Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
AUGUST 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 17-18
“Máa Dúpẹ́ Oore”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 17:12, 14
àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá: Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn adẹ́tẹ̀ sábà máa ń péjọ pọ̀ tàbí kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀, èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́. (2Ki 7:3-5) Òfin Ọlọ́run sọ pé àdádó ni káwọn adẹ́tẹ̀ máa gbé. Tí adẹ́tẹ̀ bá wà níbì kan, ó gbọ́dọ̀ máa ké jáde pé “Aláìmọ́, aláìmọ́!” láti kìlọ̀ fẹ́ni tó ń bọ̀ sápá ibi tó wà. (Le 13:45, 46) Bí Òfin ṣe sọ, àwọn adẹ́tẹ̀ tí Jésù wò sàn náà jìnnà díẹ̀ sí Jésù.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 8:2 àti Glossary, “Ẹ̀tẹ̀; Adẹ́tẹ̀.”
Glossary Ẹ̀tẹ̀; Adẹ́tẹ̀
Ẹ̀tẹ̀; Adẹ́tẹ̀. Àrùn burúkú tó máa ń ba awọ ara jẹ́. Kì í ṣe ohun tá a mọ̀ sí ẹ̀tẹ̀ lónìí nìkan ni Bíbélì máa ń pè ní ẹ̀tẹ̀, torí pé kì í ṣe ara èèyàn nìkan ló máa ń wà, ó tún máa ń lẹ̀ mọ́ aṣọ àti ilé. Ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ ń ṣe ni wọ́n ń pè ní adẹ́tẹ̀.—Le 14:54; Lk 5:12.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 8:2
adẹ́tẹ̀: Ẹni tí àìsàn burúkú tó ń ba awọ ara jẹ́ ń ṣe. Kì í ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ẹ̀tẹ̀ lónìí nìkan ni Bíbélì máa ń pè ní ẹ̀tẹ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń lé ẹnikẹ́ni tó bá ní àìsàn yìí kúrò láàárín ìlú títí dìgbà tára ẹ̀ á fi yá.—Le 13:2, 45, 46; wo Glossary, “Ẹ̀tẹ̀; Adẹ́tẹ̀.”
lọ fi ara rẹ han àlùfáà: Jésù Kristi náà wà lábẹ́ Òfin nígbà tó wà láyé, torí ó mọ̀ pé iṣẹ́ àlùfáà àwọn ọmọ Léfì kò tíì dópin, ó sọ fáwọn adẹ́tẹ̀ tó wò sàn náà pé kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà. (Mt 8:4; Mk 1:44) Ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mósè, àlùfáà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ara adẹ́tẹ̀ kan ti yá lóòótọ́. Adẹ́tẹ̀ tára ẹ̀ ti yá náà á wá lọ sí tẹ́ńpìlì, á mú ààyè ẹyẹ méjì tí ó mọ́, igi kédárì àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti hísópù láti fi rúbọ.— Le 14:2-32.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore?
Ǹjẹ́ Jésù gbójú fò ó dá pé àwọn mẹ́sàn-án yòókù ò dúpẹ́ oore? Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: ‘Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni a wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà? Ṣé a kò rí kí ẹnì kankan padà láti fi ògo fún Ọlọ́run bí kò ṣe ọkùnrin yìí tí ó jẹ́ ará orílẹ̀-èdè mìíràn?’ ”—Lúùkù 17:17, 18.
Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́sàn-án yòókù kì í ṣe èèyàn burúkú o. Ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n ti fi hàn gbangba pé àwọn gba Jésù gbọ́, wọ́n sì ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ tinútinú, títí kan lílọ tí wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù láti fi ara wọn han àwọn àlùfáà. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọyì oore tí Jésù ṣe fún wọn, wọn ò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn adẹ́tẹ̀ yẹn kò ṣe ohun tí Jésù retí pé kí wọ́n ṣe. Àwa ńkọ́? Nígbà tí ẹnì kan bá ṣe wá lóore, ǹjẹ́ a tètè máa ń dúpẹ́ oore, tàbí ká kọ̀wé láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni náà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀?
