Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MAY 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 7-8
“Gbé Òpó Igi Oró Rẹ, Kí Ó sì Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 8:34
kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀: Tàbí “kí ó yọ̀ǹda ara rẹ pátápátá.” Èyí fi hàn pé ẹni náà múra tán láti yááfì ara rẹ̀ tàbí pé ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ pátápátá fún Ọlọ́run. A tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí sí “ó gbọ́dọ̀ sọ pé rárá fún ara rẹ̀,” èyí sì bá a mú torí ó lè gba pé kéèyàn sọ pé rárá fún àwọn ohun téèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, àfojúsùn ẹni tàbí ohun tó rọni lọ́rùn. (2Kọ 5:14, 15) Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yìí kan náà ni Máàkù lò nígbà tó ń ṣàlàyé bí Pétérù ṣe sẹ́ Jésù.—Mk 14:30, 31, 72.
Bawo ni Iwọ Ṣe Ń Sáré Ninu Eré-ìje Fun Ìyè?
14 “Bi ẹnikẹni ba fẹ́ tẹle mi,” ni Jesu Kristi sọ fun awọn ọmọ-ẹhin ati awọn miiran ti wọn korajọ, “jẹ ki o kọ araarẹ delẹ (tabi, “ó gbọdọ sọ pe, ‘Bẹẹkọ’ fun araarẹ,” itumọ Charles B. Williams) ki ó sì gbé òpó igi ìdálóró rẹ̀ ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin nigba gbogbo.” (Marku 8:34, NW) Nigba ti a ba tẹwọgba ikesini yii, a gbọdọ muratan lati ṣe bẹẹ “nigba gbogbo,” kì í ṣe nitori pe akanṣe animọ ti o yẹ fun ìyìn wà ninu ìsẹ́ra-ẹni, ṣugbọn nitori pe akoko kukuru ti ailọgbọn-ninu ẹnikan, ifasẹhin kan ninu iṣediyele rere, lè pa gbogbo ohun ti a ti gbéró run, ani ki o tilẹ fi ire alaafia ayeraye wa paapaa sinu ewu. Itẹsiwaju tẹmi ni a sábà maa ń ní ni ìwọ̀n ìṣísẹ̀ ti kò yára, ṣugbọn ẹ wo bi a ti lè sọ ọ di asán ni kiakia tó bi a ko bá wà lojufo nigba gbogbo!
Kí Lo Máa Yááfì Kó O Lè Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun?
3 Níbẹ̀ yẹn náà, Jésù bi àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbéèrè méjì kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó ní: “Àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀? Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?” (Máàkù 8:36, 37) Kò sẹ́nì kankan tí kò ní mọ ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́ yẹn. Kò sí àǹfààní kankan tí ẹni tó jèrè gbogbo ayé àmọ́ tó wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ jẹ. Ìgbà tí ẹ̀mí wa bá lè lo dúkìá ni dúkìá lè wúlò fún wa. Nígbà tí Jésù béèrè ìbéèrè kejì pé: “Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?,” ó ṣeé ṣe kó mú káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rántí ohun tí Sátánì sọ nígbà ayé Jóòbù, pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn tí kò sin Jèhófà rò pé òótọ́ lohun tí Sátánì sọ yìí. Ọ̀pọ̀ lè ṣe ohunkóhun, wọ́n lè tẹ òfin èyíkéyìí lójú, torí kí ẹ̀mí wọn má ṣáà ti bọ́. Àmọ́ ojú tí àwa Kristẹni fi ń wo nǹkan yàtọ̀ síyẹn.
4 A mọ̀ pé Jésù kò wá láti wá fún wa ní ìlera tó jí pépé, ọrọ̀ àti ẹ̀mí gígùn nínú ayé ìsinsìnyí. Àmọ́ ó wá kó lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti gbé títí láé nínú ayé tuntun, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun yẹn sì lohun tá a kà sí pàtàkì gan-an. (Jòh. 3:16) Kristẹni kan máa lóye pé ohun tí ìbéèrè àkọ́kọ́ tí Jésù béèrè túmọ̀ sí ni, “Àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tó ní?” Ìdáhùn ni pé, Kò sí àǹfààní kankan níbẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17) Ká lè dáhùn ìbéèrè kejì tí Jésù béèrè, a lè bi ara wa léèrè pé, ‘Kí ni mo lè yááfì nísinsìnyí tó máa jẹ́ kí n nírètí tó dájú pé màá wà nínú ayé tuntun?’ Ìdáhùn wa sí ìbéèrè yẹn yóò hàn nínú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa, ìyẹn sì máa fi hàn bí ìrètí yẹn ṣe fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa tó.—Fi wé Jòhánù 12:25.
jy 143 ¶4
Ta Ni Ọmọ Ènìyàn?
Kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó lè rí ojúure rẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà kí wọ́n sì múra tán láti lo ara wọn fáwọn míì. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.” (Máàkù 8:38) Ó dájú pé tí Jésù bá dé, ó máa “san èrè iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀.”—Mátíù 16:27.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló dé táwọn ọ̀tá Jésù fi ranrí mọ́ ọ̀rọ̀ fífọ ọwọ́?
▪ Èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn táwọn ọ̀tá Jésù fi kan òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Òfin Mósè sọ àwọn àṣẹ tí ẹni tó ní ìsunjáde tàbí àrùn ẹ̀tẹ̀ máa tẹ̀ lé kó lè di mímọ́, títí kan bí wọ́n á ṣe mójú tó òkú èèyàn àti òkú ẹran. Ó tún sọ ohun tí wọ́n lè ṣe kí ẹnì kan tàbí ohun kan tó ti di aláìmọ́ lè di mímọ́. Lára ohun tí wọ́n lè ṣe ni pé kí wọ́n fọ̀ ọ́, kí wọ́n rúbọ tàbí kí wọ́n wọ́n omi tàbí nǹkan míì sí i.—Léf. orí 11-15; Núm. orí 19.
Àwọn Júù tó jẹ́ rábì ń fẹ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ inú òfin yìí lójú. Ìwádìí kan sọ pé gbogbo ohun tó lè sọ èèyàn di aláìmọ́ làwọn rábì máa ń “yẹ̀ wò fínnífínní kí wọ́n lè mọ ibi tí ẹ̀gbin ti lè wá, bó ṣe máa ń ràn, ibi tó lè ràn dé, àwọn ohun èlò tó lè di aláìmọ́ àtèyí tí ò lè di aláìmọ́ àti gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún ìwẹ̀mọ́gaara.”
Àwọn alátakò Jésù bi í pé: “Èé ṣe tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í hùwà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń fi ọwọ́ ẹlẹ́gbin jẹ oúnjẹ wọn?” (Máàkù 7:5) Kì í ṣe pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń fi ọwọ́ tó dọ̀tí jẹun ni àwọn ọ̀tá yìí ń sọ. Ara ààtò ẹ̀sìn àwọn rábì ni pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ da omi sí wọn lọ́wọ́ kí wọ́n tó jẹun. Ìwádìí tá a mẹ́nu bà lókè yìí tún sọ pé: “Wọ́n tún máa ń rin kinkin lórí irú ìkòkò tó yẹ kí wọ́n fi da omi náà, irú omi tó yẹ kí wọ́n lò, ẹni tó yẹ kó dà á àti ibi tó yẹ kí wọ́n da omi náà dé lápá wọn.”
Ojú wo ni Jésù fi wo àwọn òfin táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ yìí? Èsì tó fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe kedere, ó ní: “Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípa ẹ̀yin alágàbàgebè, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi [Jèhófà]. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́.’ Ní pípa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ̀yin di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti ènìyàn mú ṣinṣin.”—Máàkù 7:6-8.
Ǹjẹ́ O Ní “Èrò Inú Kristi”?
9 Adití ni ọkùnrin yìí, agbára káká ló fi lè sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti rí i pé ara ọkùnrin yìí kò balẹ̀ láàárín èrò tó wà yìí tàbí kó ti rí i pé ojú ń tì í. Jésù wá ṣe ohun kan tó ṣàjèjì. Ó mú ọkùnrin náà kúrò láàárín èrò, ó mú un lọ sí ibi kọ́lọ́fín. Jésù wá fara ṣàpèjúwe ohun tó fẹ́ ṣe fún ọkùnrin náà. Ó “fi àwọn ìka rẹ bọ àwọn etí ọkùnrin náà àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.” (Máàkù 7:33) Lẹ́yìn èyí, Jésù gbójú sókè ọ̀run, ó sì gbàdúrà tó kún fún ìmí ẹ̀dùn. Gbogbo ìgbésẹ̀ yìí ń jẹ́ kí ọkùnrin yìí mọ̀ pé, ‘Agbára Ọlọ́run ni mo fẹ́ fi ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ọ yìí.’ Níkẹyìn, Jésù wí pé: “Là.” (Máàkù 7:34) Bí etí ọkùnrin náà ṣe là nìyẹn, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ dáadáa.
10 Jésù mà lẹ́mìí ìgbatẹnirò o! Ó lójú àánú, ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tó ní yìí ló sì sún un láti hùwà lọ́nà tí kò fi mú ọkàn wọn gbọgbẹ́. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó dára táa bá lè mú ẹ̀mí ìrònú Kristi dàgbà, ká sì máa fi irú ẹ̀mí yẹn hàn. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.” (1 Pétérù 3:8) Èyí ń béèrè pé ká sọ̀rọ̀, ká sì hùwà lọ́nà tí yóò fi hàn pé à ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò.
11 Nínú ìjọ, a lè jẹ́ ẹni tó ń gba ti àwọn ẹlòmíràn ró nípa bíbuyì fún wọn, ká máa bá wọn lò báa ṣe fẹ́ káwọn náà máa bá wa lò. (Mátíù 7:12) Ìyẹn yóò kan pé ká máa ṣọ́ àwọn ọ̀rọ̀ táa fẹ́ sọ àti ọ̀nà tí a ó gbà sọ ọ́. (Kólósè 4:6) Rántí pé, ‘ọ̀rọ̀ aláìnírònú lè dà bí ìgúnni idà.’ (Òwe 12:18) Nínú ìdílé ńkọ́? Tọkọtaya tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú kì í fi ọ̀ràn ara wọn ṣeré rárá. (Éfésù 5:33) Wọ́n máa ń yẹra fún ọ̀rọ̀ aṣa, tàbí ṣíṣe lámèyítọ́ ẹni ṣáá, tàbí sísọ òkò ọ̀rọ̀ síni—gbogbo èyí ló lè mú kí ọkàn ẹni gbọgbẹ́, tí ọgbẹ́ náà kò sì ní tètè san. Àwọn ọmọ pàápàá máa ń mọ nǹkan lára, àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ sì máa ń gba èyí rò. Tí wọ́n bá nílò ìtọ́sọ́nà, irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ yóò ṣe é lọ́nà tí yóò fi hàn pé wọ́n fi ọ̀wọ̀ tó yẹ àwọn ọmọ wọn wọ̀ wọ́n, wọn kò sì ní fẹ́ dójú ti àwọn ọmọ. (Kólósè 3:21) Nígbà táa bá gba tàwọn ẹlòmíràn rò, ńṣe là ń fi hàn pé a ní èrò inú Kristi.
Bíbélì Kíkà
MAY 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 9-10
“Ìran Tó Ń Fún Ìgbàgbọ́ Lókun”
Kristi Làwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tọ́ka Sí
9 Àwọn Júù ṣàjọ̀dún Ìrékọjá ti ọdún 32 Sànmánì Tiwa. Ní ohun tó lé ní ọdún kan ṣáájú àjọ̀dún yìí ni Jésù sọ àwọn ẹ̀rí tá a mẹ́nu bà lókè yìí láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ni Mèsáyà náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù tẹ́lẹ̀ kò tẹ̀ lé e mọ́, bóyá nítorí inúnibíni, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tàbí àníyàn ìgbésí ayé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jésù ò ṣe gbà káwọn èèyàn fi òun jọba ló mú kí ọkàn àwọn kan dàrú tàbí ló múnú bí wọn. Nígbà táwọn aṣáájú ìsìn Júù ní kí Jésù fún àwọn ní àmì láti fi hàn pé òun ní Mèsáyà, kò fún wọn ní àmì kankan látọ̀run nítorí èyí yóò mú káwọn èèyàn máa fògo fún un. (Mátíù 12:38, 39) Ìdí tí Jésù ò fi fún wọn ní àmì lè má yé àwọn kan. Síwájú sí i, Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó ṣòro lóye fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé “òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun sì jìyà ohun púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun.”—Mátíù 16:21-23.
