May 13-19
2 KỌ́RÍŃTÌ 7-10
Orin 109 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe”: (10 min.)
2Kọ 8:1-3—Àwọn ará tó wà ní Makedóníà ṣe “kọjá agbára wọn,” láti ran àwọn ará tó wà ní Jùdíà lọ́wọ́ (w98 11/1 25 ¶1; kr 209 ¶1)
2Kọ 8:4—Tá a bá ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wa tó nílò ìrànlọ́wọ́, ara “iṣẹ́ òjíṣẹ́” wa là ń ṣe (kr 209-210 ¶4-6)
2Kọ 9:7—“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú” (kr 196 ¶10)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
2Kọ 9:15—Kí ni “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́” Ọlọ́run “tí kò ṣeé ṣàpèjúwe”? (w16.01 9 ¶2)
2Kọ 10:17—Kí ló túmọ̀ sí láti “máa fi Jèhófà yangàn”? (g99 7/8 18-19)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 2Kọ 7:1-12 (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 4)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bí Àwọn Ará Wa Ní Caribbean Ṣe Jàǹfààní Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Ìfẹ́ Sún Wọn Ṣiṣẹ́—Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù Tó Wáyé Láwọn Erékùṣù Caribbean.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 6 ¶1-6
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 94 àti Àdúrà