May 31–June 6
DIUTARÓNÓMÌ 1-2
Orin 125 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ọlọ́run Ló Ni Ìdájọ́”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Di 1:19; 2:7—Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n rìnrìn àjò fún ogójì ọdún nínú ‘aginjù tó tóbi, tó sì ń bani lẹ́rù’? (w13 9/15 9 ¶9)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Di 1:1-18 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 16)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Pe ẹni náà wá sípàdé, kó o sì ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 11)
Àsọyé: (5 min.) w13 8/15 11 ¶7—Àkòrí: Má Ṣe Máa Sọ Tàbí Tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Tí Kò Dáa. (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ Yìí”: (15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù? Mẹ́nu kan àwọn ìtọ́ni tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fún un yín àtèyí tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fohùn ṣọ̀kan lé lórí, ìyẹn tó bá wà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 9 ¶10-17
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 64 àti Àdúrà