August 10-16
Ẹ́KÍSÓDÙ 15-16
Orin 149 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Fi Orin Yin Jèhófà”: (10 min.)
Ẹk 15:1, 2—Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi orin yin Jèhófà (w95 10/15 11 ¶11)
Ẹk 15:11, 18—Ó yẹ ká máa yin Jèhófà (w95 10/15 11-12 ¶15-16)
Ẹk 15:20, 21—Míríámù àtàwọn obìnrin Ísírẹ́lì fi orin yin Jèhófà (it-2 454 ¶1; 698)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 16:13—Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Jèhófà fi fi ẹyẹ àparò bọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù? (w11 9/1 14)
Ẹk 16:32-34—Ibo ni wọ́n tọ́jú ìkòkò mánà sí? (w06 1/15 31)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 16:1-18 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni Ladé ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́? Báwo ló ṣe ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó ṣe kedere?
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà, fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Fi Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Yin Jèhófà”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Àwọn Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Mẹ́ta ní Orílẹ̀-Èdè Mòǹgólíà. Fọ̀rọ̀ wá arákùnrin tàbí arábìnrin kan lẹ́nu wò, kí ẹni náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí kó ti fìgbà kan ri jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bi í pé: Àwọn ìṣòro wo lo ti kojú? Àwọn ìbùkún wo lo ti rí?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 127, àti àpótí “Pápá Ẹ̀jẹ̀”
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 16 àti Àdúrà