10 Tó bá fi máa di nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá sígbà yẹn, àkókò á tó “fún [Jésù] láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 13:1) Nítorí pé ọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an, ó ṣèlérí pé òun máa fún àwọn kan lára wọn ní àmì kan látọ̀run, ìyẹn àmì tí kò fún àwọn Júù tó jẹ́ aláìṣòótọ́. Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:28) Dájúdájú, kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa wà láàyè títí dìgbà tí Ìjọba Mèsáyà yóò bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso lọ́dún 1914. Ńṣe ni Jésù fẹ́ fi ìran kan tó gbàfiyèsí han àwọn mẹ́ta kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ìran nípa ògo tó máa ní nígbà tó bá di Ọba ni. Ìran náà là ń pè ní ìran ìyípadà ológo.
Kristi Làwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tọ́ka Sí
11 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù gorí òkè ńlá kan lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Òkè Hámónì. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Jésù “yí . . . padà di ológo níwájú wọn, ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn, ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” Mósè àti Èlíjà náà fara hàn, àwọn àti Jésù sì jọ ń sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé alẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí wáyé, èyí sì mú kí ìran náà hàn kedere gan-an sí wọn. Ìran yìí dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi débi pé Pétérù sọ pé òun máa kọ́ àgọ́ mẹ́tà, ọ̀kan fún Jésù, ọ̀kan fún Mósè, ọ̀kan fún Èlíjà. Bí Pétérù ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìmọ́lẹ̀ kan tàn yòò sí wọn, wọ́n wá ń gbọ́ ohùn kan látinú sánmà tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.”—Mátíù 17:1-6.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 9:7
ohùn kan: Ìgbà kejì nínú ìgbà mẹ́ta nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere níbi tí Jèhófà ti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní tààràtà.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 1:11; Jo 12:28.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Máàkù
10:6-9. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àwọn tọkọtaya má ṣe ya ara wọn. Nítorí náà, dípò táwọn tọkọtaya yóò fi máa wá bí wọ́n á ṣe kọ ara wọn sílẹ̀, ńṣe ló yẹ kí wọ́n sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kí wọ́n bàa lè yanjú àwọn ìṣòro tó bá yọjú nínú ìgbéyàwó wọn.—Mát. 19:4-6.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 10:17, 18
Olùkọ́ Rere: Ọkùnrin yìí lo ọ̀rọ̀ náà “Olùkọ́ Rere” bí orúkọ oyè kan láti fi ṣàpọ́nlé Jésù, torí pé ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń fẹ́ káwọn èèyàn ṣe fáwọn nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò lòdì sí pé káwọn èèyàn pe òun ní “Olùkọ́” àti “Olúwa” (Jo 13:13), síbẹ̀ ó darí gbogbo ògo sí Baba rẹ̀.
Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run: Jésù fi hàn pé Jèhófà nìkan ló lè fi ìlànà lélẹ̀ nípa ohun tó jẹ́ rere, Òun nìkan ló lè pinnu ohun tó jẹ́ rere àti ohun tó jẹ́ búburú. Bí Ádámù àti Éfà ṣe hùwà ọ̀tẹ̀ nígbà tí wọ́n jẹ lára èso ìmọ̀ rere àti búburú, ńṣe ni wọ́n fẹ́ gba iṣẹ́ Jèhófà ṣe. Àmọ́ Jésù kò hùwà bíi tiwọn, ó hùwà ìrẹ̀lẹ̀ nípa jíjẹ́ kí Baba rẹ̀ nìkan pinnu ìlànà nípa ohun tó jẹ́ rere. Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ rere nípasẹ̀ àwọn ohun tó pa láṣẹ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Mk 10:19.
