September 16-22
HÉBÉRÙ 11
Orin 119 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́?”: (10 min.)
Heb 11:1—Ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí (w16.10 27 ¶6)
Heb 11:6—A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ ká tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ (w13 11/1 11 ¶2-5)
Heb 11:33-38—Ìgbàgbọ́ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ní ló mú kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú (w16.10 23 ¶10-11)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Heb 11:4—Kí ló jẹ́ kí Ébẹ́lì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára? (it-1 804 ¶5)
Heb 11:5—Báwo ni Jèhófà ṣe san Énọ́kù lẹ́san torí ìgbàgbọ́ tó ní? (wp17.1 12-13)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Heb 11:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 3)
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Fún onílé ní ìwé ìkésíni sáwọn ìpàdé wa, kó o sì ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 11)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Kí Lo Máa Ṣe Ní Ọdún Ọ̀gbẹlẹ̀?”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 10 ¶10-15
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 54 àti Àdúrà