December 14-20
LÉFÍTÍKÙ 12-13
Orin 140 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Òfin Nípa Àrùn Ẹ̀tẹ̀”: (10 min.)
Le 13:4, 5—Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn èèyàn tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ́tọ̀ (wp18.1 7)
Le 13:45, 46—Ẹni tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn kó má bàa kó o ràn wọ́n (wp16.4 9 ¶1)
Le 13:52, 57—Wọ́n gbọ́dọ̀ sun ohunkóhun tí àrùn náà bá wà lára ẹ̀ (it-2 238 ¶3)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Le 12:2, 5—Kí nìdí tọ́mọ bíbí fi máa ń sọ àwọn obìnrin di “aláìmọ́”? (w04 5/15 23 ¶2)
Le 12:3—Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ kẹjọ ni Jèhófà ní kí wọ́n dádọ̀dọ́ ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí? (wp18.1 7)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Le 13:9-28 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Ìjíròrò. E wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Báwo ni Tóyìn ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó yẹ? Báwo ló ṣe jẹ́ kí onílé lóye ẹsẹ Bíbélì tó kà?
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 19)
Ìpadàbẹ̀wò: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀kọ́ 11. (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (15 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) rr orí 2 ¶1-9 àti fídíò ohun tó wà ní orí 2
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 28 àti Àdúrà