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 17:10
tí kò dára fún ohunkóhun: Ní olówuuru, ó túmọ̀ sí, “kò wúlò; kò já mọ́ nǹkan.” Àpèjúwe Jésù yìí kò túmọ̀ sí pé kí àwọn ẹrú, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, máa wo ara wọn bí ẹni tí kò wúlò tàbí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé, gbólóhùn náà “tí kò dára fún ohunkóhun” túmọ̀ sí pé àwọn ẹrú yẹn kò ní máa ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ tàbí kí wọn máa retí pé káwọn èèyàn máa yìn wọ́n lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àbùmọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì túmọ̀ sí pé “ẹrú lásán ni wá, a ò nílò káwọn èèyàn kà wá sí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 18:8
ìgbàgbọ́: Tàbí “irú ìgbàgbọ́ yìí.” Tá a bá tú u ní olówuuru, ó túmọ̀ sí “ìgbàgbọ́.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó ṣáájú ọ̀rọ̀ náà “ìgbàgbọ́” jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe ohun táwọn èèyàn mọ̀ sí ìgbàgbọ́ ni Jésù ń sọ níbí, ńṣe ló ń tọ́ka sí irú ìgbàgbọ́ tí opó kan fi hàn nínú àpèjúwe tó ṣe. (Lk 18:1-8) Ó túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà rẹ̀ àti pé Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ jìyà gbé. Jésù mọ̀ọ́mọ̀ má dáhùn ìbéèrè tí wọ́n béèrè nípa ìgbàgbọ́ ni, káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè ronú nípa bí ìgbàgbọ́ tàwọn náà ṣe lágbára tó. Àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àdúrà àti ìgbàgbọ́ bá a mu gan-an torí pé ńṣe ni Jésù ń sọ irú àdánwò táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa kojú.—Lk 17:22-37.
AUGUST 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 19-20
“Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá”
jy 232 ¶2-4
Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá Tí Jésù Ṣe
Ó sọ pé: “Ọkùnrin kan tí a bí ní ilé ọlá rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ jíjìnnàréré láti gba agbára ọba síkàáwọ́ ara rẹ̀, kí ó sì padà.” (Lúùkù 19:12) Ó máa pẹ́ gan-an kó tó dé láti irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀. Ó ṣe kedere pé Jésù ni “ọkùnrin kan tí a bí ní ilé ọlá” tó rìnrìn-àjò lọ sí “ilẹ̀ jíjìnnàréré,” ìyẹn ọ̀run, níbi tí Bàbá rẹ̀ ti máa fún un ní agbára láti ṣàkóso.
Nínú àpèjúwe yẹn, kí ‘ọkùnrin tí a bí ní ilé ọlá’ yẹn tó rìnrìn-àjò, ó pe àwọn ẹrú rẹ̀ mẹ́wàá, ó sì fún wọn ní mínà mẹ́wàá, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣòwò títí èmi yóò fi dé.” (Lúùkù 19:13) Owó tó níye lórí gan-an ni mínà jẹ́. Tí àgbẹ̀ kan bá ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta, mínà kan ló máa gbà.
Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọlẹ́yìn ti mọ̀ pé àwọn ni Jésù fi wé àwọn ẹrú mẹ́wàá yẹn, torí Jésù ti kọ́kọ́ fi wọ́n wé àgbẹ̀ tó ń kóre oko. (Mátíù 9:35-38) Àmọ́ ṣá o, kò tíì ní kí wọ́n kóre oko wọn wá. Torí pé, àwọn ọmọlẹ́yìn míì máa kópa nínú iṣẹ́ ìkórè náà, ìyẹn àwọn tó máa láǹfààní láti wọ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ọmọlẹ́yìn lo ohun tí wọ́n ní láti kó ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ìjọba náà jọ.
jy 232 ¶7
Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá Tí Jésù Ṣe
Tí àwọn ọmọlẹ́yìn bá fòye mọ̀ pé àwọn ni Jésù fi wé ẹrú tó lo ohun ìní rẹ̀ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn, ọkàn wọn á balẹ̀ pé àwọn ti ṣe ohun tí Jésù fẹ́. Á sì dá wọn lójú pé ó máa san àwọn lẹ́san torí iṣẹ́ àṣekára wọn. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló máa ní irú àǹfààní kan náà tàbí tí wọ́n á ní irú ẹ̀bùn kan náà. Síbẹ̀, Jésù tó ti “gba agbára ọba” mọ ibi tágbára kálukú mọ, ó sì máa bù kún ìsapá tí wọ́n ṣe tọkàntọkàn lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 28:19, 20.
