ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 July ojú ìwé 4
  • July 17-23

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 17-23
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 July ojú ìwé 4

July 17-23

Ìsíkíẹ́lì 18-20

  • Orin 21 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Tí Jèhófà Bá Ti Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jini, Ṣé Ó Máa Ń Gbàgbé Rẹ̀?”: (10 min.)

    • Isk 18:​19, 20​—Kálukú ló máa jíhìn ohun tó bá yàn láti ṣe (w12 7/1 18 ¶2)

    • Isk 18:​21, 22​—Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí wa lọ́rùn mọ́ lọ́jọ́ iwájú (w12 7/1 18 ¶3-7)

    • Isk 18:​23, 32​—Tí àwọn ẹni ibi bá kọ̀ láti ronú pìwà dà, ìgbà yẹn ni Jèhófà máa ń tó pa wọ́n run (w08 4/1 8 ¶4; w06 12/1 27 ¶11)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Isk 18:29​—Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ní èrò tí kò tọ́ nípa Jèhófà, báwo ni àwa náà kò ṣe ní ṣe irú àṣìṣe kan náà? (w13 8/15 11 ¶9)

    • Isk 20:49​—Kí nìdí tí àwọn èèyàn náà fi rò pé “ọ̀rọ̀ òwe,” ni Ìsíkíẹ́lì ń bá àwọn sọ, báwo ni ìyẹn ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa? (w07 7/1 14 ¶3)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Isk 20:​1-12

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Jo 5:19 ​—Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni. Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.

  • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 3:​2-5​—Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni. Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá. (Wo mwb16.08 8 ¶2.)

  • Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w16.05 32​—Àkòrí: Báwo Ni Àwọn Ará Nínú Ìjọ Ṣe Lè Fi Ayọ̀ Wọn Hàn Nígbà Tí Wọ́n Bá Ṣèfilọ̀ Pé A Ti Gba Ẹnì Kan Tá A Yọ Lẹ́gbẹ́ Pa Dà?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 77

  • “Ṣé O Máa Ń Dárí Ji Ara Rẹ?”: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò náà, Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Ìdájọ́ Jèhófà Lẹ́yìn​—Máa Dárí Jini.

  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé​—Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Tí Mo Bá Ṣàṣìṣe?: (5 min.) Ẹ jíròrò àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé​—Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Tí Mo Bá Ṣàṣìṣe?” èyí tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ ohùn tá a gbà sílẹ̀ náà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti “Kí Lo Máa Ṣe?”

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 15 ¶9-17

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 38 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́