ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 January ojú ìwé 11
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Yín Fáwọn Òbí Yín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Yín Fáwọn Òbí Yín
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • O Lè Mú Kí Ayọ̀ Túbọ̀ Wà Nínú Ìdílé Rẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 January ojú ìwé 11

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ Máa Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Yín Fáwọn Òbí Yín

Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa sọ tọkàn ẹ fáwọn òbí ẹ? (Owe 23:26) Ìdí ni pé Jèhófà ló ní kí wọ́n máa bójú tó ẹ, kí wọ́n sì máa tọ́ ẹ sọ́nà. (Sm 127:3, 4) Àmọ́, kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí o ò bá jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ò ń bá yí, o ò sì ní lè jàǹfààní látinú ìrírí wọn. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo nǹkan lo gbọ́dọ̀ máa sọ fáwọn òbí ẹ? Kò pọn dandan kó rí bẹ́ẹ̀, tó ò bá ṣáà ti fi àwọn ohun tí kò yẹ pa mọ́.​—Owe 3:32.

Báwo lo ṣe lè bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀? O lè wá àkókò tó máa rọrùn fún wọn, táá sì rọrùn fún ìwọ náà. Tí ìyẹn ò bá rọrùn, o lè kọ lẹ́tà sí ọ̀kan nínú wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ. Àmọ́ tí wọ́n bá béèrè ohun tí o ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ ńkọ́, kí lo lè ṣe? Má gbàgbé pé àwọn òbí ẹ fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni. Fi sọ́kàn pé ọ̀rẹ́ ẹ ni wọ́n jẹ́, wọn kì í ṣe ọ̀tá. Tó o bá ń sapá láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fáwọn òbí ẹ, ó dájú pé ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ máa ṣe ẹ́ láǹfààní nísinsìnyí àti títí láé!​—Owe 4:10-12.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÀ Ọ̀DỌ́ MI​—BÁWO NI MO ṢE LÈ MÁA BÁ ÀWỌN ÒBÍ MI SỌ̀RỌ̀ KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Fọ́tò kan nínú fídíò Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi​—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?” Ọ̀dọ́bìnrin kan ń tẹ kọ̀ǹpútà, ìyá ẹ̀ ń bá a sọ̀rọ̀ àmọ́ kò dá a lóhùn.

    Kí ni Esther àti Partik rí i pé àwọn ń ṣe tí ò dáa?

  • Fọ́tò kan nínú fídíò Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi​—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?” Ọ̀dọ́bìnrin kan ń bá ìyá ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì ń fi nǹkan hàn án lórí fóònù.

    Kí lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?

  • Fọ́tò kan nínú fídíò Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi​—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?” Ìyá kan fi iṣẹ́ ilé tó ń ṣe sílẹ̀ kó lè lọ bá ọmọ ẹ̀ ṣeré.

    Kí làwọn òbí ẹ ti ṣe fún ẹ tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ?

  • Fọ́tò kan nínú fídíò Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi​—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?” Kóoṣì kan ń ya àwòrán báwọn tó wà nínú àwùjọ ẹ̀ ṣe máa gbá bọ́ọ̀lù.

    Àwọn òbí ẹ fẹ́ káyé ẹ dáa

    Àwọn ìlànà Bíbélì wo lo lè ronú lé tó bá ṣòro fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rò?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́