jy 233 ¶1
Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá Tí Jésù Ṣe
Ẹ̀rú yìí pàdánù, torí pé kò ṣe ohun tó máa mú kí ohun ìní ọ̀gá rẹ̀ pọ̀ sí i. Àwọn àpọ́sítélì ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, ohun tí Jésù sọ nípa ẹ̀rú yìí mú kí wọ́n mọ̀ pé táwọn ò bá ṣiṣẹ́ kára, ó ṣeé ṣe káwọn má ní àyè kankan nínú Ìjọba náà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 19:43
àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká: Tàbí “òpó.” Ibí yìí nìkan ni ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà kha ʹrax ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Wọ́n ní ó túmọ̀ sí “igi olórí ṣóńṣó tàbí òpó tí wọ́n fi ṣe odi; òpó igi,” ó tún lè túmọ̀ sí “igi olórí ṣóńṣó táwọn ọmọ ogun rì mọ́lẹ̀; òpó.” Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí ọ̀gágun Titus pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun Róòmù pé kí wọ́n mọ odi yí Jerúsálẹ́mù ká. Nǹkan mẹ́ta ni Titus ní lọ́kàn tó fi pà àṣẹ yìí, àkọ́kọ́ ni pé káwọn Júù má bàa lè sá lọ, ìkejì ni pé kí wọ́n lè juwọ́ sílẹ̀, ìdí kẹta sì ni pé kó lè febi pa wọ́n títí táá fi ṣẹ́gun wọn. Àwọn ọmọ ogun Róòmù gé gbogbo igi tó wà nígbó tán, kí wọ́n lè rí igi tí wọ́n máa fi mọ odi yí Jerúsálẹ́mù ká.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 20:38
gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀: Bíbélì fi hàn pé ẹni tí kò bá ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà láàyè, ó jẹ́ òkú lójú Ọlọ́run. (Ef 2:1; 1Ti 5:6) Lọ́nà kan náà, lójú Ọlọ́run àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú ṣì wà láàyè, torí ó dájú gbangba pé ó máa jí wọn dìde.—Ro 4:16, 17.
AUGUST 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 21-22
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”
Ìjọba Ọlọ́run Mú Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Kúrò
9 Àwọn ohun àrà mérìíyìírí lójú ọ̀run. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run.” Ó dájú pé àwọn èèyàn kò ní lọ gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn mọ́, torí wọn kò ní ka àwọn aṣáájú ìsìn sí ìmọ́lẹ̀ mọ́. Ṣé ohun tí Jésù sì tún ń sọ ni pé àwọn nǹkan àràmàǹdà á máa ṣẹlẹ̀ látojú ọ̀run? Bóyá ohun tó ń sọ náà nìyẹn. (Aísá. 13:9-11; Jóẹ́lì 2:1, 30, 31) Kí làwọn èèyàn máa ṣe nípa ohun tí wọ́n rí? Ńṣe ni wọn yóò wà nínú “làásìgbò” torí pé wọn kò mọ “ọ̀nà àbájáde.” (Lúùkù 21:25; Sef. 1:17) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run, látorí àwọn ọba wọn tó fi dórí àwọn ẹrú wọn ni yóò “kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá,” wọ́n á sì sáré láti wá ibi fara pa mọ́ sí. Síbẹ̀, wọn ò ní ríbi ààbò kankan fi ara wọn pa mọ́ sí tí wọ́n á fi lè bọ́ lọ́wọ́ ìrunú Ọba wa.—Lúùkù 21:26; 23:30; Ìṣí. 6:15-17.
“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Ará Tí Ẹ Ní Máa Bá A Lọ”!
17 “Jẹ́ onígboyà.” (Ka Hébérù 13:6.) Ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà ń fún wa nígboyà láti fara da àwọn àdánwò tó le koko. Ìgboyà yìí ló sì máa jẹ́ ká ní ẹ̀mí pé nǹkan á dáa. Tá a bá sì ti wá mọ̀ pé nǹkan á dáa, àá máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará, àá máa fún wọn níṣìírí, àá sì máa tù wọ́n nínú. (1 Tẹsalóníkà 5:14, 15) Kódà, nígbà ìpọ́njú ńlá pàápàá, a lè nígboyà torí a mọ̀ pé ìdáǹdè wa kù sí dẹ̀dẹ̀.—Lúùkù 21:25-28.
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!
13 Kí ni àwọn ewúrẹ́ máa ṣe tí wọ́n bá rí i pé “ìkékúrò àìnípẹ̀kun” ló ń dúró de àwọn? Wọ́n máa “lu ara wọn nínú ìdárò.” (Mát. 24:30) Ṣùgbọ́n kí ni àwọn arákùnrin Kristi àti àwọn olóòótọ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn máa ṣe nígbà yẹn? Torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, wọ́n á ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa fún wọn pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) A ò ní mikàn, torí ó dá wa lójú pé a máa là á já.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 21:33
Ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ: Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì sọ pé ọ̀run àti ayé máa wà títí láé. (Jẹ 9:16; Sm 104:5; Onw 1:4) Torí náà, ó ní láti jẹ́ pé àbùmọ́ ọ̀rọ̀ ni Jésù lò níbí, ìyẹn ni pé ká tiẹ̀ wá sọ pé ọ̀run àti ayé kọjá lọ, èyí tí kò lè ṣẹlẹ̀ láéláé, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ̀ máa ṣẹ dandan ni. (Fi wé Mt 5:18.) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀run àti ayé ìṣàpẹẹrẹ ni Jésù ń sọ níbí, èyí tí Bíbélì pè ní “ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú” ní Iṣi 21:1.
àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà: Bí Jésù ṣe sọ pé “kì yóò kọjá lọ” mú kó dájú gbangba pé ohun tí Jésù sọ máa ṣẹ láìkùnà.
Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
15 Lẹ́yìn tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwá sílẹ̀, ó dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́, májẹ̀mú náà la sábà máa ń pè ní májẹ̀mú Ìjọba. (Ka Lúùkù 22:28-30.) Májẹ̀mú yìí yàtọ̀ sáwọn yòókù, torí pé Jèhófà wà lára àwọn tí májẹ̀mú yòókù kàn. Àmọ́, májẹ̀mú Ìjọba wà láàárín Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Nígbà tí Jésù sọ pé, “gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan,” ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí májẹ̀mú tí Jèhófà dá pẹ̀lú rẹ̀ pé ó máa jẹ́ “àlùfáà títí láé ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.”—Héb. 5:5, 6.
16 Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ‘ti dúró ti Jésù gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò rẹ̀.’ Májẹ̀mú Ìjọba mú kó dá wọn lójú pé wọ́n máa wà pẹ̀lú Jésù lókè ọ̀run, wọ́n á sì jókòó lórí ìtẹ́ kí wọ́n lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba àti àlùfáà. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn mọ́kànlá náà nìkan ló máa ní àǹfààní yẹn. Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo bá àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nínú ìran, ó sì sọ fún un pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.” (Ìṣí. 3:21) Torí náà, gbogbo àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ni Jésù bá dá májẹ̀mú Ìjọba náà. (Ìṣí. 5:9, 10; 7:4) Májẹ̀mú yìí ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. Ńṣe ló dà bí obìnrin kan tí ọba fi ṣe aya, gbàrà tí wọ́n bá ṣègbéyàwó ni obìnrin náà ti láǹfààní láti máa ṣàkóso pẹ̀lú ọba. Kódà, Ìwé Mímọ́ pe àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ni “ìyàwó” Kristi, ó ní wọ́n jẹ́ “wúńdíá oníwàmímọ́” tí ó ń fojú sọ́nà láti fẹ́ Kristi.—Ìṣí. 19:7, 8; 21:9; 2 Kọ́r. 11:2.
AUGUST 27–SEPTEMBER 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 23-24
“Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
“Láti Mọ Ìfẹ́ Kristi”
16 Ọ̀nà pàtàkì mìíràn tún wà tí Jésù ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Bàbá rẹ̀ ní lọ́nà pípé, ìyẹn ni pé òun náà “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Pé ó ṣe tán láti dárí jini ṣe kedere nígbà tó wà lórí igi oró pàápàá. Nígbà tó wà lójú ikú, ìyẹn ikú ẹ̀sín tí wọ́n fi pa á, tí wọ́n ń kan ìṣó mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, ọ̀rọ̀ wo ló tẹnu Jésù jáde? Ṣé ó ké pe Jèhófà kí ó gbẹ̀san lára àwọn tó pa òun ni? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ara ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ gbẹ̀yìn ni pé: “Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Lúùkù 23:34.
Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Jáì Jini?
Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan bá dá nìkan ni Jèhófà máa ń kíyè sí, ó tún máa ń kíyè sí ìṣarasíhùwà ẹni tó dẹ́ṣẹ̀. (Aísáyà 1:16-19) Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn aṣebi méjì tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì Jésù. Ó dájú pé àwọn méjèèjì ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, torí ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ohun tí ó tọ́ sí wa ni àwa ń gbà ní kíkún nítorí àwọn ohun tí a ṣe; ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí [Jésù] kò ṣe ohun kan tí kò tọ̀nà.” Ọ̀rọ̀ tí aṣebi yẹn sọ fi hàn pé ó mọ ohun kan nípa Jésù. Ó sì ṣeé ṣe kí ohun tó mọ̀ yẹn wà lára ohun tó ràn án lọ́wọ́ tí ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ nípa Jésù fi yàtọ̀. Ìyẹn sì fara hàn nínú ẹ̀bẹ̀ tó bẹ Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Kí ni Kristi sọ sí ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá tí aṣebi náà bẹ̀ ẹ́? Ó dáhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:41-43.
