September 26 Sí October 2
SÁÀMÙ 142-150
Orin 134 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Tóbi, Ó sì Yẹ fún Ìyìn Gidigidi”: (10 min.)
Sm 145:1-9—Títóbi Jèhófà kò ní ààlà (w04 1/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3 àti 4; ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7 àti 8; ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 20 àti 21; ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 2)
Sm 145:10-13—Àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà máa ń yìn ín (w04 1/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3 sí 6)
Sm 145:14-16—Jèhófà máa ń ti àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i lẹ́yìn, ó sì máa ń bójú tó wọn (w04 1/15 ojú ìwé 17 àti 18 ìpínrọ̀ 10 sí 14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 143:8—Báwo ni Sáàmù 143:8 ṣe lè mú ká máa fi ògo fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa? (w10 1/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
Sm 150:6—Kí ni ẹsẹ tó gbẹ̀yìn nínú ìwé Sáàmù rọ̀ wá pé ká máa ṣe? (it-2 ojú ìwé 448)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 145:1-21
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Pe 5:7—Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 37:9-11—Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 9 ìpínrọ̀ 3—Ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè rí bó ṣe lè fi ohun tó kọ́ sílò.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fún Àwọn Tó Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa Níṣìírí Láti Wá sí Ìpàdé”: (15 min.) Ìjíròrò. Fún àwọn ará ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé ìkésíni tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí ìpàdé ìjọ, kẹ́ ẹ sì jíròrò ojú ìwé 2 ní ṣókí. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò bí akéde kan ṣe ń pe ẹnì kan tó máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé wá sí ìpàdé. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, ẹ jíròrò àpótí náà “Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù October: Ìwé Ìkésíni sí Àwọn Ìpàdé Ìjọ.”
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 1 ìpínrọ̀ 11 sí 20, àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé “10” àti “12”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 145 àti Àdúrà
Ìránnilétí: Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.