June 8-14
JẸ́NẸ́SÍSÌ 46-47
Orin 86 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Pèsè Oúnjẹ Lásìkò Ìyàn”: (10 min.)
Jẹ 47:13—Ìyàn mú gan-an nílẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Kénáánì (w87 5/1 15 ¶2)
Jẹ 47:16, 19, 20—Àwọn ará Íjíbítì yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n má bàa kú
Jẹ 47:23-25—Ó gba ìsapá ká tó lè jàǹfààní látinú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí ètò Ọlọ́run ń pèsè fún wa lónìí (kr 235 ¶11-12)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 46:4—Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Jósẹ́fù yóò “gbé ọwọ́ rẹ̀ lé” ojú Jékọ́bù? (it-1 220 ¶1)
Jẹ 46:26, 27—Èèyàn mélòó nínú ìdílé Jékọ́bù ló bá a lọ sí Íjíbítì? (“gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin (75)” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 7:14, nwtsty)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 47:1-17 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni akéde yẹn ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́? Báwo ló ṣe ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì tó kà?
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún un ní ìwé Bíbélì Kọ́ Wa, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní orí 9. (th ẹ̀kọ́ 14)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Fiyè Sí Àwọn Ìránnilétí Jèhófà: (15 min.) Ẹ wo fídíò Mọyì Àwọn Ìránnilétí Jèhófà. Rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa ka Bíbélì déédéé, kí wọ́n sì máa gbádùn gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí tí ètò Ọlọ́run ń pèsè.—Ais 25:6; 55:1; 65:13; Mt 24:45.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 118
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 109 àti Àdúrà