Bíbélì Kíkà
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 10:4, 11
ìwé ẹ̀rí ìlélọ: Tàbí “ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.” Òfin béèrè pé kí ọkùnrin tó ń ronú láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ ṣe ìwé lábẹ́ òfin, kó sì kàn sí àwọn àgbà ọkùnrin. Nípa bẹ́ẹ̀, ọkùnrin náà á lè ráyè ronú dáadáa nípa ìpinnu ńlá tó fẹ́ ṣe yẹn. Ó ṣe kedere pé ìdí tí òfin yìí fi wà ni láti má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn kàn máa kọ ara wọn sílẹ̀ láìronú jinlẹ̀, kó sì lè dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin lábẹ́ Òfin. (Di 24:1) Àmọ́ nígbà ayé Jésù, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti mú kó rọrùn gan-an láti rí ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ gbà. Josephus òpìtàn kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tó jẹ́ Farisí tó ti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ sọ pé, èèyàn lè kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ “fún ìdí èyíkéyìí (ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀).”—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:31.
kọ aya rẹ̀ sílẹ̀: Tàbí “lé ìyàwó rẹ̀ lọ.” Tá a bá fẹ́ lóye ọ̀rọ̀ Jésù tí Máàkù sọ níbí yìí dáadáa, a gbọ́dọ̀ ronú lórí ohun tó wà nínú Mt 19:9, níbi tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ Jésù yìí wà, níbẹ̀ wọ́n fi gbólóhùn kan kún un pé “bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè.” (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:32.) Ọ̀rọ̀ Jésù tí Máàkù fà yọ níbí yìí fi hàn pé ìdí kan ṣoṣo téèyàn fi lè kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀ ni tí ọ̀kan lára wọn bá ṣe “ìṣekúṣe” (por·neiʹa lédè Gíríìkì) tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìṣòótọ́.
ṣe panṣágà lòdì sí i: Jésù kò fara mọ́ èrò àwọn Rábì tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn pé ọkùnrin lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ “lórí onírúurú ìdí gbogbo.” (Mt 19:3, 9) Ó ṣàjèjì sí àwọn Júù pé ọkùnrin lè ṣe panṣágà lòdì sí ìyàwó rẹ̀. Èrò àwọn Rábì tí wọ́n fi ń kọ́ni ni pé ọkùnrin kò lè ṣe panṣágà lòdì sí ìyàwó rẹ̀, ìyẹn ni pé obìnrin nìkan ló lè jẹ́ aláìṣòótọ́. Ọ̀rọ̀ Jésù yìí fi hàn pé bó ṣe yẹ kí obìnrin máa hùwà mímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kí ọkùnrin máa hùwà mímọ́, ó sì tipa báyìí buyì kún àwọn obìnrin, ó sì gbé wọn sípò tó tọ́.
MAY 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 11-12
“Ó Fi Púpọ̀ Sí I Ju Àwọn Tó Kù Lọ”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 12:41, 42
àwọn àpótí ìṣúra: Ìwé àwọn Júù láyé ìgbàanì ṣàlàyé pé ńṣe làwọn àpótí ọrẹ yìí dà bí kàkàkí tàbí ìwo, ó sì máa ń ní ẹnu róbótó. Àwọn èèyàn máa ń fi onírúurú ọrẹ sínú rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí yìí tún fara hàn nínú Jo 8:20, nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, wọ́n pè é ní “ibi ìṣúra.” Ọ̀rọ̀ yẹn tọ́ka sí apá ibì kan nínú Àgbàlá Àwọn Obìnrin. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 27:6 àti Àfikún Ìsọfúnni 15.) Ìwé àwọn rábì kan sọ pé àpótí ìṣúra mẹ́tàlá [13] ni wọ́n gbé káàkiri ara ògiri inú àgbàlá náà. Wọ́n tún gbà gbọ́ pé ibì kan wà nínú tẹ́ńpìlì náà tí wọ́n máa ń kó àwọn owó tí wọ́n bá rí nínú àwọn àpótí ìṣúra náà sí.
