹ̀ ní ìbísí níwájú oòrùn, kí wọ́n sì máa bù kún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀; kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀. Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu. Ìbùkún sì ni fún orúkọ rẹ̀ ológo fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Àmín àti Àmín.”—Sm. 72:17-19.
*** w11 8/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 17 Wọ́n Retí Mèsáyà ***
17 Àwọn èèyàn máa kórìíra Mèsáyà láìnídìí. (Sm. 69:4) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó gbọ́ lẹ́nu Jésù, ó ní: “Ká ní èmi kò ti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹlòmíràn kankan kò ṣe láàárín [àwọn èèyàn náà] ni, wọn kì bá ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan; ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti rí, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti lè mú ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’” (Jòh. 15:24, 25) Lọ́pọ̀ ìgbà “Òfin” túmọ̀ sí àpapọ̀ àwọn ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Jòh. 10:34; 12:34) Àwọn Ìwé Ìhìn rere fi hàn pé àwọn èèyàn kórìíra Jésù, pàápàá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù. Síwájú sí i, Kristi sọ pé: “Ayé kò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, ṣùgbọ́n ó kórìíra mi, nítorí mo ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.”—Jòh. 7:7.
*** w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 15 Wọ́n Rí Mèsáyà! ***
15 Wọ́n máa fún Mèsáyà ní ọtí kíkan àti òróòro mu. Onísáàmù náà sọ pé: “Wọ́n fún mi ní ọ̀gbìn onímájèlé láti fi ṣe oúnjẹ, àti fún òùngbẹ mi, wọ́n gbìyànjú láti mú mi mu ọtí kíkan.” (Sm. 69:21) Mátíù sọ fún wa pé: “Wọ́n fi wáìnì tí a pò pọ̀ mọ́ [òróòro] fún [Jésù] láti mu; ṣùgbọ́n, lẹ́yìn títọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.” Lẹ́yìn náà, “ọ̀kan lára wọ́n sáré, ó sì mú kànrìnkàn, ó sì rẹ ẹ́ sínú wáìnì kíkan, ó sì fi í sórí ọ̀pá esùsú, ó sì lọ ń fún un mu.”—Mát. 27:34, 48.
*** w13 2/15 ojú ìwé 25-26 ìpínrọ̀ 3-4 Sá Fún Àwọn Nǹkan Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dá ẹ Lọ́lá ***
3 Ohun tí onísáàmù kan sọ fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa dá òun lọ́lá. (Ka Sáàmù 73:23, 24.) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dá àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lọ́lá? Bó ṣe máa ń dá wọn lọ́lá ni pé ó máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà òun, ó sì máa ń bù kún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí òun fẹ́, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun.—1 Kọ́r. 2:7; Ják. 4:8.
4 Jèhófà tún fi iṣẹ́ ìwàásù dá wa lọ́lá. (2 Kọ́r. 4:1, 7) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń fún wa ní àǹfààní láti máa fi ògo fún Ọlọ́run. Jèhófà ṣe ìlérí kan fún àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìwàásù yìn ín tí wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Ó ní: “Àwọn tí ń bọlá fún mi ni èmi yóò bọlá fún.” (1 Sám. 2:30) Láìsí àní-àní, Jèhófà ń dá àwọn tó bá ń fògo fún un nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù lọ́lá. Wọ́n ní orúkọ rere lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ti pé wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. A sì máa ń sọ̀rọ̀ wọn ní rere nínú ìjọ.—Òwe 11:16; 22:1.
Ọ̀SẸ̀ JULY 18 SÍ 24
*** w15 8/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3-4 Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Tí Jèhófà Ní sí Wa ***
3 Àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ò fi àwọn sílẹ̀ nígbà àdánwò. Ó sì yẹ kó dá àwa náà lójú pé Ọlọ́run ò ní fi wá sílẹ̀. (Sm. 118:6, 7) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe fara hàn nínú (1) àwọn ohun tó dá, (2) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, (3) àdúrà àti (4) ìràpadà. Tá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe, a óò túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa.—Ka Sáàmù 77:11, 12.
