Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
DECEMBER 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 10-11
“A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ju Ìdílé Wa Lọ”
it-1 1174
Ohun Tí Kò Yẹ
Ẹbọ àti Tùràrí Tí Kò Yẹ. Ní Léfítíkù 10:1, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà, zar (tó túmọ̀ sí, ṣàjèjì) nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹbọ tí kò yẹ níwájú Jèhófà,” ìyẹn “ohun tí kò pa láṣẹ fún wọn,” àmọ́ tí àwọn ọmọ Áárónì, ìyẹn Nádábù àti Ábíhù rú níwájú Jèhófà, tí Jèhófà sì tìtorí ẹ̀ fi iná pa wọ́n. (Le 10:2; Nọ 3:4; 26:61) Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Áárónì pé: “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí nígbà tí ẹ bá wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí ẹ má bàa kú. Àṣẹ tí ìran yín á máa pa mọ́ títí láé ni. Èyí máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun mímọ́ àti ohun tó di aláìmọ́ àti sáàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́, yóò sì tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìlànà tí Jèhófà sọ fún wọn nípasẹ̀ Mósè.” (Le 10:8-11) Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí Nádábù àti Ábíhù ti mutí yó, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n rú ẹbọ tí kò yẹ sí Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àkókò tí wọ́n rú ẹbọ náà, ibi tí wọ́n ti rú u tàbí bí wọ́n ṣe rú u ni kò tọ̀nà. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n lo tùràrí tó yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọ́run sọ nínú Ẹ́kísódù 30:34, 35. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti mutí yó, tí wọn ò sì mọ ohun tí wọ́n ń ṣe, ìyẹn ò ní kí Jèhófà gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Ṣé O Ti Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run?
Áárónì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè bá ara rẹ̀ nínú ipò tó ṣòro nítorí ohun tí méjì nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe. Ronú nípa bó ṣe máa rí lára rẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀, Nádábù àti Ábíhù rú ẹbọ tí kò bá ìlànà mu sí Jèhófà, tí Jèhófà sì pa wọ́n. Ikú àwọn ọmọ náà fòpin sí àjọṣe èyíkéyìí tí wọ́n lè ní pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Síbẹ̀, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ ṣòro fún Áárónì àti ìdílé rẹ̀. Jèhófà pàṣẹ fún òun àti àwọn méjì yòókù tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ banú jẹ́ nítorí wọn. Ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí orí yín wà láìtọ́jú, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ya ẹ̀wù yín [torí pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀], kí ẹ má bàa kú, kí ìkannú [Jèhófà] má bàa ru sí gbogbo àpéjọ yìí.” (Léf. 10:1-6) Ẹ̀kọ́ tí èyí kọ́ wa ṣe kedere. Ẹ̀kọ́ náà sì ni pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára ju ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ìbátan wa tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Jèhófà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
A Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Wa
Ká lè máa jẹ́ mímọ́, a gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yẹ̀ wò ká sì máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe. Ronú nípa àwọn ọmọ Áárónì, Nádábù àti Ábíhù, tí wọ́n kú torí pé wọn rú “ẹbọ tí kò bá ìlànà mu,” bóyá nítorí pé wọ́n ti mutí yó. (Léf. 10:1, 2) Kíyè sí ohun tí Ọlọ́run sọ fún Áárónì lẹ́yìn náà. (Ka Léfítíkù 10:8-11.) Ṣé ohun tí ẹsẹ yẹn ń sọ ni pé a kò gbọ́dọ̀ mu ọtí ká tó lọ sí ìpàdé ìjọ? Àwọn kókó tó o máa ronú lé lórí rèé: A kò sí lábẹ́ Òfin Mósè. (Róòmù 10:4) Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni máa ń mu ọtí níwọ̀nba tí wọ́n bá ń jẹun kí wọ́n tó lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ife wáìnì mẹ́rin ni wọ́n máa ń lò níbi àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nígbà tí Jésù dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó ní kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mu wáìnì tó ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (Mát. 26:27) Bíbélì sọ pé ọtí àmujù àti àmupara kò dára. (1 Kọ́r. 6:10; 1 Tím. 3:8) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni sì wà tó jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn wọn mú kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní mutí rárá táwọn bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ èyíkéyìí. Àmọ́, bí ipò nǹkan ṣe rí ní orílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí bó ṣe rí ní orílẹ̀-èdè míì àti pé ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí àwọn Kristẹni máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́” kí wọ́n lè máa hùwà mímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́.