Ẹ ò rí i pé ohun tó kọyọyọ gbáà ni pé lára ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ gbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn ni pé òun á fi àánú hàn sí ọkùnrin kan tó gbà pé ikú tọ́ sí òun. Ìṣírí ńlá gbáà mà nìyẹn jẹ́ o! Ó yẹ kó dá wa lójú nígbà náà pé Jésù Kristi àti Baba rẹ̀, Jèhófà, máa fi àánú hàn sí gbogbo àwọn tó bá ronú pìwà dà látọkàn wá láìka ohun yòówù tí wọn ì báà ti ṣe nígbà kan rí sí.—Róòmù 4:7.
“Láti Mọ Ìfẹ́ Kristi”
17 Bóyá àpẹẹrẹ mìíràn tó tilẹ̀ tún wọni lọ́kàn ju àwọn tá a ti mẹ́nu kàn lọ, nípa bí Jésù ṣe ń dárí jini, ni ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù. Kò sí àní-àní pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ Jésù dénúdénú. Ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ìyẹn òru ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé Jésù láyé, Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n àti sínú ikú.” Ṣùgbọ́n ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sẹ́ Jésù, tó lóun ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rí! Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa nígbà tí Pétérù sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀kẹta, pé: “Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù.” Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí Pétérù ṣẹ̀ yìí dùn ún gan-an, nítorí náà ó “bọ́ sóde, ó sì sunkún kíkorò.” Nígbà tí Jésù kú lẹ́yìn náà lọ́jọ́ yẹn, ó ṣeé ṣe kí ominú máa kọ àpọ́sítélì náà pé, ‘Ǹjẹ́ Olúwa mi dárí jì mí báyìí?’—Lúùkù 22:33, 61, 62.
18 Kò pẹ́ tí Pétérù fi rí ìdáhùn. Àárọ̀ ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Nísàn ni a jí Jésù dìde, ó sì jọ pé ọjọ́ yẹn gan-an ló yọ sí Pétérù. (Lúùkù 24:34; 1 Kọ́ríńtì 15:4-8) Kí nìdí tí Jésù fi fún àpọ́sítélì tó sẹ́ Ẹ kanlẹ̀ yìí ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀? Bóyá ṣe ni Jésù fẹ́ kí Pétérù tó ti ronú pìwà dà mọ̀ dájú pé Olúwa òun ṣì nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ó ṣì ka òun séèyàn àtàtà. Àmọ́ Jésù kò fi mọ sórí fífi Pétérù lọ́kàn balẹ̀ nìkan.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 23:31
nígbà tí igi wà ní tútù, . . . nígbà tí ó bá rọ: Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Júù ni Jésù ń tọ́ka sí. Ńṣe ni wọ́n dà bí igi tó ti ń kú lọ àmọ́ tó ṣì lómi díẹ̀ lára, ìdí ni pé Jésù àtàwọn Júù míì tó gbà á gbọ́ ṣì wà pẹ̀lú wọn. Àmọ́ ṣá o, wọ́n máa tó pa Jésù, Ọlọ́run sì máa fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Júù tó jẹ́ olóòótọ́, wọ́n á sì di ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Ro 2:28, 29; Ga 6:16) Ìgbà yẹn ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa di òkú nípa tẹ̀mí, wọ́n á dà bí igi tó ti gbẹ.—Mt 21:43.
nwtsty àwòrán àti fídíò
Ìṣó nínú Egungun Gìgísẹ̀
Àwòrán ohun tó jọ egungun gìgísẹ̀ èèyàn rèé, wọ́n sì fi ìṣó irin tí ó gùn tó sẹ̀ńtímítà mọ́kànlá ààbọ̀ [11.5 cm] gún un ní àgúnyọ. Ọdún 1968 ni wọ́n rí egungun yìí, nígbà tí wọ́n ń walẹ̀ ní apá àríwá Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣeé ṣe kó ti wà níbẹ̀ látìgbà ayé àwọn ará Róòmù. Ó jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé wọ́n máa ń lo ìṣó nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kan àwọn èèyàn mọ́gi. Ó ṣeé ṣe kí ìṣó yìí jọ irú èyí tí àwọn ọmọ ogun Róòmù fi kan Jésù Kristi mọ́gi. Inú òkúta kan tí wọ́n gbẹ́ bí àpótí ni wọ́n ti rí egungun yìí. Inú irú àwọn òkúta bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń kó egungun àwọn tó bá ti kú sí, lẹ́yìn tí ẹran ara wọn bá ti jẹrà. Èyí sì fi hàn pé wọ́n lè sìnkú ẹni tí wọ́n bá kàn mọ́gi.