MÁA ṢE ÀṢÀRÒ LÓRÍ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ DÁ
4 Ṣé òótọ́ ni pé tá a bá ń kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá, a máa rí i pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wa? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìdí sì ni pé ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan. (Róòmù 1:20) Ó dá ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ká lè máa wà láàyè ká sì ní ìlera tó dáa. Àmọ́, kò dá wa lásán, ó tún fẹ́ ká máa gbádùn ara wa. Ó di dandan ká jẹun ká tó lè máa wà láàyè. Torí náà, kí àwa èèyàn lè máa rí oúnjẹ tó gbámúṣe jẹ, Jèhófà rí i dájú pé onírúurú ewéko ń hù jáde. Kódà, ó tún mú kí àwọn oúnjẹ náà ládùn kí wọ́n sì gbádùn mọ́ni. (Oníw. 9:7) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Catherine kúndùn kó máa wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, pàápàá nígbà ìrúwé ilẹ̀ Kánádà tó máa ń mára tuni. Ó sọ pé: “Ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí bí gbogbo nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀: bí òdòdó ṣe máa ń yọ ọ̀mùnú, bí àwọn ẹyẹ ṣe máa ń darí wálé láti ibi tí wọ́n ṣí lọ àti bí ẹyẹ akùnyùnmù tín-ń-tín ṣe máa ń wá síbi tí mò ń kó oúnjẹ ẹyẹ sí lójú wíńdò ilé ìdáná mi. Bí Jèhófà ò bá nífẹ̀ẹ́ wa, kò ní ṣe àwọn ohun táá máa múnú wa dùn tó bẹ́ẹ̀.” Inú Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ máa ń dùn sáwọn nǹkan tó dá, ó sì fẹ́ kí àwa náà máa gbádùn wọn.—Ìṣe 14:16, 17.
*** w04 3/1 ojú ìwé 19-21 Bí a Ṣe Ń fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ***
Bí a Ṣe Ń fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
DÍDI ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn kàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ lásán. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kárí ayé ṣe mọ̀, bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un yóò máa jinlẹ̀ sí i, bá a sì ṣe ń mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtèyí tó kórìíra, tá à ń mọ àwọn ohun tó fara mọ́ àtohun tó fẹ́ ká ṣe, ni ìfẹ́ náà yóò túbọ̀ máa lágbára sí i.
Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fi fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí í ṣe Bíbélì, nínú èyí tó ti fi ẹni tí òun jẹ́ hàn. Inú rẹ̀ la ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó ọ̀ràn ní onírúurú ipò. Bíi lẹ́tà tá a gbà látọ̀dọ̀ èèyàn wa kan ṣe máa ń múnú wa dùn, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe ń fúnni láyọ̀ bá a ṣe ń rí àwọn apá tuntun tá a ṣí payá lára ànímọ́ Jèhófà.
Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe sábà máa ń kíyè sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, a rí i pé bí ẹnì kan tiẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, ìyẹn ò ní kí onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jésù sọ fáwọn Júù abaraámóorejẹ tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; . . . ṣùgbọ́n èmi mọ̀ dunjú pé ẹ kò ní ìfẹ́ fún Ọlọ́run nínú yín.” (Jòhánù 5:39, 42) Àwọn kan kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un kò tó nǹkan. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọn kì í ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó wé mọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn olóòótọ́ èèyàn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Kí lò mú kó rí bẹ́ẹ̀? Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ásáfù gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti ṣe. Lọ́nà wo?
Máa Fi Ìmọrírì Ṣàṣàrò
Ásáfù pinnu láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sínú ọkàn ara rẹ̀. Ó kọ ọ́ pé: “Èmi yóò fi ìdàníyàn hàn nínú ọkàn-àyà mi . . . èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.” (Sáàmù 77:6, 11, 12) Ìfẹ́ fún Ọlọ́run yóò máa pọ̀ sí i nínú ọkàn ẹni tó bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ọ̀nà Jèhófà gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti ṣe.
Láfikún sí i, rírántí àwọn ìrírí dídára tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà yóò mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ sì jọ máa ń ní ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Nígbà tá a bá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ó máa ń mọyì rẹ̀ èyí sì máa ń mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Nígbà náà, tá a bá wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, tó sì tọ́ wa sọ́nà láti yanjú àwọn ìṣòro kan, èyí á jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kò fi wá sílẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún un yóò sì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
Àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn méjì túbọ̀ máa ń dára sí i bí wọ́n ṣe ń finú han ara wọn. Bákan náà, nígbà tá a bá sọ ìdí tá a fi ń sin Jèhófà tọkàntọkàn fún un, ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ lágbára sí i. A ò rí i pé ohun tí Jésù sọ là ń ṣe, tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Kí ni a lè ṣe láti rí i dájú pé à ń bá a nìṣó ní fífi gbogbo ọkàn-àyà wa, gbogbo ọkàn wa, gbogbo èrò-inú wa àti gbogbo okun wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Fífi Gbogbo Ọkàn-Àyà Wa Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ tó túmọ̀ sí ohun tí ẹnì kan jẹ́ ní inú lọ́hùn ún, ìyẹn àwọn ohun tó máa ń wù ú, ìṣarasíhùwà rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Nítorí náà, fífi gbogbo ọkàn-àyà wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ọ̀ràn èyíkéyìí lọ, ó túmọ̀ sí pé à ń fẹ́ láti ṣe àwọn ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí. (Sáàmù 86:11) Nípa híhu ìwà tí inú rẹ̀ dùn sí ni ó ń fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. À ń sapá láti fara wé Ọlọ́run nípa ‘fífi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú kí a sì rọ̀ mọ́ ohun rere.’—Róòmù 12:9.
Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ń nípa lórí irú ojú tá a fi ń wo gbogbo nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, a lè fẹ́ràn iṣẹ́ tá à ń ṣe gan-an tàbí kó máa gba àfiyèsí wa gan-an, àmọ́ ṣé ibẹ̀ ni ọkàn wa máa ń wà? Rárá o. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ọkàn-àyà wa la fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí mú kí jíjẹ́ tá a jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run gba ipò iwájú. Síbẹ̀síbẹ̀, a fẹ́ mú inú àwọn òbí wa dùn, a sì fẹ́ mú inú ọkọ tàbí aya wa àti ọ̀gá wa níbi iṣẹ́ dùn àmọ́ ọ̀nà tí a ó gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn ni pé ká máa ṣe àwọn ohun tí yóò mú inú rẹ̀ dùn. Ó ṣe tán, òun ló yẹ kó gba ipò kìíní nínú ọkàn wa.—Mátíù 6:24; 10:37.
*** w03 7/1 ojú ìwé 10-11 ìpínrọ̀ 6-7 “Wò ó! Ọlọ́run Wa Nìyí” ***
6 Tó o bá dúró síta nígbà tójú ọjọ́ mọ́ rekete lọ́sàn-án, kí ló máa ń rà ọ́ lára? Ìtànṣán oòrùn ni. Ara iṣẹ́ tí agbára ìṣẹ̀dá Jèhófà ń ṣe lo rí yẹn. Báwo ni oòrùn tiẹ̀ ṣe lágbára tó? Bí a bá fi ohun tí a fi ń díwọ̀n ìgbóná nǹkan wọn àárín gbùngbùn oòrùn lọ́hùn-ún, ìwọ̀n ìgbóná rẹ̀ á dé orí ipele mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórí òṣùwọ̀n ọ̀hún. Ká sọ pé ó ṣeé ṣe fún ọ láti mú èyí tí kò ju orí abẹ́rẹ́ lọ lára ibi àárín gbùngbùn oòrùn yẹn wá sórí ilẹ̀ ayé, gbígbóná tí ìwọ̀nba bíńtín yẹn máa gbóná yóò pọ̀ débi pé o kò ní lè dúró ní nǹkan bí ogóje kìlómítà síbi tó bá wà! Agbára tó ń ti ara oòrùn jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan dà bí ìgbà tí ọ̀kẹ́ àìmọye àgbá bọ́ǹbù átọ́míìkì bá bú gbàù pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Síbẹ̀, ìwọ̀n tó tọ́ gẹ́lẹ́, láìjìnnà jù láìsúnmọ́ ọn jù, ni ayé wà tó ń yípo oòrùn, tí í ṣe àgbáàràgbá iná ìléru tó ń kẹ̀ rìrì yẹn. Bí ayé bá sún mọ́ ọn jù bẹ́ẹ̀, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; bó bá sì jìnnà jù bẹ́ẹ̀, omi inú ayé yóò di yìnyín gbagidi. Bí èyíkéyìí nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ayé ò ní ṣeé gbé fún ohun alààyè rárá.
7 Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò ka oòrùn sí rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló gbé ẹ̀mí wọn ró. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n pàdánù ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n rí kọ́ lára oòrùn. Sáàmù 74:16 sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ . . . ni ó pèsè orísun ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀, àní oòrùn.” Dájúdájú, oòrùn ń ṣe Jèhófà “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” lógo. (Sáàmù 146:6) Síbẹ̀, èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan péré lára ọ̀kẹ́ àìmọye ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tó ń kọ́ wa nípa agbára kíkàmàmà tí Jèhófà ní. Bá a bá ṣe mọ̀ sí i tó nípa agbára ìṣẹ̀dá Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe túbọ̀ hàn sí wa tó pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba gidigidi.