ẹyọ owó kéékèèké méjì: Ó túmọ̀ sí “lẹ́pítónì méjì,” ìyẹn ohun tó kéré gan-an. Lẹ́pítónì kan jẹ́ owó ẹyọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, ó jẹ́ nǹkan bí 1/128 owó dínárì, òun ni owó bàbà tàbí owó idẹ tó kéré jù lọ tí wọ́n ń ná nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́.—Wo “Lẹ́pítónì” nínú Àfikún Ìsọfúnni 18-B.
tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an: Ó túmọ̀ sí “Kúádíránì.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ko·dranʹtes (tí wọ́n mú látinú ọ̀rọ̀ Látìn náà quadrans) ń tọ́ka sí owó bàbà tàbí owó idẹ tí wọ́n ń ná nílẹ̀ Róòmù, ó jẹ nǹkan bí 1/64 owó dínárì. Níbí yìí, Máàkù lo owó tí wọ́n ń ná nílẹ̀ Róòmù láti ṣàlàyé bí owó táwọn Júù sábà máa ń ná ṣe níye lórí tó.—Wo Àfikún Ìsọfúnni 18-A.
Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Tí O Ṣe Tọkàntọkàn
16 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ní Nísàn 11, Jésù lo àkókò gígùn nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí a ti gbé ìbéèrè dìde sí ọlá àṣẹ rẹ̀, tí ó sì ti dáhùn ìbéèrè akóni-sí-ṣòro, tí kò rò tẹ́lẹ̀, nípa owó orí, nípa àjíǹde, àti nípa àwọn ọ̀ràn mìíràn. Ó fi àwọn akọ̀wé àti Farisí bú fún ‘jíjẹ ilé àwọn opó run,’ àti fún ṣíṣe àwọn ohun mìíràn. (Máàkù 12:40) Lẹ́yìn èyí, Jésù jókòó, ó ṣe kedere pé ní Àgbàlá Àwọn Obìnrin, níbi tí àpótí ìṣúra 13 wà, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù. Ó jókòó fún àkókò díẹ̀, ó ń wo bí àwọn ènìyàn ti ń sọ ọrẹ wọn sínú wọn. Ọ̀pọ̀ ọlọ́rọ̀ wá, àwọn kan sì ti lè wá pẹ̀lú ìrísí jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni, àní pẹ̀lú ẹ̀mí ṣekárími pàápàá. (Fi wé Mátíù 6:2.) Jésù tẹjú mọ́ obìnrin kan ní pàtàkì. Ojú lásán lè ṣàìrí ohun tí ó kàmàmà nípa rẹ̀ tàbí nípa ọrẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù, tí ó lè mọ ọkàn àyà àwọn ẹlòmíràn, mọ̀ pé “òtòṣì opó” ni. Ó tún mọ iye gan-an tí ó fi tọrẹ—‘ẹyọ owó kéékèèké méjì, tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an.’—Máàkù 12:41, 42.
17 Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí ó fẹ́ kí wọ́n fojú ara wọn rí ẹ̀kọ́ tí ó fẹ́ kọ́ wọn. Jésù sọ pé obìnrin náà “sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà.” Lójú tirẹ̀, ohun tí ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo ohun tí àwọn yòó kù sọ sínú rẹ̀ lọ lápapọ̀. Ó fi “gbogbo ohun tí ó ní”—ìwọ̀nba owó tí ó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ rẹ̀—ṣètọrẹ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fi ara rẹ̀ sábẹ́ ìtọ́jú Jèhófà. Nípa báyìí, ẹni tí a fà yọ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fífún Ọlọ́run ní nǹkan ni ẹni tí ẹ̀bùn rẹ̀ kò níye lórí nípa ti ara. Ṣùgbọ́n lójú Ọlọ́run, kò ṣeé díye lé!—Máàkù 12:43, 44; Jákọ́bù 1:27.
Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Tí O Ṣe Tọkàntọkàn
17 Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí ó fẹ́ kí wọ́n fojú ara wọn rí ẹ̀kọ́ tí ó fẹ́ kọ́ wọn. Jésù sọ pé obìnrin náà “sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà.” Lójú tirẹ̀, ohun tí ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo ohun tí àwọn yòó kù sọ sínú rẹ̀ lọ lápapọ̀. Ó fi “gbogbo ohun tí ó ní”—ìwọ̀nba owó tí ó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ rẹ̀—ṣètọrẹ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fi ara rẹ̀ sábẹ́ ìtọ́jú Jèhófà. Nípa báyìí, ẹni tí a fà yọ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fífún Ọlọ́run ní nǹkan ni ẹni tí ẹ̀bùn rẹ̀ kò níye lórí nípa ti ara. Ṣùgbọ́n lójú Ọlọ́run, kò ṣeé díye lé!—Máàkù 12:43, 44; Jákọ́bù 1:27.
w87 12/1 30 ¶1
Ǹjẹ́ Fífúnni Rẹ Ha Jẹ́ Ìrúbọ Bí?
