June 5-11
JEREMÁYÀ 51-52
Orin 37 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Gbogbo Ọ̀rọ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ Láìkù Síbì Kan”: (10 min.)
Jer 51:11, 28—Jèhófà sọ ẹni tó máa pa Bábílónì run (it-2 360 ¶2-3)
Jer 51:30—Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì ò ní lè ṣe nǹkan kan nígbà táwọn ọ̀tá bá wá pa ìlú wọn run (it-2 459 ¶4)
Jer 51:37, 62—Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bábílónì máa dahoro nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín (it-1 237 ¶1)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jer 51:25—Kí nìdí tí Bábílónì fi jẹ́ “òkè ńlá tí ń fa ìparun”? (it-2 444 ¶9)
Jer 51:42—Kí ni “òkun” tó máa ‘wá sórí Bábílónì’? (it-2 882 ¶3)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 51:1-11
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa fi ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì jw.org han onílé, lábẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà Ṣe Lágbára Tó?”: (15 min.) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nipa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn látìgbàdégbà, èyí á mú kí ìgbàgbọ́ wọn máa lágbára sí i.—Ro 1:11, 12.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 13 ¶24-32
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 49 àti Àdúrà