October 30–November 5
JÓẸ́LÌ 1-3
Orin 143 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
‘Àwọn Ọmọkùnrin Yín àti Àwọn Ọmọbìnrin Yín Yóò Máa Sọ Tẹ́lẹ̀’: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóẹ́lì.]
Joe 2:28, 29—Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà (w02 8/1 15 ¶4-5; jd 167 ¶4)
Joe 2:30-32—Àwọn tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà nìkan ló máa rí ìgbàlà ní ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù rẹ̀ (w07 10/1 13 ¶2)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Joe 2:12, 13—Kí ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kọ́ wa nípa ojúlówó ìrònúpìwàdà? (w07 10/1 13 ¶5)
Joe 3:14—Kí ni “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu”? (w07 10/1 13 ¶3)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Joe 2:28–3:8
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Káàdì ìkànnì JW.ORG
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Káàdì ìkànnì JW.ORG—Nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù fún ẹni náà, o ti fún un ní káàdì yìí. Máa bá ìjíròrò náà lọ, kí o sì fi fídíò kan hàn án láti orí ìkànnì jw.org.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 196-197 ¶3-5
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Ń Mú Ká Lè Fara Da Àdánwò: (9 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Jèhófà Ni Odi Agbára Mi. Lẹ́yìn náà, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará pé: Àdánwò wo ló dojú kọ ìdílé Henschel? Tí àwọn òbí bá ní ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì jẹ́ oníwà títọ́, báwo ni èyí ṣe lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́? Báwo ni Jèhófà ṣe lè fún ẹ lókun bó ṣe ṣe fún Arákùnrin Henschel?
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Orúkọ Jèhófà: (6 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Orúkọ Jèhófà. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n pé: Kí ni orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí? Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà dá? Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 20 ¶17-19; àpótí “Ó Jẹ́ Kó Fi Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Ṣe Ohun Tó Dára” àti “Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Pèsè Ìrànwọ́ Jákèjádò Ayé”; àpótí tó wà fún àtúnyẹ̀wò “Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 72 àti Àdúrà