Ọpọlọpọ ẹkọ-arikọgbọn tí ó niyelori ni a le kẹkọọ rẹ̀ lati inu irohin-ọrọ yii. Ọ̀kan tí ó tayọjulọ, àfàìmọ̀, ni pé nigba tí o jẹ pé gbogbo wa ni a ní anfaani naa lati kọwọti ijọsin tootọ nipasẹ awọn ohun ìní wa nipa ti ara , ohun tí ó ṣe iyebiye nitootọ ni oju-iriran Ọlọrun kii ṣe fifunni ni ohun tí a mọ̀ pé ko pọndandan fun wa lati ni lọnakọna, ṣugbọn fifunni ní ohun ti o ṣe iyebiye fun wa. Ní awọn ọrọ miiran, njẹ a nfunni ni ohun kan tí a ko le ṣàárò rẹ̀ niti gidi? Tabi fifunni wa ha jẹ irubọ tootọ gidi bi?
Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
15 Ǹjẹ́ kò wúni lórí pé nínú gbogbo àwọn èèyàn tó wá sí tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yẹn, opó yìí nìkan ṣoṣo la mẹ́nu kàn láàárín wọn nínú Bíbélì? Jèhófà lo àpẹẹrẹ yìí láti fi kọ́ wa pé Ọlọ́run onímọrírì lòun. Ó ń fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn àtọkànwá tá a ní bó ti wù kó kéré tó lẹ́gbẹ̀ẹ́ tàwọn ẹlòmíràn. Bóyá ni ọ̀nà mìíràn tó dáa tó yìí wà tí Jèhófà tún fi lè kọ́ wa ní òtítọ́ pàtàkì yìí!
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 11:17
ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè: Àwọn mẹ́ta lára àwọn tó kọ ìwé ìhìn rere ló fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ais 56:7, àmọ́ Máàkù nìkan ló fi gbólóhùn yìí kún un, ìyẹn “fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè [àwọn èèyàn].” (Mt 21:13; Lk 19:46) Ohun tí wọ́n torí ẹ̀ kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè wá máa jọ́sìn kí wọ́n sì máa gbàdúrà sí Jèhófà níbẹ̀. (1Ọb 8:41-43) Ó tọ́ bí Jésù kò ṣe fara mọ́ ìwà àwọn Júù tó sọ tẹ́ńpìlì di ibi ìṣòwò, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà. Ìwà wọn yìí mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè láti sún mọ́ Jèhófà nínú ilé àdúrà rẹ̀, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àǹfààní láti mọ Ọlọ́run tòótọ́ dù wọ́n.
jy 244 ¶7
Ó Lo Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìgbàgbọ́
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fi wọ ìlú Jerúsálẹ́mù. Bí Jésù ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. Ó ṣeé ṣe káwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà ìlú máa ronú nípa ohun tí Jésù ṣe fáwọn tó ń pààrọ̀ owó ní ọjọ́ kan ṣáájú ìgbà yẹn, ni wọ́n bá fi ìbéèrè kan kò ó lójú pé: “Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? tàbí ta ní fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?”—Máàkù 11:28.