it-1 111 ¶5
Ẹranko
Àwọn tí Ọlọ́run fún ní Òfin Mósè nìkan ni ọ̀rọ̀ yìí kàn, pé kí wọ́n má jẹ àwọn ẹran kan, torí ohun tí Léfítíkù 11:8 sọ ni pé: “Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín,” ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ Òfin Mósè parí iṣẹ́ lẹ́yìn tí Jésù Kristi fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ, torí náà òfin tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran kan ti dópin. Ìyẹn wá mú kí gbogbo èèyàn lè máa tẹ̀ lé ohun tí Ọlọ́run sọ fún Nóà lẹ́yìn Ìkún Omi.—Kol 2:13-17; Jẹ 9:3, 4.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 12-13
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Òfin Nípa Àrùn Ẹ̀tẹ̀”
Ṣé Bíbélì Bá Àkókò Wa Mu Àbí Kò Wúlò Mọ́ Rárá?
• Yíya àwọn tó ní àrùn sọ́tọ̀.
Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn èèyàn tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ́tọ̀. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méje [700] sẹ́yìn tí oríṣiríṣi àrùn ń yọjú ni àwọn dókítà wá bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ̀ lé ìlànà yìí, wọ́n sì gbà pé ó wúlò títí dòní.—Léfítíkù, orí 13 àti 14.
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Àwọn Júù máa ń bẹ̀rù àìsàn ẹ̀tẹ̀ kan tó sábà máa ń ṣe àwọn èèyàn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ńṣe ló máa ń mú kí ara ẹni náà kú tipiri, táá sì sọ ẹni náà di aláàbọ̀ ara débi tí kò fi ní látùnṣe mọ́. Àìsàn náà kò gbóògùn nígbà yẹn. Torí náà, ńṣe ni wọ́n máa ń ya àwọn tó ní àìsàn yìí sọ́tọ̀, tí wọ́n á sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sún mọ́ wọn.—Léfítíkù 13:45, 46.
it-2 238 ¶3
Àrùn Ẹ̀tẹ̀
Lára aṣọ àti ilé. Àrùn ẹ̀tẹ̀ tún lè mú aṣọ onírun, aṣọ ọ̀gbọ̀ tàbí ohun tí wọ́n fi awọ ṣe. Tí wọ́n bá fọ aṣọ ọ̀hún, àrùn náà lè kúrò lára ẹ̀, ètò sì wà pé kí wọ́n sé aṣọ náà mọ́lé fún ọjọ́ mélòó kan. Àmọ́ tí àbààwọ́n aláwọ̀ ewé tàbí aláwọ̀ pupa tí àrùn náà fà bá ṣì wà lára aṣọ náà, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an ni, wọ́n á sì dáná sun aṣọ náà. (Le 13:47-59) Tí àbààwọ́n aláwọ̀ ewé tàbí aláwọ̀ pupa bá yọ sára ògiri ilé kan, àlùfáà gbọ́dọ̀ ti ilé náà pa fún ọjọ́ mélòó kan. Ó lè pọn dandan kí wọ́n yọ àwọn òkúta tí àrùn náà wà lára ẹ̀ kúrò, kí wọ́n sì ha inú ilé náà. Kí wọ́n wá da àwọn òkúta náà àtàwọn ohun tí wọ́n ha lára ilé náà sí ẹ̀yìn ìlú níbi àìmọ́. Tí àrùn yẹn bá pa dà yọ sára ilé náà, kí àlùfáà kéde pé ó ti di aláìmọ́, kí wọ́n wó o, kí wọ́n sì da àwọn ohun tí wọ́n fi kọ́ ilé náà nù síbi àìmọ́. Àmọ́ ká sọ pé àlùfáà kéde pé ilé náà mọ́, ètò wà láti wẹ ẹ̀gbin kúrò nínú ilé náà. (Le 14:33-57) Àwọn kan sọ pé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá yọ sára aṣọ tàbí ilé, ó máa ń dà bí nǹkan tó bu; àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Léfítíkù
12:2, 5—Kí nìdí tọ́mọ bíbí fi sọ àwọn obìnrin di “aláìmọ́”? Ọlọ́run dá ẹ̀yà ìbímọ ènìyàn kí á lè fi mú ẹ̀dá ènìyàn pípé wá sáyé. Àmọ́ nítorí àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún, àìpé òun ẹ̀ṣẹ̀ là ń bí mọ́ àwọn ọmọ. Àkókò ráńpẹ́ tí wọ́n fi jẹ́ “aláìmọ́” nígbà ìbímọ àti nítorí àwọn nǹkan mìíràn, irú bíi nǹkan oṣù àti dída àtọ̀ máa ń jẹ́ kí wọ́n rántí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti jogún. (Léfítíkù 15:16-24; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Òfin tá a fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìwẹ̀mọ́ yóò jẹ́ kí wọ́n lóye ìdí tí wọ́n fi nílò ẹbọ ìràpadà láti fi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé àti láti sọ aráyé di pípé. Nítorí èyí, Òfin náà di “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ [wọn] tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.”—Gálátíà 3:24.
