May 24-30
NỌ́ŃBÀ 34-36
Orin 33 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Fi Jèhófà Ṣe Ibi Ààbò Rẹ”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Nọ 35:31—Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà ò fi ní jàǹfààní ìràpadà tí Jésù san? (w91 2/15 13 ¶13)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Nọ 34:1-15 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 12)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 9)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) fg ẹ̀kọ́ 2 ¶9-10 (th ẹ̀kọ́ 19)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Ìfẹ́ Ni Ìbáwí: (6 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan, kó o sì béèrè àwọn ìbéèrè yìí lọ́wọ́ wọn: Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí ẹ máa bá ẹ wí? Báwo ni ìbáwí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń bá wa wí?
“Ìfẹ́ Ló Ń Mú Kí Jèhófà Bá Wa Wí”: (9 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò “Àwọn Tí Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ló Máa Ń Bá Wí”.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 9 ¶1-9 àti fídíò ohun tó wà ní orí 9
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 93 àti Àdúrà