July 23-29
Lúùkù 12-13
Orin 4 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Níye Lórí Ju Ọ̀pọ̀ Ológoṣẹ́”: (10 min.)
Lk 12:6—Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn ẹyẹ kéékèèké pàápàá (“ológoṣẹ́” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 12:6, nwtsty)
Lk 12:7—Bí Jèhófà ṣe mọ gbogbo nǹkan nípa wa fi hàn pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lọ́kàn (“irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 12:7, nwtsty
Lk 12:7—Jèhófà ka ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sí pàtàkì? (cl 241 ¶4-5)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Lk 13:24—Kí ni ìmọ̀ràn Jésù yìí túmọ̀ sí? (“Ẹ tiraka tokuntokun” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 13:24, nwtsty)
Lk 13:33—Kí nìdí tí Jésù fi sọ ọ̀rọ̀ yìí? (“kò ṣeé gbà wọlé” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 13:33, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 12:22-40
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Kó o sì pe ẹni náà wá sí ìpàdé.
Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa lò, kó o sì fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)lv 185 ¶4-5
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
A Ò Gbàgbé Wọn: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, kó o béèrè àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn ìṣòro wo ni àwọn akéde mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn kojú?
Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ò tíì gbàgbé wọn?
Báwo làwọn àkéde yẹn ṣe ń sin Jèhófà nìṣó láìka ìṣòro wọn sí, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ ìṣírí fún àwọn míì?
Báwo lo ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí àwọn àgbàlagbà àtàwọn aláìlera tó wà ní ìjọ rẹ?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 10 ¶16-24
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 5 àti Àdúrà