July 22-28
1 TÍMÓTÌ 1-3
Orin 103 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Iṣẹ́ Rere Ni Kó O Máa Lé”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tímótì Kìíní.]
1Ti 3:1—Bíbélì gba àwọn arákùnrin níyànjú pé kí wọ́n sapá láti di alábòójútó (w16.08 21 ¶3)
1Ti 3:13—Àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tó dáa máa gba ọ̀pọ̀ ìbùkún (km 12/79 3 ¶7)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
1Ti 1:4—Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ fún Tímótì pé kó má tẹ́tí sí àwọn ìtàn ìdílé? (it-1 914-915)
1Ti 1:17—Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan la lè pè ní “Ọba ayérayé”? (cl 12 ¶15)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Ti 2:1-15 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 38-39 ¶6-7 (th ẹ̀kọ́ 6)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ṣiṣẹ́ ní Warwick Bọlá fún Jèhófà: (6 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà (lára àwọn fídíò tó wà ní abala IṢẸ́ WA). Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ṣe ṣèrànwọ́ nígbà tá à ń kọ́ Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Warwick, àǹfààní wo ni wọ́n sì rí níbẹ̀?
Àwọn àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin tó wà nínú ìjọ ní láti fi bọlá fún Jèhófà?
“Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́ Lára Wọn?”: (9 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Bọ̀wọ̀ Fún Àwọn Ọkùnrin Onírìírí.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 8 ¶16-22
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 115 àti Àdúrà