Ṣé Bíbélì Bá Àkókò Wa Mu Àbí Kò Wúlò Mọ́ Rárá?
• Ìgbà tó yẹ kí wọ́n dádọ̀dọ́ fún ọmọ.
Òfin Ọlọ́run sọ ní pàtó pé wọ́n gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ ọmọkùnrin ní ọjọ́ kẹjọ tí wọ́n bí i. (Léfítíkù 12:3) Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n bá bí ọmọ jòjòló ni ẹ̀jẹ̀ tó lè tètè dá lára rẹ̀ bó ṣe yẹ. Ní àwọn ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, tí ìmọ̀ ìṣègùn kò tíì jinlẹ̀ tó tòde òní, ó bọ́gbọ́n mu kí wọ́n dúró di ẹ̀yìn ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n tó dádọ̀dọ́ ọmọ fún àǹfààní ọmọ náà.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 14-15
“Ìjọsìn Mímọ́ Gba Pé Kéèyàn Wà Ní Mímọ́”
it-1 263
Ìwẹ̀
Àwọn ohun pàtó kan wà tó máa ń mú kó pọn dandan fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wẹ̀ láwọn àkókò kan. Bí àpẹẹrẹ, tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ lára ẹnì kan, tí ẹnì kan bá fara kan ẹni tí “ohun kan ń dà jáde lára” ẹ̀, tí àtọ̀ bá dà lára ọkùnrin kan, tí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù tàbí tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára ẹ̀ tàbí tí ẹnì kan bá ní ìbálòpọ̀, onítọ̀hún ti di “aláìmọ́” nìyẹn, ó sì gbọ́dọ̀ wẹ̀. (Le 14:8, 9; 15:4-27) Tí ẹnì kan bá wà nínú àgọ́ pẹ̀lú òkú èèyàn tàbí tó fara kan òkú náà, ẹni náà ti di “aláìmọ́,” wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi omi ìwẹ̀mọ́ wẹ̀ ẹ́ mọ́. Tí ẹni náà ò bá tẹ̀ lé ohun tí òfin sọ, wọ́n gbọ́dọ̀ “pa ẹni náà kúrò láàárín ìjọ, torí ó ti sọ ibi mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́.” (Nọ 19:20) Torí náà, ṣe ni ìwẹ̀ máa ń ṣàpẹẹrẹ kéèyàn jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. (Sm 26:6; 73:13; Ais 1:16; Isk 16:9) Òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló dà bí omi, tá a bá sì ń fi wẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àá jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà.—Ef 5:26.
it-2 372 ¶2
Nǹkan Oṣù
Obìnrin kan máa jẹ́ aláìmọ tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá ń ṣe ségesège tàbí “tí iye ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ fi dà lára rẹ̀ bá pọ̀ ju iye tó máa ń jẹ́ tó bá ń ṣe nǹkan oṣù.” Ohunkóhun tó bá sùn lé tàbí jókòó lé máa jẹ́ aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì fara kan àwọn nǹkan náà máa jẹ́ aláìmọ́. Lẹ́yìn tí ẹ̀jẹ̀ yẹn bá dáwọ́ dúró, obìnrin náà máa ka ọjọ́ méje kó tó lè di mímọ́. Tó bá wá di ọjọ́ kẹjọ, ó máa mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì lọ fún àlùfáà, kí àlùfáà lè fi ṣe ètùtù fún obìnrin náà. Àlùfáà yẹn máa fi ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà ṣe ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀, á sì fi ìkejì ṣe ọrẹ sísun.—Le 15:19-30 wo MÍMỌ́ àti ÌJẸ́MÍMỌ́.
