July 2-8
Lúùkù 6-7
Orin 109 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Máa Díwọ̀n Fúnni Fàlàlà”: (10 min.)
Lk 6:37—Tá a bá ń dárí jini, àwọn èèyàn máa dárí ji àwa náà (“Ẹ máa bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀, a ó sì tú yín sílẹ̀,” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 6:37, nwtsty; w08 5/15 9-10 ¶13-14)
Lk 6:38—Ó yẹ ká jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan (“Ẹ sọ fífúnni dàṣà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 6:38, nwtsty)
Lk 6:38—Bá a bá ṣe hùwà sáwọn èèyàn ni wọ́n ṣe máa hùwà sí wa (“itan yín” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 6:38, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Lk 6:12, 13—Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwa Kristẹni tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣèpinnu lórí ohun tó ṣe pàtàkì? (w07 8/1 6 ¶1)
Lk 7:35—Báwo ni ọ̀rọ̀ Jésù yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí wọ́n bá fọ̀rọ̀ èké bà wá lórúkọ jẹ́? (“àwọn ọmọ rẹ̀” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 7:35, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 7:36-50
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 185 ¶4-5
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Jẹ́ Ọ̀làwọ́ Bíi Ti Jèhófà: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí:
Ọ̀nà wo ni Jèhófà àti Jésù gbà fi hàn pé àwọn jẹ́ ọ̀làwọ́?
Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ wa?
Kí ló túmọ̀ sí láti máa dárí jini fàlàlà?
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ ọ̀làwọ́ tó bá dọ̀rọ̀ àkókò wa?
Báwo la ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́ tó bá dọ̀rọ̀ bá a ṣe ń gbóríyìn fúnni?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 9 ¶22-26, àpótí Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ ka àpótí tàbí àfikún]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 57 àti Àdúrà