ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 6-7
Ẹ Máa Díwọ̀n Fúnni Fàlàlà
Ẹni tó bá lawọ́ máa ń lo àkókò rẹ̀, okun rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn, kó sì fún wọn ní ìṣírí.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ẹ sọ fífúnni dàṣà” gba pé kéèyàn máa ṣe nǹkan láìdáwọ́dúró
Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan, àwọn èèyàn á máa fún àwa náà. Bíbélì sọ pé “wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín.” Ọ̀rọ̀ yìí tọ́ka sí bí àwọn tó ń tajà ṣe máa ń wọn ọjà wọn kún dáadáa, tí wọ́n á sì dà á sínú ìṣẹ́po ẹ̀wù àwọ̀lékè ẹni tó wá rajà