MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
Ìkìlọ̀ pàtàkì lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù jẹ́ fáwa Kristẹni. (1Kọ 10:6, 8, 11) Nígbà táwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ Móábù oníṣekúṣe àti abọ̀rìṣà, àwọn ọmọ Móábù mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Wàhálà ńlá nìyẹn sì fà fún wọn. (Nọ 25:9) Ọ̀pọ̀ àwọn tó yí wa ká ni ò sin Jèhófà, irú bí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ iléèwé wa, àwọn aládùúgbò àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa. Kí la rí kọ́ látinú ìtàn yìí nípa ìdí tí kò fi yẹ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò sin Jèhófà?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ JẸ́ ÀRÍKỌ́GBỌ́N FÚN WA—ÀYỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Èrò burúkú wo ni Símírì àtàwọn míì ń gbìn sọ́kàn Jámínì?
Báwo ni Fíníhásì ṣe ran Jámínì lọ́wọ́ kó lè ní èrò tó tọ́?
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín kéèyàn ṣe dáadáa sí ẹnì kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti kéèyàn di ọ̀rẹ́ rẹ̀?
Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára tá a bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, kódà tó bá jẹ́ nínú ìjọ?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bá àwọn tá ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì?