January 30–February 5
Aísáyà 43-46
Orin 33 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Ni Ọlọ́run Tó Ń Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Kìí Yẹ̀”: (10 min.)
Ais 44:26-28—Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́, ó sì tún sọ pé Kírúsì lẹni tó máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì (ip-2 71-72 ¶22-23)
Ais 45:1, 2—Jèhófà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì (ip-2 77-78 ¶4-6)
Ais 45:3-6—Jèhófà sọ ìdí tó fi jẹ́ pé Kírúsì ni òun lò láti ṣẹ́gun ìlú Bábílónì (ip-2 79-80 ¶8-10)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ais 43:10-12—Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà jẹ́ orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà? (w14 11/15 21-22 ¶14-16)
Ais 43:25—Kí nìdí tí Jèhófà fi ń mú àwọn ìrélànàkọjá wa kúrò? (ip-2 60 ¶24)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 46:1-13
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg—Jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà fún ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọléèwé rẹ.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jl ẹ̀kọ́ 4
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò yìí Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo lá ṣe lè lo fídíò yìí nígbà tá a bá ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, tá a bá ń wàásù níbi térò pọ̀ sí àti ilé-dé-ilé? Àwọn ìrírí tó dáa wo lo ní nígbà tó o lo fídíò yìí?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 7 ¶19-23, àpótí “JW.ORG,” àtẹ “Àwọn Ọ̀nà Kan Tí a Ti Gbà Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Èèyàn,” àti àpótí àtúnyẹ̀wò “Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 103 àti Àdúrà