September 9-15
HÉBÉRÙ 9-10
Orin 10 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Òjìji Àwọn Nǹkan Rere Tó Ń Bọ̀”: (10 min.)
Heb 9:12-14—Ẹ̀jẹ̀ Kristi ṣeyebíye ju ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti tàwọn akọ màlúù lọ (it-1 862 ¶1)
Heb 9:24-26—Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Kristi gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ lọ fún Ọlọ́run, kò sì ní tún un ṣe mọ́ láé (cf 183 ¶4)
Heb 10:1-4—Òfin yẹn ṣàpẹẹrẹ nǹkan ńlá tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú (it-2 602-603)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Heb 9:16, 17—Kí ni ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí? (w92 3/1 31 ¶4-6)
Heb 10:5-7—Ìgbà wo ni Jésù sọ̀rọ̀ yìí, kí ló sì ní lọ́kàn? (it-1 249-250)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Heb 9:1-14 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà, fún un ní káàdì ìkànnì JW.ORG. (th ẹ̀kọ́ 11)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Mọyì Àwọn Ìpàdé Wa? (Sm 27:11): (12 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo ni Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà wa ṣe, tó ṣe wá láǹfààní?
Ọ̀nà mẹ́ta wo la lè gbà fi hàn pé a mọrírì ohun tó ṣe?
Máa Fetí Sílẹ̀ Nípàdé: (3 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò. Lẹ́yìn náà, ní kí àwọn ọmọdé sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa fetí sílẹ̀ nípàdé.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 10 ¶5-9
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 108 àti Àdúrà