November 12-18
Ìṣe 1-3
Orin 104 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ọlọ́run Tú Ẹ̀mí Mímọ́ Sórí Ìjọ Kristẹni”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣe.]
Iṣe 2:1-8, 14, 37, 38, 41—Lẹ́yìn tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n wàásù fún àwọn èèyàn, àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló sì ṣèrìbọmi
Iṣe 2:42-47—Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi hàn pé àwọn lawọ́, wọ́n sì lẹ́mìí aájò àlejò bí wọ́n ṣe jẹ́ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọlẹ́yìn dúró ní Jerúsálẹ́mù fún àwọn àkókò díẹ̀ sí i kí ìgbàgbọ́ wọn lè túbọ̀ lágbára (w86 12/1 22 ¶4-5, 7)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Iṣe 3:15—Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ “Olórí Aṣojú ìyè”? (it-2 61 ¶1)
Iṣe 3:19—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà? (cl 265 ¶14)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Iṣe 2:1-21
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)it-1 129 ¶2-3—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Fi Ẹlòmíì Rọ́pò Júdásì Àmọ́ Tí Wọn Ò Ṣe Bẹ́ẹ̀ fún Àwọn Àpọ́sítélì Tó Jẹ́ Olóòótọ́ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Kú?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ẹ Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Wàásù Láwọn Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè”: (15 min.) Ìjíròrò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó apá yìí. Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Sọ àwọn ètò tó wà nílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ onírúurú èdè.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 15 ¶18-23 àti àpótí “Ìpinnu Tí Mo Ṣe Fún Mi Láyọ̀ Mo Sì Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn” [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ ka àpótí tàbí àfikún àlàyé]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 68 àti Àdúrà