*** w06 7/15 ojú ìwé 11 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù ***
75:4, 5, 10—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìwo” dúró fún? Ohun ìjà tó lágbára ni ìwo orí ẹranko jẹ́. Nítorí náà, agbára tàbí okun ni ọ̀rọ̀ náà “ìwo” dúró fún. Jèhófà ń gbé ìwo àwọn èèyàn rẹ̀ ga, ìyẹn ni pé ó ń mú kí wọ́n di ẹni ìgbéga, àmọ́ ńṣe ló ń ‘ké ìwo àwọn ẹni burúkú lulẹ̀.’ Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún wa pé ká má ṣe ‘gbé ìwo wa ga sí ibi gíga lókè,’ tó túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ máa gbéra ga tàbí ká máa fẹgẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló ń gbéni ga, ńṣe ló yẹ ká máa wo àwọn ẹrù iṣẹ́ táwọn ará wa ní nínú ètò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ti wá.—Sáàmù 75:7.
*** it-1 p. 1160 Ìrẹ̀lẹ̀ ***
Gbogbo wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin gbọ́dọ̀ máa tẹríba fún àwọn tó ń múpò iwájú, ká sì tún ní sùúrù kí Jèhófà fúnra rẹ̀ yàn wá sípò tàbí fún wa ní ẹrú iṣẹ́ torí pé òun ló ń gbeni ga. (Sm 75:6, 7) Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Kórà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú èyí, wọ́n ní: “Mo ti yàn láti máa dúró ní ibi àbáwọ ilé Ọlọ́run mi Kàkà kí n máa rìn kiri nínú àwọn àgọ́ ìwà burúkú.” (Sm 84:10) Ó gba àkókò kéèyàn tó lè ní irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ yan ẹni tuntun láti ṣe alábòójútó “torí ìbẹ̀rù pé ó lè wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, kí ó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.”—1Ti 3:6.
*** w04 4/1 ojú ìwé 21-23 Ǹjẹ́ O Tẹjú Mọ́ Èrè Náà? ***
Mímọ̀ tá a mọ èrò ti Jèhófà ní nípa àwọn èèyàn rẹ̀ ń mú ká ní ìrètí, ìyẹn ànímọ́ kan tó ṣe pàtàkì bí ìgbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 13:13) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìrètí” nínú Bíbélì ní èrò fífi ìháragàgà “retí ohun kan tó dára.” Ìrètí yẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin, kí ẹ má bàa di onílọ̀ọ́ra, ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:11, 12) Ṣàkíyèsí pé bí a bá ń bá a lọ láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, a lè ní ìdánilójú pé a óò rí ohun tá à ń retí gbà. Ìrètí yìí “kì í . . . ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀,” kò dà bí ìgbà téèyàn bá ń retí àwọn nǹkan ti ayé yìí. (Róòmù 5:5) Nígbà náà, báwo la ṣe lè mú kí ìrètí wa máa wà lọ́kàn wa digbí, kó sì lágbára sí i?
Bí A Ṣe Lè Mú Kí Ojú Tẹ̀mí Wa Ríran Sí I
Ojúyòójú wa kò lè máa wo nǹkan méjì lẹ́ẹ̀kan náà. Bákan náà ni ojú tẹ̀mí wa. Tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tó wà nínú ètò àwọn nǹkan yìí ló máa ń gbà wá lọ́kàn, ó dájú pé yóò gbé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ayé tuntun kúrò lọ́kàn wa. Láìpẹ́, àwòrán ayé tuntun tó ti di bàìbàì lọ́kàn wa kò wá ní wù wá mọ́, bí yóò ṣe pòórá nìyẹn. Ẹ ò ri pé àjálù ńlá nìyẹn yóò jẹ́! (Lúùkù 21:34) Nítorí náà, ẹ ò ri pé ó ṣe pàtàkì fún wa gan-an láti jẹ́ kí ‘ojú wa mú ọ̀nà kan,’ ìyẹn ni pé ká tẹjú mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti èrè ìyè àìnípẹ̀kun!—Mátíù 6:22.
Kì í sábà rọrùn láti jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan. Àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ ń gbà àfiyèsí wa, ìpínyà ọkàn àti ìdẹwò lè wáyé pàápàá. Nínú irú àwọn ipò báwọ̀nyí, báwo la ṣe lè pọkàn pọ̀ sórí Ìjọba Ọlọ́run àti ìlérí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣe láìpa àwọn ìgbòkègbodò pàtàkì mìíràn tì? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò.
Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Kíka Bíbélì déédéé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Lóòótọ́ o, a lè ti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, bí a ṣe gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ nípa tara kí a lè máa wà láàyè nìṣó. A kò ní ṣíwọ́ oúnjẹ nítorí pé a ti jẹun láìmọye ìgbà sẹ́yìn. Nítorí náà, bó ti wù ká mọ Bíbélì tó, ó sì yẹ ká máa bá a lọ láti jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ látinú rẹ̀, ìyẹn á mú kí ìrètí wa wà lọ́kàn wa digbí, yóò sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wa túbọ̀ lágbára.—Sáàmù 1:1-3.
Máa fi ìmọrírì ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tí àṣàrò fi ṣe pàtàkì? Ohun méjì ló fà á. Àkọ́kọ́, àṣàrò yóò jẹ́ ká lè lóye ohun tí a kà, yóò sì jẹ́ ká mọrírì rẹ̀ jinlẹ̀. Ìkejì, àṣàrò kò ní jẹ́ ká gbàgbé Jèhófà, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ àti ìrètí tó gbé síwájú wa. Bí àpẹẹrẹ: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bá Mósè kúrò ní Íjíbítì fi ojú wọn kòrókòró rí bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu. Wọ́n tún rí ààbò onífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ bó ṣe ń darí wọn síbi tí ogún wọ́n wà. Síbẹ̀, kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé aginjù ní ojú ọ̀nà Ilẹ̀ Ìlérí tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí kùn, èyí tó fi hàn pé wọn ò nígbàgbọ́ rárá. (Sáàmù 78:11-17) Kí ni ìṣòro wọn gan-an?
Àwọn èèyàn náà yí àfiyèsí wọn kúrò lórí ìrètí àgbàyanu tí Jèhófà gbé síwájú wọn, wọ́n wá gbájú mọ́ ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ àtàwọn nǹkan tara. Láìka gbogbo iṣẹ́ àmì àtàwọn iṣẹ́ ìyanu táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fojú ara wọn rí sí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló di aláìnígbàgbọ́ tó ń ráhùn. Sáàmù 106:13 sọ pé: “Kíákíá ni wọ́n gbàgbé àwọn iṣẹ́ [Jèhófà].” Irú àìkaǹkansí burúkú bẹ́ẹ̀ yẹn ni kò jẹ́ kí ìran yẹn wọ Ilẹ̀ Ìlérí.
Nítorí èyí, bí o bá ń ka Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ kó o wáyè láti ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè àti ìlera rẹ nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń ka Sáàmù 106, tí a sàyọkà apá kan rẹ̀ lókè, ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà. Wo bí àánú àti sùúrù rẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pọ̀ tó. Wo bó ṣe ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Kíyè sí bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí i léraléra. Fojú inú wo bí yóò ṣe ká Jèhófà lára tó nígbà táwọn èèyàn aláìmoore tó tún jẹ́ aláìgbatẹnirò yẹn ń tẹ́ńbẹ́lú àánú rẹ̀ tí wọ́n sì tún ń tán an ní sùúrù. Síwájú sí i, nípa ríronú lórí ẹsẹ 30 àti 31 tó sọ bí Fíníhásì ṣe dúró gbọin-in, tó sì fi ìgboyà dúró ti òdodo, ìyẹn á mú kó dá wa lójú pé Jèhófà kò gbàgbé àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ àti pé ó ń san wọ́n lẹ́san lọ́pọ̀ yanturu.
Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé rẹ. Bá a ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, à ń rí i fúnra wa pé àwọn ìmọ̀ràn Jèhófà gbéṣẹ́. Òwe 3:5, 6 sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Ẹ wo bí ìgbésí ayé oníṣekúṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé ṣe fa ìdààmú, ìnira àtàwọn ìyọnu mìíràn bá wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àní títí ayé wọn ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi máa ń jìyà ìgbádùn tí wọ́n jẹ fúngbà díẹ̀. Ní òdìkejì, àwọn tó ń rìn ní ‘ojú ọ̀nà híhá’ ń rí ìtọ́wò ètò tuntun, èyí sì jẹ́ ìṣírí fún wọn láti máa rin ọ̀nà ìyè nìṣó.—Mátíù 7:13, 14; Sáàmù 34:8.