it-1 1133
Ibi Mímọ́
2. Ó tọ́ka sí àgọ́ ìpàdé àti tẹ́ńpìlì nígbà tó yá. Àwọn ilé méjèèjì, títí kan àgbàlá àgọ́ ìjọsìn àti àgbàlá tẹ́ńpìlì ló jẹ́ ibi mímọ́. (Ẹk 38:24; 2Kr 29:5; Iṣe 21:28) Àwọn ohun pàtàkì tó wà ní àgbàlá náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń rúbọ àti bàsíà tí wọ́n fi bàbà ṣe. Ohun mímọ́ ni wọ́n. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn tó bá ti wẹ ara wọn mọ́ lọ́nà Òfin nìkan ló lè wọnú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn nígbàkigbà; bẹ́ẹ̀ ló ṣe jẹ pé àwọn tí ò bá mọ́ kò lè wọnú àgbàlá tẹ́ńpìlì. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin tó bá wà nípò àìmọ́ kò lè fara kan ohun mímọ́ kankan, kò sì lè wọnú ibi mímọ́. (Le 12:2-4) Ìyẹn túmọ̀ sí pé, ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ṣì wà ní ipò àìmọ́ lè sọ àgọ́ ìjọsìn di ẹlẹ́gbin tó bá wọbẹ̀. (Le 15:31) Àwọn tó bá mú ọrẹ wá láti wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú àrùn ẹ̀tẹ̀ kì í kọjá ẹnubodè àgbàlá. (Le 14:11) Ẹni tó bá sì jẹ́ aláìmọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì, kó má bàa kú.—Le 7:20, 21.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 665 ¶5
Etí
Nígbà tí wọ́n bá ń faṣẹ́ lé àwọn àlùfáà lọ́wọ́ ní Ísírẹ́lì, Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè pé kó fi díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ àgbò àfiyanni sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀, kó tún fi sí ọwọ́ ọ̀tún àti ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìyẹn fi hàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa ronú lórí ipò tí wọ́n wà nínú àgọ́ ìjọsìn, kíyẹn sì máa darí ohun tí wọ́n ń gbọ́, ìṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe àti ibi tí wọ́n ń rìn sí. (Le 8:22-24) Bákan náà, tí wọ́n bá ti wẹ adẹ́tẹ̀ kan mọ́, Òfin sọ pé kí àlùfáà fi díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ àgbò tí adẹ́tẹ̀ náà fi ṣe ẹbọ ẹ̀bi àti òróró tó mú wá sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún adẹ́tẹ̀ náà. (Le 14:14, 17, 25, 28) Ohun tó jọ èyí ni wọ́n máa ń ṣe fún ẹrú kan tó bá wù láti di ti ọ̀gá rẹ̀ títí láé. Wọ́n á mú ẹni náà wá síbi férémù ilẹ̀kùn, ọ̀gá rẹ̀ á sì fi òòlu lu etí rẹ̀. Àmì tó wà ní etí rẹ̀ yìí fi hàn pé ẹrú náà múra tán láti máa ṣègbọràn sí ọ̀gá rẹ̀.—Ẹk 21:5, 6.
g 1/06 14, àpótí
Èbíbu—Ṣé Ó Wúlò àbí Kò Wúlò?
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ NÍGBÀ TÍ WỌ́N KỌ BÍBÉLÌ
Bíbélì sọ pé ‘ẹ̀tẹ̀ lè yọ lára ilé kan.’ (Léfítíkù 14:34-48) Àwọn kan sọ pé ohun tí Bíbélì pè ní “àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an” lára ilé lè túmọ̀ sí pé kí ilé náà ti bu, àmọ́ a ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Èyí ó wù ó jẹ́, Òfin Ọlọ́run sọ pé kí ẹni tó nilé náà yọ àwọn òkúta tí àrùn náà wà lára ẹ̀, kó ha gbogbo inú ilé náà, kó sì kó àwọn òkúta àti gbogbo nǹkan tó ha lára ilé náà dà nù sí ẹ̀yìn ìlú “níbi àìmọ́.” Tí àrùn náà bá tún yọ lára ilé náà, àlùfáà máa kéde pé ilé náà ti di aláìmọ́, wọ́n á wó o, wọ́n á sì kó àwókù rẹ̀ dà nù. Òfin yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ gan-an, ìlera wọn sì ṣe pàtàkì sí i.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 28–JANUARY 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 16-17
“Bí Ọjọ́ Ètùtù Ṣe Kàn Ẹ́”
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
Ka Léfítíkù 16:12, 13. Fojú inú wò ó bíi pé o wà níbẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù: Àlùfáà àgbà wọnú àgọ́ ìjọsìn. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbà mẹ́ta tó máa wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ lọ́jọ́ yẹn. Ó fi ọwọ́ kan gbé tùràrí onílọ́fínńdà dání, ó sì fi ọwọ́ kejì gbé ìkóná oníwúrà tó kún fún ẹyin iná. Ó dúró díẹ̀ nígbà tó dé iwájú aṣọ ìdábùú tó wà ní àbáwọlé Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló fi wọlé sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì dúró síwájú àpótí májẹ̀mú. Níbi tó dé yìí, ṣe ló dà bíi pé iwájú Jèhófà Ọlọ́run gan-an ló wà! Lẹ́yìn náà, ó rọra da tùràrí mímọ́ náà sínú ẹyin iná, gbogbo iyàrá náà sì kún fún òórùn dídùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì tún máa pa dà wá sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ǹjẹ́ ẹ kíyè sí i pé ó kọ́kọ́ sun tùràrí kó tó wá rú ẹbọ náà.