Bíbélì Kíkà
MAY 28–JUNE 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 13-14
“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Èèyàn Dẹkùn Mú Ẹ”
Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìdáríjì Lọ́dọ̀ Ọ̀gá Rẹ̀
14 Níkẹyìn, Pétérù yọ́ tẹ̀ lé wọn dé ẹnubodè ọ̀kan lára ilé tó tóbi jù ní Jerúsálẹ́mù. Ilé Káyáfà, àlùfáà àgbà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ àti alágbára ni. Àgbàlá sábà máa ń wà láàárín irú ilé bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń ní ẹnubodè níwájú. Nígbà tí Pétérù dé ẹnubodè náà wọn kò jẹ́ kó wọlé. Jòhánù tó ti wọlé tẹ́lẹ̀ torí pé ó jẹ́ ẹni mímọ̀ àlùfáà àgbà, sì jáde wá bá aṣọ́bodè náà pé kó jẹ́ kí Pétérù wọlé. Ó jọ pé Pétérù kò dúró ti Jòhánù, kò sì gbìyànjú láti wọnú ilé lọ kó lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀gá rẹ̀. Ṣe ló dúró sí àgbàlá níbi tí díẹ̀ lára àwọn ẹrú àtàwọn ìránṣẹ́ dúró sí, nídìí iná tó mọ́lẹ̀, tí wọ́n ń yáná nínú òtútù lóru yẹn. Ó ń wo bí àwọn tó ń jẹ́rìí èké lòdì sí Jésù ṣe ń wọlé lọ síbi ìgbẹ́jọ́ náà, tí wọ́n sì ń jáde.—Máàkù 14:54-57; Jòh. 18:15, 16, 18.
it-2 619 ¶6
Pétérù
Ọmọ ẹ̀yìn mìíràn ki Pétérù láyà, ó tẹ̀ lé e dé ilé àlùfáà àgbà, Pétérù sì wọ inú àgbàlá lọ. (Jo 18:15, 16) Kò fara pamọ́ sínú òkùnkùn níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní rí i, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló gba ibi táwọn èèyàn ti ń yáná lọ, tí òun náà sì ń báwọn yáná. Ìmọ́lẹ̀ iná náà jẹ́ káwọn èèyàn dá a mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù ni, èdè Gálílì tó sì ń hàn nínú ohùn rẹ̀ túbọ̀ wá mú kó dá wọn lójú. Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kan Pétérù, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sẹ́ pé òun ò mọ Jésù rí, ó tiẹ̀ tún búra kó lè fi dá wọn lójú pé òótọ́ lòun sọ. Àkùkọ kan wá kọ láàárín ìlú lẹ́ẹ̀kejì, Jésù sì “yí padà, ó sì bojú wo Pétérù.” Pétérù wá bọ́ síta, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkorò. (Mt 26:69-75; Mk 14:66-72; Lk 22:54-62; Jo 18:17, 18; wo COCKCROWING; OATH.) Àmọ́, Ọlọ́run dáhùn àdúrà tí Jésù ti gbà nítorí Pétérù, ìgbàgbọ́ Pétérù ò sì yẹ̀ pátápátá.—Lk 22:31, 32.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Máàkù
14:51, 52—Ta ni ọ̀dọ́kùnrin tó “sá lọ ní ìhòòhò”? Máàkù nìkan ló ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, nítorí náà a lè gbà pé òun gan-an lọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ sí.
jy 287 ¶4
Wọ́n Mú Jésù Lọ Sọ́dọ̀ Ánásì, Lẹ́yìn Náà Sọ́dọ̀ Káyáfà
Káyáfà mọ̀ pé inú máa ń bí àwọn Júù sí ẹnikẹ́ni tó bá pe ara rẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run. Nígbà kan tí Jésù sọ pé Ọlọ́run ni Bàbá òun, ńṣe làwọn Júù fẹ́ pa á, wọn ní ó ń mú “ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.” (Jòhánù 5:17, 18; 10:31-39) Níwọ̀n bí Káyáfà ti mọ èrò àwọn Júù yìí, ó wá fọgbọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Mo fi Ọlọ́run alààyè mú kí o wá sábẹ́ ìbúra láti sọ fún wa yálà ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run!” (Mátíù 26:63) Lóòótọ́, Jésù ti sọ pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. (Jòhánù 3:18; 5:25; 11:4) Tó bá wá kọ̀ tí kò sọ̀rọ̀ báyìí, ńṣe ló máa dà bíi pé ó sẹ́ pé òun kì í ṣe Ọmọ Ọlọ́run àti Kristi. Torí náà, Jésù sọ pé: “Èmi ni; ẹ ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí yóò sì máa bọ̀ nínú àwọsánmà ọ̀run.”—Máàkù 14:62.
Bíbélì Kíkà