ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 51-52
Gbogbo Ọ̀rọ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ Láìkù Síbì Kan
Jèhófà sọ bí àwọn nǹkan ṣe máa rí gẹ́lẹ́ lọ́jọ́ iwájú
Èṣọ́ ààfin Páṣíà kan tó jẹ́ tafàtafà
“Ẹ dán ọfà”
Tafàtafà tó jẹ́ atamátàsé làwọn ará Mídíà àti Páṣíà, ọrun sì ni olórí ohun ìjà wọn. Wọ́n máa ń dán ọfà wọn dáadáa kó bàa lè rọrùn láti wọlé síni lára
“Àwọn alágbára ńlá Bábílónì ti ṣíwọ́ ìjà”
Ìwé ìtàn kan tó ń jẹ́ Nabonidus Chronicle sọ pé: “Wọ́ọ́rọ́wọ́ ni àwọn ọmọ ogun Kírúsì wọnú ìlú Bábílónì.” Ó ṣeé ṣe kí èyí túmọ̀ sí pé àwọn ará Bábílónì kò bá wọn fa wàhálà, èyí sì bá àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà mu
Ìwé ìtàn Nabonidus Chronicle
‘Bábílónì yóò sì di ìtòjọpelemọ òkúta, yóò di ahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin’
Láti ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ògo Bábílónì ti bẹ̀rẹ̀ sí í wọmi. Alẹkisáńdà Ńlá gbèrò láti fi ìlú Bábílónì ṣe olú ìlú rẹ̀, àmọ́ ńṣe ló kú lójijì. Nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, àwọn Júù kan ń gbé Bábílónì, ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì Pétérù máa lọ ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni, ìlú yẹn ti pa run pátápátá, ó sì ti ròkun ìgbàgbé