Ó lè má rọrùn láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Nígbà mìíràn, tá a bá wà nínú ipò tí kò rọgbọ, ó lè jẹ́ pé ojútùú kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu lò máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní ìṣòro ìṣúnná owó, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká fi ire Ìjọba náà sí ipò kejì. Àmọ́ ṣá o, gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí ní ìdánilójú pé ìgbẹ̀yìn “yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” (Oníwàásù 8:12) Nígbà mìíràn, Kristẹni kan lè ní láti ṣe àfikún iṣẹ́, ṣùgbọ́n kí irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ rí i pé òun ò dà bí Ísọ̀, ẹni tó fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn nǹkan tẹ̀mí, tó gbé wọn sọnù bí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan.—Jẹ́nẹ́sísì 25:34; Hébérù 12:16.
*** w11 8/15 ojú ìwé 11 Wọ́n Retí Mèsáyà ***
Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Àwọn Nǹkan Míì Tí Mèsáyà Máa Ṣe
14 Mèsáyà máa lo àwọn àkàwé tàbí àpèjúwe láti sọ̀rọ̀. Nínú orin tí onísáàmù náà, Ásáfù kọ, ó sọ pé: “Èmi yóò la ẹnu mi nínú ọ̀rọ̀ òwe.” (Sm. 78:2) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí lára? Ohun tí Mátíù sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó ti sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fi hóró músítádì àti ìwúkàrà ṣàpèjúwe Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ pé: “[Jésù] kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe; kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì náà bàa lè ṣẹ, ẹni tí ó wí pé: ‘Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi pẹ̀lú àwọn àpèjúwe, èmi yóò kéde àwọn ohun tí a fi pa mọ́ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní gbangba.’” (Mát. 13:31-35) Lára ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn lóye òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ wọn nípa Jèhófà ni pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ òwe tàbí àkàwé.
*** w12 11/1 ojú ìwé 14 Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà ***
Bí mo ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, òye tí mo ní nípa Ọlọ́run yí pa dà pátápátá. Mo wá mọ̀ pé òun kọ́ ni ó fa ìwà ibi àti ìyà tó ń jẹ aráyé àti pé ó máa ń dùn ún tí àwọn èèyàn bá ń hùwà àìdáa. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Sáàmù 78:40, 41) Mo pinnu pé màá gbìyànjú kí n má ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà. Ṣe ni mo fẹ́ máa mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Torí náà, mo jáwọ́ nínú mímu ọtí àmujù àti sìgá mímu, bákan náà mo jáwọ́ nínú ìṣekúṣe. Ní March ọdún 1994, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
*** w11 7/1 ojú ìwé 10 Báwo Ni Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Jèhófà? ***
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Báwo Ni Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Jèhófà?
BÍ A bá sọ pé, bẹ́ẹ̀ ni, ìbéèrè míì ni pé: Ǹjẹ́ ìwà wa lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́? Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí láyé ìgbàanì sọ pé rárá. Èrò wọn ni pé, kò sí ẹni tó lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí bà á nínú jẹ́, nítorí náà, wọ́n sọ pé Ọlọ́run kò lè mọ nǹkan lára. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ sí èrò yìí pátápátá, ó sọ pé, Jèhófà ní ìyọ́nú, ohun tá a sì ń ṣe jẹ ẹ́ lógún gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó wà nínú Sáàmù 78:40, 41.
Sáàmù 78 sọ nípa àjọṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì. Nígbà tí Jèhófà dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní oko ẹrú Íjíbítì, ó ní òun fẹ́ kí àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ wà láàárín òun pẹ̀lú wọn. Ó ṣèlérí pé, tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin òun, wọ́n máa di “àkànṣe dúkìá” òun, òun á sì lò wọ́n lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti mú ìfẹ́ òun ṣẹ. Àwọn èèyàn náà gbà, wọ́n sì dá májẹ̀mú Òfin pẹ̀lú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ wọ́n dúró lórí àdéhùn tí wọ́n bá Ọlọ́run ṣe?—Ẹ́kísódù 19:3-8.