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń lo tùràrí ní Ọjọ́ Ètùtù? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi àdúrà wọn wé tùràrí. (Sm. 141:2; Ìfi. 5:8) Ẹ rántí pé nígbà tí àlùfáà àgbà bá fẹ́ lọ sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ láti sun tùràrí, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ẹni ńlá ni Jèhófà, ó sì yẹ ká bọ̀wọ̀ fún un gan-an. A mọyì pé Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run gbà káwa èèyàn lásán-làsàn sún mọ́ òun, ká sì bá òun sọ̀rọ̀ bí ọmọ ṣe máa ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀. (Jém. 4:8) Kódà, ó gbà pé ọ̀rẹ́ òun ni wá! (Sm. 25:14) A mọyì àǹfààní ńlá tí Jèhófà fún wa yìí, torí náà a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bà á nínú jẹ́.
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
Àlùfáà àgbà máa ní láti kọ́kọ́ sun tùràrí kó tó lè rú ẹbọ sí Jèhófà, torí ìyẹn ló máa jẹ́ kó rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà nígbà tó bá rú ẹbọ. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Nígbà tí Jésù wà láyé, kó tó di pé ó fi ara rẹ̀ rúbọ, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an, kódà ohun náà ṣe pàtàkì ju ìgbàlà wa lọ. Kí ni nǹkan náà? Ó gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i torí pé ìyẹn lá jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ tó fẹ́ rú. Ìgbọràn Jésù máa fi hàn pé ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbésí ayé wa ni pé ká ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó sì tún máa jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 226 ¶3
Ásásélì
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ, ó sì ṣe ohun tí “ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́” ò lè ṣe láti gba aráyé là. (Heb 10:4, 11, 12) Torí náà, Jésù dà bí “ewúrẹ́ tó lọ,” ó “gbé àwọn àìsàn wa” lọ, wọ́n sì “gún un torí àṣìṣe wa.” (Ais 53:4, 5; Mt 8:17; 1Pe 2:24) Ó “gbé” ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀ lọ. Ohun tó ṣe yẹn jẹ́ ká rí ètò tí Ọlọ́run ṣe láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá. Láwọn ọ̀nà yìí, ewúrẹ́ tá a pè ní “Ásásélì” ṣàpẹẹrẹ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.
Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́
Ka Léfítíkù 17:10. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe jẹ “ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí.” Ọlọ́run ní kí àwa Kristẹni náà ta kété sí ẹ̀jẹ̀, ì báà jẹ́ ti èèyàn tàbí ti ẹranko. (Ìṣe 15:28, 29) Kò sẹ́ni tẹ́rù ò ní bà tó bá mọ̀ pé Ọlọ́run máa ‘dojú kọ òun’ kó sì ké òun kúrò láàárín ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ láti máa ṣègbọràn sí i. Bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé a dojú kọ ohun tó lè ṣekú pa wá, tí àwọn tí kò mọ Jèhófà tí wọn ò sì fẹ́ ṣègbọràn sí i ń rọ̀ wá láti ṣohun tí kò tọ́, a ti pinnu pé a ò ní juwọ́ sílẹ̀. Kódà, bí wọ́n bá fẹ́ mú wa lọ́ranyàn, a ò ní gbà. Ó dájú pé àwọn èèyàn máa fi wá ṣẹ̀sín tá a bá ta kété sí ẹ̀jẹ̀, àmọ́ a ti pinnu láti ṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́run sọ. (Júúdà 17, 18) Tó bá dọ̀ràn ẹ̀jẹ̀, kí ló máa mú ká ‘pinnu lọ́nà tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in’ pé a kò ní jẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí pé a ò ní gbà kí wọ́n fà á sí wa lára?—Diu. 12:23.
Bíbélì Kíkà