July 1-7
KÓLÓSÈ 1-4
Orin 56 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Bọ́ Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Kí Ẹ sì Fi Ìwà Tuntun Wọ Ara Yín Láṣọ”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kólósè.]
Kol 3:5-9—“Ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀” (w11 3/15 10 ¶12-13)
Kol 3:10-14—‘Ẹ fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ’ (w13 9/15 21 ¶18-19)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Kol 1:13, 14—Kí ni “ìjọba Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n”? (it-2 169 ¶3-5)
Kol 2:8—Kí ni “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé”? (w08 8/15 28 ¶8)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kol 1:1-20 (th ẹ̀kọ́ 2)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni: (10 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà, lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ 7 nínú ìwé pẹlẹbẹ Kíkọ́ni.
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w04 5/1 19-20 ¶3-7—Àkòrí: Báwo Ni Àwọn Ará Ṣe Jẹ́ “Àrànṣe Afúnnilókun” fún Pọ́ọ̀lù? (Kol 4:11, àlàyé ìsàlẹ̀) (th ẹ̀kọ́ 7)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìròyìn Látọwọ́ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́—2018: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni ìrìn àjò ṣe di apá pàtàkì lára àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run? Kí ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìrìn Àjò ní Oríléeṣẹ́ máa ń ṣe láti ṣọ́wó ná? Kí ni àwọn ará lè ṣe láti dín owó tí ètò Ọlọ́run ń ná kù? Ìrànlọ́wọ́ wo ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìrìn Àjò ní Oríléeṣẹ́ ń ṣe fún àwọn tó máa rìnrìn àjò lọ fún àpéjọ àgbáyé tọdún 2019?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 7 ¶21-25 àti àfikún Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 102 àti Àdúrà