Onísáàmù náà sọ pé: “Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó!” (Ẹsẹ 40) Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e fi kún un pé: “Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò.” (Ẹsẹ 41) Ẹ kíyè sí i pé, ẹni tó kọ sáàmù yìí ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run léraléra. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọ́run dá wọn sílẹ̀ ní Íjíbítì, ìyẹn ìgbà tí wọ́n wà ní aginjù ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ọ̀tẹ̀ àti ìwà àìlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Ọlọ́run, wọ́n ń sọ pé àwọn kò rò pé ó lè bójú tó àwọn, àwọn kò sì rò pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Númérì 14:1-4) Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, “ọ̀nà míì téèyàn lè gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ‘wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i’ ni pé ‘wọ́n mú ọkàn wọn le sí Ọlọ́run’ tàbí ‘wọ́n sọ pé “Rárá” fún Ọlọ́run.’” Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run àánú máa ń dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ yìí tí wọ́n bá ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà máa ń pa dà sídìí ìwà búburú wọn, wọ́n á sì tún ṣọ̀tẹ̀, bí wọ́n sì ṣe ń bá a nìṣó nìyẹn.—Sáàmù 78:10-19, 38.
Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà tí àwọn èèyàn tí kò láyọ̀ lé yìí bá ṣọ̀tẹ̀? Ẹsẹ 40 sọ pé, “Wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́.” Ohun tí ìtúmọ̀ Bíbélì míì sọ ni pé, wọ́n “mú kó ní ẹ̀dùn ọkàn.” Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, ìwà àwọn Hébérù yìí mú kó ní ìrora ọkàn, ìyẹn bí ìgbà tí ìwà ọmọ tó jẹ́ aláìgbọràn àti ọlọ̀tẹ̀ ṣe máa ń mú kí òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn.” Bí ọmọ tí kò gbọ́ràn ṣe lè mú kí àwọn òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Ẹsẹ 41.
Kí la lè rí kọ́ nínú Sáàmù yìí? Ó fi ní lọ́kàn balẹ̀ pé, Jèhófà kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ṣeré rárá, kì í sì í tètè sọ ìrètí nù pé wọn kò lè ṣàtúnṣe. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún múni ronú jinlẹ̀ pé, Jèhófà máa ń mọ nǹkan lára, ìyẹn ni pé ìwà wa lè múnú rẹ̀ dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. Ipa wo ló yẹ kí ohun tó o mọ̀ yìí ní lórí rẹ? Ǹjẹ́ èyí mú kó o fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́?
Dípò tí a ó fi máa ṣe ohun tí kò tọ́ tí a ó sì kó ìrora ọkàn bá Jèhófà, a lè pinnu láti ṣe ohun tó tọ́, ká sì mú inú rẹ̀ dùn. Ohun tí Ọlọ́run sì fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ṣe gan-an nìyẹn, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.” (Òwe 27:11) Kò sí ohun tó ṣeyebíye tá a lè fún Jèhófà ju pé ká gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀.
Ọ̀SẸ̀ JULY 25 SÍ 31
*** w08 10/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 7-8 Jèhófà Dáhùn Àdúrà Àtọkànwá Tí Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Kan Gbà ***
7 Kí ló jẹ Ásáfù lógún jù? Kò sí àní-àní pé ó ṣàníyàn gidigidi nípa ààbò òun àti ìdílé rẹ̀. Àmọ́, ohun tí àdúrà rẹ̀ dá lé ni ẹ̀gàn táwọn èèyàn mú bá orúkọ Jèhófà àti bí wọ́n ṣe ń gbógun ti àwọn èèyàn Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí ohun tó jẹ́ Ásáfù lógún yẹn jẹ àwa náà lógún bá a ṣe ń fara da àkókò lílekoko ti àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin yìí.—Ka Mátíù 6:9, 10.
8 Ásáfù sọ ohun táwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì sọ, ó ní: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a pa wọ́n rẹ́ kúrò ní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè, kí a má bàa rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.” (Sm. 83:4) Àwọn ọ̀tá wọ̀nyẹn mà kórìíra àwọn èèyàn Ọlọ́run gan-an o! Àmọ́, ìdí mìíràn tún wà tí wọ́n fi gbìmọ̀ pọ̀ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ìdí náà ni pé ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀ wọ́n lójú, wọ́n wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba àwọn ibi gbígbé Ọlọ́run fún ara wa.” (Sm. 83:12) Ǹjẹ́ ohun tó fara jọ ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó kúkú ń ṣẹlẹ̀!
