August 31–September 6
Ẹ́KÍSÓDÙ 21-22
Orin 141 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Jọ Ẹ́ Lójú Bíi Ti Jèhófà”: (10 min.)
Ẹk 21:22, 23—Ẹ̀mí ọmọ tó wà nínú oyún ṣeyebíye lójú Jèhófà (lv 80 ¶16)
Ẹk 21:28, 29—Jèhófà ò fẹ́ ká fọ̀rọ̀ ààbò ṣeré rárá (w10 4/15 29 ¶4)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 21:5, 6—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí i pé ìyàsímímọ́ máa ń ṣe wá láǹfààní? (w10 1/15 4 ¶4-5)
Ẹk 21:14—Kí ló ṣeé ṣe kí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí? (it-1 1143)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 21:1-21 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Pe ẹni náà wá sí àwọn ìpàdé wa. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 20)
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w09 4/1 31—Àkòrí: Jèhófà Ni Bàbá Àwọn Ọmọ Aláìníbaba. (th ẹ̀kọ́ 19)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Fi Hàn Pé Ẹ̀mí Èèyàn Jọ Ẹ́ Lójú: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn ìyẹn, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kó yọjú tí obìnrin kan bá lóyún? Báwo ni Ẹ́kísódù 21:22, 23 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kò dáa kéèyàn ṣẹ́yún? Kí nìdí tá a fi nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ká lè ṣe ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn? Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe ń tù wá nínú?
Bí Ìyàsímímọ́ Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní: (5 min.) Àsọyé tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ January 15, 2010, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 4-7. Gba àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níyànjú pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 130
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 15 àti Àdúrà