ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 February ojú ìwé 4
  • “Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bọla fun Oriṣi Eniyan Gbogbo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa Àgbàlagbà
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti ‘Bọlá fún Baba àti Ìyá Rẹ’?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bọla fun Jehofa—Eeṣe ati Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 February ojú ìwé 4

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ pàtàkì náà: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹk 20:12; Mt 15:⁠4) Jésù lẹ́nu ọ̀rọ̀ torí pé ó ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ̀ nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. (Lk 2:51) Nígbà tó sì dàgbà, ó ṣètò pé kí ẹnì kan máa tọ́jú ìyá rẹ̀ tí òun bá kú. ​—⁠Joh 19:​26, 27.

Bákan náà, lóde òní, tí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni bá ń gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu tí wọ́n sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn ń bọlá fún wọn. Àṣẹ yìí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Kódà, bí àwọn òbí wa bá tiẹ̀ ti darúgbó pàápàá, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti bọlá fún wọn ká sì máa jàǹfààní látinú ọgbọ́n wọn. (Owe 23:22) Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà bọlá fún àwọn òbí wa ni pé ká máa bójú tó ìmọ̀lára wọn àti ìnáwó wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. (1Ti 5:⁠8) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí a ti dàgbà, tá a bá ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn òbí wa, ńṣe là ń fi hàn pé a bọlá fún wọn.

WO ERÉ OJÚ PÁTÁKÓ NÁÀ BÁWO NI MO ṢE LÈ MÁA SỌ TINÚ MI FÁWỌN ÒBÍ MI? LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló lè mú kó ṣòro fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀?

  • Báwo lo ṣe lè bọlá fún àwọn òbí rẹ tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀?

    Ọmọkùnrin kan ń kọ lẹ́tà sí àwọn òbí rẹ̀, ó ń bá àwọn òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀, òun àti bàbá rẹ̀ sì jọ ń gba bọ́ọ̀lù
  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa sapá láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀? (Owe 15:⁠22)

    Àwọn òbí kan ń ran ọmọkùnrin wọn lọ́wọ́ kó lè kojú àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú

    Tó o bá ń bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀, èyí lè mú kó o túbọ̀ ṣe àṣeyọrí ní ìgbésí ayé rẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́