May 29–June 4
JEREMÁYÀ 49-50
Orin 102 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Ó sì Ń Fìyà Jẹ Àwọn Agbéraga”: (10 min.)
Jer 50:4-7—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù nígbèkùn, tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n sì rẹ ara wọn sílẹ̀ máa kúrò nígbèkùn, wọ́n á sì pa dà sí Síónì
Jer 50:29-32—Bábílónì máa pa run tórí pé ó gbéra ga sí Jèhófà (it-1 54)
Jer 50:38, 39—Bábílónì máa dahoro títí láé (jr 161 ¶15; w98 4/1 20 ¶20)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jer 49:1, 2—Kí nìdí tí Jèhófà fi gégùn-ún fún àwọn omọ Ámónì? (it-1 94 ¶6)
Jer 49:17, 18—Báwo ni ìlú Édómù ṣe dà bíi Sódómù àti Gòmórà, kí sì nìdí? (jr 163 ¶18; ip-2 351 ¶6)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 50:1-10
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) T-32—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) T-32—Ẹ jíròrò apá náà, “Rò Ó Wò Ná.” Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w15 3/15 17, 18—Àkòrí: Láwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí, Kí Nìdìí Tí A Kì í Fi Bẹ́ẹ̀ Sọ Pé Ẹnì Kan, Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Tàbí Ohun Kan Nínú Bíbélì Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Míì?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Yọ Igi Ìrólé: (15 min.) Jẹ́ káwọn ará wo fídíò Yọ Igi Ìrólé. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló fi hàn pé arákùnrin yẹn jẹ́ agbéraga àti alárìíwísí? Kí ló ràn án lọ́wọ́? Àǹfààní wo ló rí?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 13 ¶11-23
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 131 àti Àdúrà