ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 43-46
Jèhófà Ni Ọlọ́run Tó Ń Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Kìí Yẹ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
Ní nǹkan bí igba [200] ọdún kí ìlú Bábílónì tó pa run, Jèhófà ti gbẹnu Aísáyà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀.
Kírúsì ló máa ṣẹ́gun Bábílónì
Àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì rẹ̀ máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀
Odò Yúfírétì wà lára ohun tí wọ́n fi ń dáàbò bo ìlú náà, àmọ́ ó máa “gbẹ táútáú”