*** w08 10/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 16 Jèhófà Dáhùn Àdúrà Àtọkànwá Tí Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Kan Gbà ***
16 Látìbẹ̀rẹ̀ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá a wà yìí ni Jèhófà ti ń sọ gbogbo ìsapá àwọn ọ̀tá di asán, pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń sapá tó láti pa àwọn èèyàn rẹ̀ run. (2 Tím. 3:1) Àbùkù ni èyí sì máa ń yọrí sí fáwọn ọ̀tá. Sáàmù 83:16 sọ nípa èyí, ó ní: “Fi àbùkù kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.” Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn ọ̀tá tó ń sapá láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́ ti ǹ pòfo. Láwọn orílẹ̀-èdè yẹn, dídúró táwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà dúró láìyẹsẹ̀ àti ìfaradà tí wọ́n ní ti jẹ́rìí fáwọn olóòótọ́ ọkàn, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ti ‘wá orúkọ Jèhófà.’ Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí màbo nígbà kan rí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló ń fayọ̀ yin Jèhófà níbẹ̀ báyìí. Ẹ ò rí i pé Jèhófà ti ṣẹ́gun lóòótọ́! Àbùkù gbáà lèyí sì jẹ́ fáwọn ọ̀tá rẹ̀!—Ka Jeremáyà 1:19.
*** w11 5/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1-2 Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ? ***
BÓYÁ ìgbà tí wọ́n fi orúkọ Jèhófà hàn ẹ́ nínú Sáàmù 83:18 lo kọ́kọ́ rí orúkọ yẹn. Ó tiẹ̀ lè yà ẹ́ lẹ́nu láti ka ohun tó wà níbẹ̀, pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Kò sí iyè méjì pé látìgbà tí wọ́n ti fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn hàn ẹ́, o ti lò ó láti ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́.—Róòmù 10:12, 13.
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà, irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ nìkan kò tó. Kíyè sí bí onísáàmù náà ṣe tẹnu mọ́ òtítọ́ pàtàkì mìíràn tá a gbọ́dọ̀ mọ̀ ká bàa lè rí ìgbàlà, nígbà tó sọ pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run. Torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, ó ní ẹ̀tọ́ láti retí pé kí gbogbo ohun tó dá máa tẹrí ba fún un nínú ohun gbogbo. (Ìṣí. 4:11) Èyí wá mú ká rí ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bi ara wa pé, ‘Tá lo ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé mi?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ìdáhùn wa sí ìbéèrè yẹn!
*** w08 10/15 ojú ìwé 15-16 ìpínrọ̀ 17-18 Jèhófà Dáhùn Àdúrà Àtọkànwá Tí Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Kan Gbà ***
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtakò táwọn ọ̀tá ń ṣe sí wa kò tíì parí, síbẹ̀ náà, à ń bá a nìṣó láti máa wàásù, àní fáwọn ọ̀tá pàápàá. (Mát. 24:14, 21) Àmọ́ ṣá o, àǹfààní táwọn ọ̀tá náà ní láti ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìgbàlà, kò ní pẹ́ dópin, nítorí pé sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ ṣe pàtàkì gan-an ju ìgbàlà àwọn èèyàn. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:23.) Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá kóra wọn jọ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, a óò rántí àdúrà tí Ásáfù gbà pé: “Kí ojú tì wọ́n, kí a sì yọ wọ́n lẹ́nu ní ìgbà gbogbo, kí wọ́n sì tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé.”—Sm. 83:17.
18 Ẹ̀tẹ́ ló máa gbẹ̀yìn àwọn olóríkunkun tó ń ta ko Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé “ìparun àìnípẹ̀kun” ló máa jẹ́ ti àwọn tí “kò ṣègbọràn sí ìhìn rere,” tí wọ́n sì wá tipa bẹ́ẹ̀ pa rún ní ogun Amágẹ́dọ́nì. (2 Tẹs. 1:7-9) Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà máa pa àwọn wọ̀nyí run, tó sì máa gba àwọn tó ń fòtítọ́ sìn ín là, jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé Jèhófà ni Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Nínú ayé tuntun, títí láé la ó máa rántí ìṣẹ́gun ńlá yẹn! Àwọn tó bá pa dà wá sí ìyè nígbà “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” yóò gbọ́ nípa iṣẹ́ àrà Jèhófà. (Ìṣe 24:15) Nínú ayé tuntun, wọn yóò rí ẹ̀rí tó lágbára pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ láti wà lábẹ́ Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn tó sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù nínú wọn yóò tètè gbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.
*** w06 7/15 ojú ìwé 12 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù ***
79:9. Jèhófà máa ń fetí sí àwọn àdúrà wa, pàápàá tí wọ́n bá jẹ mọ́ ìyàsímímọ́ orúkọ rẹ̀.
*** w06 7/15 ojú ìwé 12 Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù ***
86:5. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini”! Ńṣe ló máa ń wá ohun táá jẹ́ kó lè fi àánú hàn sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.