FEBRUARY 10-16
JẸ́NẸ́SÍSÌ 15-17
Orin 39 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Yí Orúkọ Ábúrámù àti Sáráì Pa Dà?”: (10 min.)
Jẹ 17:1—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Ábúrámù, ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi (it-1 817)
Jẹ 17:3-5—Jèhófà yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ábúráhámù (it-1 31 ¶1)
Jẹ 17:15, 16—Jèhófà yí orúkọ Sáráì pa dà sí Sérà (w09 2/1 13)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 15:13, 14—Ìgbà wo ni ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún táwọn ọmọ Ábúrámù fi jìyà bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ló sì parí? (it-1 460-461)
Jẹ 15:16—Báwo làwọn ọmọ Ábúráhámù ṣe pa dà sí ilẹ̀ Kénáánì ní “ìran wọn kẹrin”? (it-1 778 ¶4)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 15:1-21 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni akéde náà ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó yẹ? Báwo ló ṣe fi àpèjúwe kọ́ onílé lẹ́kọ̀ọ́?
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀, kó o sì fi ẹ̀kọ́ 3 bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 6)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bí Àwọn Tọkọtaya Ṣe Lè Túbọ̀ Ṣe Ara Wọn Lọ́kan”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Túbọ̀ Ṣe Ara Wọn Lọ́kan.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 15 ¶17-20
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 92 àti Àdúrà