September 2-8
HÉBÉRÙ 7-8
Orin 16 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àlùfáà Títí Láé Ní Ọ̀nà Ti Melikisédékì”: (10 min.)
Heb 7:1, 2—Melikisédékì tó jẹ́ ọba àti àlùfáà pàdé Ábúráhámù, ó sì súre fún un (it-2 366)
Heb 7:3—Melikisédékì “kò ní ìran” àti pé “ó jẹ́ àlùfáà títí láé” (it-2 367 ¶4)
Heb 7:17—Jésù jẹ́ “àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì” (it-2 366)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Heb 8:3—Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọrẹ, ìyẹn ẹ̀bùn táwọn èèyàn ń mú wá àti ẹbọ tí wọ́n máa ń fi rúbọ lábẹ́ òfin Mósè? (w00 8/15 14 ¶11)
Heb 8:13—Nígbà ayé Jeremáyà, báwo ni májẹ̀mú Òfin ṣe di èyí “tí kò wúlò mọ́”? (it-1 523 ¶5)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Heb 7:1-17 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni: (10 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára, lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ 9 nínú ìwé pẹlẹbẹ Kíkọ́ni.
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) it-1 524 ¶3-5—Àkòrí: Kí ni májẹ̀mú tuntun? (th ẹ̀kọ́ 7)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù September. Gba àwọn ará níyànjú láti lọ wo oríléeṣẹ́ wa tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó bá ṣeé ṣe.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 10 ¶1-4
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 83 àti Àdúrà