ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 April ojú ìwé 7
  • ‘Ẹ Mú Àwọn Ọlọ́run Àjèjì Kúrò’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Mú Àwọn Ọlọ́run Àjèjì Kúrò’
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ẹgbẹ́ Òkùnkùn Ò Léwu?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Borí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ẹ̀mí Òkùnkùn?
    Jí!—2017
  • Jèhófà Nìkan Ṣoṣo Ni Kó O Máa Jọ́sìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 April ojú ìwé 7
Ọkùnrin kan sọ ìlẹ̀kẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò nù.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

‘Ẹ Mú Àwọn Ọlọ́run Àjèjì Kúrò’

Jékọ́bù mọ̀ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa sìn, bó tílẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò tíì fún àwọn èèyàn ní òfin lórí ìbọ̀rìṣà. (Ẹk 20:3-5) Torí náà, nígbà tí Jèhófà ní kó pa dà sí Bẹ́tẹ́lì, Jékọ́bù pàṣẹ fún gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé kí wọ́n mú àwọn ère tó wà pẹ̀lú wọn kúrò. Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù kó gbogbo àwọn ère náà dànù títí kan yẹtí tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fi dáàbò bo ara wọn. (Jẹ 35:1-4) Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà máa dùn sí ohun tí Jékọ́bù ṣe.

Lóde òní ńkọ́, báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà nìkan ṣoṣo là ń sìn? Ohun pàtàkì tá a lè ṣe ni pé ká yẹra fún ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà tàbí ìbẹ́mìílò. Èyí gba pé ká kó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò dànù, ká sì ṣàyẹ̀wò eré ìnàjú tá à ń wò. Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn ìwé tàbí fíìmù tó dá lórí àwọn ẹlẹyẹ, àǹjọ̀nú, àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, babaláwo àtàwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn ni mo máa ń gbádùn? Ṣé àwọn fíìmù tí mò ń wò máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú idán pípa, èèdì tàbí ọfọ̀?’ A gbọ́dọ̀ ta kété sí ohunkóhun tí Jèhófà kórìíra.​—Sm 97:10.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ DOJÚ ÌJÀ KỌ ÈṢÙ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ọmọ kékeré kan sùn sórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì fi ońdè sọ́wọ́. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn, ìyá ọmọ náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń bá àwọn tọkọtaya tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀.

    Ìṣòro wo ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Palesa ní?

  • Tọkọtaya náà àti ìyá ọmọ náà lọ bá àwọn alàgbà fún ìrànwọ́.

    Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká wá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìbẹ́mìílò?

  • Ìyá tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà sun ońdè tó wà lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀ nínú iná.

    Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, kẹ́ ẹ sì sún mọ́ Ọlọ́run.​—Jem 4:7, 8

    Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dáàbò bò wá, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká kó dànù?

  • Ìgbésẹ̀ akin wo ni Palesa gbé?

  • Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tó o bá fẹ́ yẹra fún ìbẹ́mìílò lágbègbè rẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́