July 10-16
Ìsíkíẹ́lì 15-17
Orin 11 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ṣé O Máa Ń Mú Ìlérí Rẹ Ṣẹ?”: (10 min.)
Isk 17:1-4—Bábílónì fi Sedekáyà rọ́pò Ọba Jèhóákínì (w07 7/1 12 ¶6)
Isk 17:7, 15—Sedekáyà dalẹ̀, ó sì wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì (w07 7/1 12 ¶6)
Isk 17:18, 19—Jèhófà fẹ́ kí Sedekáyà mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ (w12 10/15 30 ¶11; w88 9/15 17 ¶8)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Isk 16:60—Kí ni “májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” àwọn wo sì ni ọ̀rọ̀ náà kàn? (w88 9/15 17 ¶7)
Isk 17:22, 23—Ta ni “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́” tí Jèhófà sọ pé òun yóò gbìn? (w07 7/1 12 ¶6)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Isk 16:28-42
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp17.4—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp17.4—Sọ̀rọ̀ nípa fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? kí ẹ sì jíròrò rẹ̀ (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó).
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 11 ¶1-2—Pe ẹni náà wá sáwọn ìpàdé wa.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Ẹ̀jẹ́ Ìgbéyàwó Rẹ Ṣẹ Kódà Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Rí Bó O Ṣe Rò: (10 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí, a gbé e ka Jí! May 2014 ojú ìwé 12-13.
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Jẹ́ Olóòótọ́: (5 min.) Jẹ́ káwọn ará wo fídíò yìí Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Jẹ́ Olóòótọ́. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé tó o ti yàn tẹ́lẹ̀ wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n láwọn ìbéèrè tó dá lórí fídíò náà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 15 ¶1-8
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 137 àti Àdúrà